Lefitiku 14 – YCB & APSD-CEB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 14:1-57

Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ tó mú awọ ara

1Olúwa sọ fún Mose pé, 214.2-32: Mt 8.4; Mk 1.44; Lk 5.14; 17.14.“Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú un tọ àlùfáà wá. 3Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà. 4Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́. 5Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀. 6Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi kedari, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà. 7Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ kúrò nínú ààrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ìta gbangba.

8“Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje. 9Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.

10“Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àgbò aláìlábùkù méjì àti abo ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pòpọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n lógù òróró kan. 11Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́, yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá síwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

12“Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti lógù òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Kí ó sì fì wọ́n níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì. 13Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ. 14Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. 15Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú lógù òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. 16Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje. 17Àlùfáà yóò mú lára òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ yóò fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí à ó wẹ̀mọ́, lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi. 18Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa.

19“Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun. 20Kí àlùfáà kí ó sì rú ẹbọ sísun, àti ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà kí ó sì ṣe ètùtù fún un, òun yóò sì di mímọ́.

21“Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òsùwọ̀n lógù òróró 22àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.

23“Kí ó mú wọn wá ní ọjọ́ kẹjọ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa. 24Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì. 25Kí ó pa ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kí ó fi sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún. 26Àlùfáà yóò sì da díẹ̀ lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. 27Yóò sì fi ìka ìfábẹ̀lá ọ̀tún rẹ̀ wọ́n òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ nígbà méje níwájú Olúwa. 28Àlùfáà yóò sì mú lára òróró ọwọ́ rẹ̀ sí etí ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ní ibi kan náà tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí. 29Kí àlùfáà fi ìyókù nínú òróró ọwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni náà tí a ń ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún, láti ṣe ètùtù fún un ní iwájú Olúwa. 30Lẹ́yìn náà kí ó fi àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé rú ẹbọ níwọ̀n tí agbára rẹ̀ mọ. 31Ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù níwájú Olúwa ní ipò ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́.”

32Òfin nìyí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ààrùn ara tí ó le ran tí kò sì lágbára láti rú ẹbọ tí ó yẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ bí a ti fi lélẹ̀.

Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ ní inú ilé

33Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé. 34“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fi fún yín ní ìní, tí mo sì fi ààrùn ẹ̀tẹ̀ sínú ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín. 35Kí ẹni tí ó ní ilé náà lọ sọ fún àlùfáà pé, ‘Èmi tí rí ohun tí ó jọ ààrùn ẹ̀tẹ̀ ní ilé mi.’ 36Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò. 37Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ. 38Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje. 39Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri. 40Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí ààrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú. 41Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà. 42Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.

43“Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ. 44Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́. 45Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.

46“Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 47Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.

48“Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí ààrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé ààrùn náà ti lọ. 49Láti sọ ilé yìí di mímọ́. Àlùfáà yóò mú ẹyẹ méjì àti igi kedari òdòdó àti hísópù. 50Yóò sì pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ nínú ìkòkò amọ̀. 51Kí ó ri igi kedari, hísópù, òdòdó àti ààyè ẹyẹ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ òkú ẹyẹ àti omi tí ó mọ́ náà kí ó fi wọ́n ilẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje. 52Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi kedari, hísópù àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́. 53Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.”

54Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyìí ààrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká, fún làpálàpá, 55àti fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, àti ti ilé, 56fún ara wíwú, fún èélá àti ibi ara tí ó ń dán yàtọ̀. 57Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́.

Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ààrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀.

Ang Pulong Sa Dios

Leviticus 14:1-57

Ang Patakaran sa Paghinlo sa Tawong Naayo sa Iyang Ngilngig nga Sakit sa Panit

1-2Mao kini ang mga patakaran nga giingon sa Ginoo kang Moises mahitungod sa paghinlo sa tawong naayo sa iyang ngilngig nga sakit sa panit:

Human pahibaloon ang pari mahitungod sa kahimtang sa sakit sa usa ka tawo, 3mogawas ang pari sa kampo ug tan-awon niya ang lawas niadtong tawo. Kon naayo na ang iyang ngilngig nga sakit sa panit, 4magpakuha ang pari ug duha ka langgam nga buhi nga giisip nga hinlo,14:4 nga giisip nga hinlo: Ang buot ipasabot, mahimong kan-on o ihalad sa Ginoo. usa ka putol sa kahoyng sedro, pula nga higot, ug usa ka pungpong nga isopo. 5Unya ipaihaw sa pari ang usa ka langgam diha ibabaw sa kolon nga gisudlan ug tubig gikan sa tuboran. 6Unya kuhaon sa pari ang buhi nga langgam ug ituslob niya kini uban sa kahoyng sedro, pula nga higot, ug isopo, didto sa dugo sa langgam nga giihaw ibabaw sa kolon nga may tubig. 7Dayon wisik-wisikan niyag makapito ang tawong naayo sa iyang ngilngig nga sakit sa panit. Pagkahuman ipahibalo niya nga hinlo na ang maong tawo, ug buhian niya ang langgam.

