Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 24:1-53

Àjíǹde náà

124.1-9: Mt 28.1-8; Mk 16.1-7; Jh 20.1,11-13.Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú ìkunra olóòórùn dídùn ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá. 2Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì. 3Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jesu Olúwa. 4Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n: 5Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn angẹli náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrín àwọn òkú? 624.6: Lk 9.22; 13.32-33.Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili. 7Pé, ‘A ó fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.’ ” 8Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

9Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù. 1024.10: Mk 16.1; Lk 8.1-3; Jh 20.2.Maria Magdalene, àti Joanna, àti Maria ìyá Jakọbu, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn aposteli. 11Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́. 12Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.

Ní ojú ọnà sí Emmausi

13Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀. 14Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀. 15Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ. 1624.16: Jh 20.14; 21.4.Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.

17Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”

Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro. 18Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”

1924.19: Mt 21.11; Lk 7.16; 13.33; Ap 3.22.Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, 20Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú. 21Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀. 22Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu: 23Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè. 2424.24: Jh 20.3-10.Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”

25Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́: 26Kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.” 2724.27: Lk 24.44-45; Ap 28.23; 1Pt 1.11.Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.

2824.28: Mk 6.48.Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú. 29Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.

3024.30: Lk 9.16; 22.19.Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn. 31Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú 32Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”

33Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn, 3424.34: 1Kọ 15.5.Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!” 35Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.

Jesu fi ara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

3624.36-43: Jh 20.19-20,27; Jh 21.5,9-13; 1Kọ 15.5; Ap 10.40-41.Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jesu tìkára rẹ̀ dúró láàrín wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”

37Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì wárìrì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan. 38Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín? 3924.39: 1Jh 1.1.Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkára mi ni! Ẹ dì mímú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”

40Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n. 41Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhìn-ín yìí?” 42Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè. 43Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.

4424.44: Lk 24.26-27; Ap 28.23.Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”

45Nígbà náà ni ó ṣí wọn ní iyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn. 4624.46: Ho 6.2; 1Kọ 15.3-4.Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú: 4724.47: Ap 1.4-8; Mt 28.19.Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ. 48Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí. 4924.49: Ap 2.1-4; Jh 14.26; 20.21-23.Èmi yóò rán ohun tí Baba mi ṣe ìlérí sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerusalẹmu, títí a ó fífi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”

Ìgòkè re ọ̀run

50Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Betani, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn. 5124.51: Ap 1.9-11.Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run. 5224.52-53: Ap 1.12-14.Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀: 53Wọ́n sì wà ní tẹmpili nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run.

Knijga O Kristu

Luka 24:1-53

Isusovo uskrsnuće

(Mt 28:1-10; Mk 16:1-8; Iv 20:1-9)

1U osvit dana u nedjelju24:1 U grčkome: prvoga dana tjedna. dođu na grob s miomirisima što su ih pripravile 2i nađu kamen s ulaza u grob odmaknut. 3Ušle su unutra, ali nisu našle tijelo Gospodina Isusa. 4Dok su tako zbunjene stajale, uz njih se pojave dva čovjeka u blistavoj odjeći. 5Žene se prestraše i poniknu licem prema zemlji. “Zašto tražite živoga među mrtvima?” upitaju ih dvojica. 6“Nije ovdje, uskrsnuo je! Sjetite se što vam je govorio još u Galileji: 7‘Sina Čovječjega predat će u ruke grešnicima i raspet će ga, ali on će treći dan uskrsnuti.’”

8One se sjete da je Isus to rekao. 9Požure zato s groba to javiti jedanaestorici učenika i ostalima. 10Bile su to Marija Magdalena, Ivana i Marija, majka Jakovljeva, i još neke žene. Sve su one to ispričale apostolima, 11ali njima se činilo da je sve to izmišljotina. I nisu im vjerovali. 12Ipak, Petar potrči do groba. Kad je stigao, proviri unutra i spazi samo povoje od lanena platna. Vrati se zatim čudeći se onomu što se dogodilo.

Isus se ukazuje učenicima na putu u Emaus

13Toga su dana dvojica Isusovih sljedbenika putovala u selo Emaus, udaljeno od Jeruzalema jedanaest kilometara.24:13 U grčkome: šezdeset stadija. 14Putem su razgovarali o svemu što se dogodilo. 15Dok su tako razgovarali i raspravljali, pristupi im Isus i pođe s njima. 16Ali njihovim je očima bilo uskraćeno da ga prepoznaju.

