Galatia 1 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Galatia 1:1-24

1Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú. 2Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,

Sí àwọn ìjọ ní Galatia:

31.3: Ro 1.7.Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa, 41.4: Ga 2.20; 1Tm 2.6.ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, 51.5: Ro 16.27.ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Kò sí ìyìnrere mìíràn

6Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìyìnrere mìíràn. 7Nítòótọ́, kò sí ìyìnrere mìíràn bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìnrere Kristi padà. 81.8: 2Kọ 11.4.Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìyìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! 9Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé, bí ẹnìkan bá wàásù ìyìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

101.10: 1Tẹ 2.4.Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi.

Paulu ẹni tí Ọlọ́run pè

111.11: Ro 1.16-17.Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn. 12N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi.

131.13: Ap 8.3.Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́. 141.14: Ap 22.3.Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi. 151.15: Ap 9.1-19; Isa 49.1; Jr 1.5.Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. 16Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìyìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni, 17bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerusalẹmu tọ àwọn tí í ṣe aposteli ṣáájú mi, ṣùgbọ́n mo lọ sí Arabia, mo sì tún padà wá sí Damasku.

181.18: Ap 9.26-30; 11.30.Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, 19èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ aposteli, bí kò ṣe Jakọbu arákùnrin Olúwa. 20Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí, kíyèsi i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.

21Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia. 22Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea. 23Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.” 24Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

加拉太書 1:1-24

1我是保羅,我作使徒並非受人委派,也不是倚靠人,而是由耶穌基督和叫祂從死裡復活的父上帝委派的。 2我和所有跟我在一起的弟兄寫信給加拉太的各教會。

3願我們的父上帝和主耶穌基督賜給你們恩典和平安! 4基督遵照我們父上帝的旨意為我們的罪獻上了自己,好拯救我們脫離這罪惡的世代。

5願榮耀歸給上帝,直到永永遠遠。阿們!

勿隨別的福音

6我很驚訝,你們竟然那麼快就背棄了藉著基督的恩典呼召你們的上帝,去追隨別的福音! 7其實那並不是福音,只是某些人擾亂你們的信仰,想篡改基督的福音。 8即便是我們或天使,若另傳福音給你們,與我們以前傳給你們的相悖,也該受咒詛。 9我們已經說過,現在我再說一次:如果有人向你們傳別的福音,跟你們以前接受的不同,那人該受咒詛。

10我現在是要贏得人的贊同嗎?還是要贏得上帝的贊同?難道我是要討好人嗎?如果我仍舊要討好人,我就不是基督的奴僕了。

保羅受上帝委派傳福音

11弟兄姊妹,我告訴你們,我傳的福音不是出於人的意思, 12因為這福音既不是我從人那裡領受的,也不是我跟人學來的,而是耶穌基督親自啟示我的。 13你們都聽說過我信奉猶太教時的所作所為,我怎樣殘酷地迫害上帝的教會,試圖摧毀它。 14我在猶太教裡比許多同輩的猶太人更進取,狂熱地維護祖先的傳統。

15然而,當我還在母腹中的時候,上帝就施恩將我分別出來並呼召了我。 16上帝既然樂意把祂的兒子啟示給我,叫我向外族人傳揚祂的福音,我就沒有跟任何人1·16 」希臘文是「血肉」。商量, 17也沒有上耶路撒冷去見那些比我先作使徒的人,而是立刻去了阿拉伯,然後回到大馬士革

18過了三年,我才到耶路撒冷去拜會彼得,和他一起住了十五天。 19我也見了主耶穌的弟弟雅各,此外沒有見過其他使徒。 20我在上帝面前保證,我寫給你們的絕無謊言。

21後來我又到了敘利亞基利迦地區。 22那時,猶太境內基督的眾教會都還沒有見過我的面。 23他們只是聽人說:「那個從前迫害我們的人如今在傳揚他曾試圖摧毀的信仰。」 24於是他們因為我的緣故將榮耀歸給上帝。