8Apan sa dili pa ipahibalo nga hinlo na siya, labhan una sa tawo ang iyang bisti, kagisan ang tanan niyang buhok ug balhibo, ug maligo. Mahimo na siyang mosulod sa kampo apan dili siya mopuyo sa iyang tolda sulod sa pito ka adlaw. 9Sa ikapito ka adlaw, kagisan niya pag-usab ang tanan niyang buhok ug balhibo, labhan niya ang iyang bisti, ug maligo.

10Sa ikawalo nga adlaw, kinahanglan nga magdala siya ug duha ka laking karnero ug usa ka bayeng karnero nga usa ka tuig, ug walay depekto. Magdala usab siya ug unom ka kilo nga maayong klase sa harina nga sinagolan ug mantika isip halad sa pagpasidungog sa Ginoo. Ug magdala pa gayod siyag usa ka basong mantika. 11Unya dad-on siya sa pari nga mopahibalo nga hinlo na siya, ngadto sa presensya sa Ginoo didto sa pultahan sa Tolda nga Tagboanan, uban sa iyang mga halad.

12Dayon kuhaon sa pari ang usa sa laking karnero ug ang usa ka basong lana, ug ihalad niya kini isip halad nga bayad sa sala. Unya ibayaw niya kini sa presensya sa Ginoo isip halad nga binayaw. 13Ihawon niya ang karnero didto sa balaan nga dapit, sa ihawanan sa halad sa paghinlo ug sa halad nga sinunog. Kining halad nga karnero balaan kaayo, ug iya na kini sa pari sama usab sa halad sa paghinlo. 14Unya magkuha ang pari ug dugo sa karnerong gihalad ug ipahid niya kini sa ubos nga bahin sa tuong dalunggan sa tawo nga ginahinloan, ug sa kumagko sa tuong kamot ug tiil niini. 15Magbutang usab ang pari ug lana diha sa iyang wala nga palad, 16ug ituslob niya sa lana ang iyang tudlo sa tuong kamot ug iwisik-wisik kini makapito didto sa presensya sa Ginoo. 17Ang ubang lana sa iyang palad ipahid niya sa ubos nga bahin sa tuong dalunggan ug sa kumagko sa tuong kamot ug tiil niadtong tawo nga ginahinloan. 18-20Ang nahibilin pa nga lana sa palad sa pari ipahid niya sa ulo sa tawo. Unya ihalad sa pari ang halad sa paghinlo. Pagkahuman, ihawon sa pari ang halad nga sinunog ug ihalad niya kini didto sa halaran uban sa halad sa pagpasidungog sa Ginoo. Pinaagi niining himuon sa pari diha sa presensya sa Ginoo, makuha ang pagkahugaw sa tawo ug mahimo na siyang hinlo.

21Apan kon ang maong tawo kabos ug dili makahimo sa paghalad niini nga mga halad, magdala na lang siya ug usa ka karnero nga laki nga ihalad niya isip bayad sa sala. Ibayaw niya kini nga halad aron makuha ang iyang mga sala ug mahimo na siyang hinlo. Magdala usab siya ug duha ka kilo nga maayong klase sa harina nga sinagolan ug mantika isip halad sa pagpasidungog sa Ginoo. Ug magdala pa gayod siyag usa ka basong mantika. 22Ug sumala lang sa iyang makaya, magdala siyag duha ka salampati o duha ka tukmo; ang usa halad sa paghinlo ug ang usa halad nga sinunog.

23Sa ikawalo nga adlaw, dad-on niya kining tanan nga halad ngadto sa pari didto sa pultahan sa Tolda nga Tagboanan, sa presensya sa Ginoo. 24Kuhaon sa pari ang karnero nga halad isip bayad sa sala ug ang usa ka basong lana, ug ibayaw niya kini sa presensya sa Ginoo isip halad nga binayaw. 25Unya ihawon niya ang karnero ug magkuha siyag dugo niini ug ipahid niya sa ubos nga bahin sa tuong dalunggan sa tawo nga ginahinloan, ug sa kumagko sa tuong kamot ug tiil niini. 26Unya magbutang ang pari ug lana sa iyang wala nga palad, 27ug pinaagi sa iyang tudlo sa tuong kamot, iwisik-wisik niya ang lana makapito didto sa presensya sa Ginoo. 28Ang ubang lana sa iyang palad ipahid gihapon niya sa ubos nga bahin sa tuong dalunggan ug sa kumagko sa tuong kamot ug tiil niadtong tawo nga ginahinloan. 29-31Ang nahibilin pa nga lana sa palad sa pari ipahid niya sa ulo sa tawo. Unya ihalad sa pari ang duha ka salampati o ang duha ka tukmo; ang usa halad sa paghinlo ug ang usa halad nga sinunog. Ihalad usab niya ang halad sa pagpasidungog sa Ginoo. Pinaagi niining himuon sa pari diha sa presensya sa Ginoo mahinloan ang tawo. 32Mao kini ang mga patakaran mahitungod sa paghinlo sa tawong may ngilngig nga sakit sa panit kon dili siya makakaya sa halad nga ihalad alang sa paghinlo.