17“O čemu to raspravljate putujući?” upita ih.

Oni zastanu, shrvani tugom. 18Jedan od njih, imenom Kleofa, odgovori mu: “Ti si, čini se, jedini tuđinac u Jeruzalemu koji ne zna što se ondje dogodilo ovih dana.”

19“Što se dogodilo?” upita Isus.

“Pa to s Isusom Nazarećaninom”, rekli su. “On je bio prorok silan i na riječi i na djelima pred Bogom i pred svim narodom. 20Ali naši svećenički poglavari i članovi Velikog vijeća predali su ga da bude osuđen na smrt te su ga raspeli. 21A mi smo se nadali da je on Otkupitelj koji će spasiti Izrael. Osim toga, već je treći dan otkako se to dogodilo. 22Još su nas i neke žene, koju su ga s nama slijedile, zbunile: čim je svanulo otišle su na grob, 23ali ondje nisu našle njegovo tijelo. Došle su i rekle da su im se ukazali anđeli i kazali im da je živ. 24Neki od nas pojurili su na grob i našli su sve kao što su žene ispričale, ali njega nisu vidjeli.”

25“Neumnici!” reče im nato Isus. “Nikako da povjerujete sve što su proroci navijestili. 26Nisu li oni prorekli da će Krist morati sve to pretrpjeti prije nego što uđe u svoju slavu?” 27Zatim im, započevši od Mojsija, protumači što su svi proroci o njemu zapisali u Svetome pismu.

28Približili su se već selu kamo su išli, a Isus se pričini da će nastaviti put. 29Ali oni su ga nagovarali: “Ostani s nama! Već je večer; dan je na izmaku!” On ostane i uđe s njima u kuću. 30Dok je sjedio s njima za stolom, Isus uzme kruh, blagoslovi ga i razlomi te im ga dade. 31Uto se njima otvore oči pa ga prepoznaju, a on nestane.

32“Nije li nam srce usplamtjelo kad nam je putem pričao i tumačio Pisma?” upitaju oni jedan drugoga. 33Smjesta se spreme i vrate u Jeruzalem. Ondje nađu na okupu Jedanaestoricu i ostale Isusove sljedbenike. 34“Gospodin je zaista uskrsnuo!” kazaše im. “Zaista se ukazao Šimunu!”

Isus se pojavljuje pred učenicima

(Iv 20:19-23)

35Ispripovijedaju im zatim susret s Gospodinom na putu u Emaus te kako su ga prepoznali kad je razlomio kruh. 36Dok su oni o tome razgovarali, Isus odjednom stane među njih. “Mir vama!” reče im. 37Zbunjeni i prestrašeni, mislili su da vide duha. 38Ali Isus im reče: “Zašto se bojite? Zašto vam se sumnja rađa u srcu? 39Pogledajte mi ruke i noge! Ja sam to! Opipajte me pa ćete vidjeti! Duhovi nemaju kostiju i mesa kao ja!” 40Pokaže im svoje ruke i noge.

41Od čuđenja i veselja nisu mogli vjerovati. On upita: “Imate li što za jelo?” 42Pruže mu komad pečene ribe, 43a on ga uzme i pojede pred njima.

44Reče zatim: “O ovome sam vam govorio dok sam prije bio s vama: Trebalo se ispuniti sve što u Mojsijevu zakonu, proročkim knjigama i psalmima piše o meni.” 45Otvori im zatim um da razumiju Sveto pismo 46pa reče: “Piše da će Krist trpjeti i treći dan ustati od mrtvih. 47U njegovo ime propovijedajte obraćenje i oproštenje grijeha svim narodima počevši od Jeruzalema. 48Vi ste svjedoci toga.

49A ja ću vam poslati Svetoga Duha, baš kao što je Otac obećao. Ostanite u gradu dok vas Sveti Duh ne ispuni silom odozgora!”

Uzašašće

(Mk 16:19-20; Djela 1:9-11)

50Isus ih zatim povede u blizinu Betanije. Ondje podigne ruke i blagoslovi ih. 51Tako se, blagoslivljajući ih, i rastane od njih: uznesen je na nebo. 52Oni mu se ničice poklone, a zatim se silno radosni vrate u Jeruzalem. 53Ondje su u Hramu neprestano slavili Boga.