Ètò ibùdó ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan
1Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: 2“Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”
3Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn:
ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu. 4Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600).
5Ẹ̀yà Isakari ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Isakari ni Netaneli ọmọ Ṣuari. 6Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400).
7Ẹ̀yà Sebuluni ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni. 8Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400).
9Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàléláàdọ́run ó-lé-irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.
10Ní ìhà gúúsù:
ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 11Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlélógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (46,500).
12Ẹ̀yà Simeoni ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Simoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. 13Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje. (59,300).
14Ẹ̀yà Gadi ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli. 15Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,650).
16Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-márùn-dínlọ́gọ́rin ó-lé-àádọ́ta-lé-légbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.
17Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi Àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.
18Ní ìhà ìlà-oòrùn:
ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu. 19Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (40,500).
20Ẹ̀yà Manase ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Manase ni Gamalieli ọmọ Pedasuri. 21Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-igba (32,200).
22Ẹ̀yà Benjamini ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni. 23Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).
24Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìnléláàdọ́ta ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
25Ní ìhà àríwá:
ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 26Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ̀gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700).
27Ẹ̀yà Aṣeri ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okanri. 28Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).
29Ẹ̀yà Naftali ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Naftali ni Ahira ọmọ Enani. 30Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-egbèje (53,400).
31Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gọ̀rin ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.
32Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta (603,550). 33Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Lefi papọ̀ mọ́ àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.
34Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.