Ang mga Patakaran bahin sa Agup-op nga Motubo sa Balay

33Mao kini ang giingon sa Ginoo kang Moises ug kang Aaron 34mahitungod sa ilang buhaton kon patuboan sa Ginoo ug agup-op14:34 agup-op: Kining klaseha sa agup-op nga motubo sa mga bahin sa balay dili kasagaran nga makita dinhi sa Pilipinas. Tan-awa usab ang “footnote” sa 13:2. ang ilang mga balay kon atua na sila sa Canaan, ang dapit nga ihatag sa Ginoo kanila nga ilang panag-iyahon:

35Kon ang tag-iya sa usa ka balay makamatikod nga dunay morag agup-op sa iyang balay, kinahanglan nga sultihan niya ang pari. 36Sa dili pa mosulod ang pari niadto nga balay aron susihon ang agup-op, magsugo una siya nga ipagawas ang tanang mga butang sa sulod, aron dili kini maapil ug maisip nga hugaw. Pagkahuman mosulod ang pari sa balay 37ug susihon niya ang agup-op nga anaa sa bongbong. Ug kon makita niya nga may pagkaberde o may pagkapula-pula ang nagalupyak sa bongbong, 38mogawas siya sa maong balay ug pasirad-an niya kini sulod sa pito ka adlaw. 39Sa ikapito nga adlaw, susihon niya kini pag-usab. Ug kon ang agup-op mikuyanap sa ubang bahin sa bongbong, 40ipakuha niya ang mga bahin sa bongbong nga may agup-op ug ipalabay kini didto sa gawas sa lungsod, sa dapit nga labayanan sa mga butang nga giisip nga hugaw. 41Pakiskisan niya ang tanang bahin sa bongbong sulod sa balay ug ang tanang kiniskis ipalabay niya sa gawas sa lungsod, sa dapit nga labayanan sa mga butang nga giisip nga hugaw. 42Unya pailisan niya ang tanang bahin sa bongbong nga nakiskisan.

43Apan kon human niadto agup-opon pa gihapon ang balay, 44adtoon kini pag-usab sa pari ug susihon. Kon mikuyanap gani ang agup-op, isipon na kadtong balaya nga hugaw kay kini nga matang sa agup-op nagabalik-balik. 45Busa ipaguba niya ang balay ug ang mga materyales niini ipalabay sa gawas sa lungsod, sa dapit nga labayanan sa mga butang nga giisip nga hugaw.

46Si bisan kinsa nga mosulod niini nga balay sa dihang gisirad-an kini isipon nga hugaw hangtod sa pagsalop sa adlaw. 47Ug si bisan kinsa nga matulog o mokaon sulod niining balaya kinahanglan niyang labhan ang iyang bisti.14:47 Tan-awa usab ang 11:24-28.

48Apan kon sa pagsusi sa pari wala na agup-opa ang balay human mailisi ang bahin sa bongbong nga giagup-opan, ipahibalo sa pari nga hinlo na ang maong balay. 49Ug aron nga isipon nga hinlo na gayod ang balay, magkuha ang pari ug duha ka langgam, kahoyng sedro, pulang higot, ug isopo. 50Ihawon niya ang usa ka langgam diha ibabaw sa kolon nga gibutangan ug tubig nga gikan sa tuboran. 51Unya kuhaon niya ang kahoyng sedro, ang pulang higot, ang isopo, ug ang buhi nga langgam, ug ituslob niya kining tanan sa tubig nga may dugo sa langgam nga giihaw. Ug wisik-wisikan niya makapito ang balay. 52Busa pinaagi sa dugo sa langgam, sa tubig nga gikan sa tuboran, sa buhi nga langgam, sa kahoyng sedro, sa isopo, ug sa pulang higot, mahinloan sa pari ang balay. 53Unya buhian niya ang langgam nga buhi didto sa gawas sa lungsod. Pinaagi niining himuon sa pari, makuha ang kahugaw sa balay ug mahimo na kining hinlo.

54-57Mao kadto ang mga patakaran mahitungod sa mga ngilngig nga sakit sa panit nga nuka, hubag-hubag, butoy-butoy, o katol-katol, ug mahitungod sa talumtom sa mga bisti ug agup-op sa balay. Pinaagi niini nga mga patakaran, masayran ninyo kon unsa ang hinlo ug ang hugaw.