Johanu 2 – YCB & PCB

Yoruba Contemporary Bible

Johanu 2:1-25

Jesu sọ omi di ọtí wáìnì

12.1: Jh 4.46; 21.2.Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀, 2A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà. 32.3: Jh 19.26; Mk 3.31.Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”

42.4: Mk 1.24; 5.7; Jh 7.6,30; 8.20.Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”

5Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”

62.6: Mk 7.3; Jh 3.25.Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá.

7Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.

8Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.”

Wọ́n sì gbé e lọ; 9alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan, 10Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”

112.11: Jh 2.23; 3.2; 4.54; 6.2.Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ ààmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

Jesu ṣe àfọ̀mọ́ tẹmpili

122.12: Mt 4.13; Jh 7.3; Mk 3.31.Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu, Òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

132.13: Jh 6.4; 11.55; De 16.1-6; Lk 2.41.Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu, 142.14-16: Mt 21.12-13; Mk 11.15-17; Lk 19.45-46.Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nínú tẹmpili wọ́n jókòó: 15Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú. 162.16: Lk 2.49.Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.” 172.17: Sm 60.9.Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

182.18: Mk 11.28; Mt 21.23; Lk 20.2.Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Ààmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

192.19: Mk 14.58; Ap 6.14.Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

20Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?” 212.21: 1Kọ 6.19; Jh 8.57.Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀. 222.22: Jh 12.16; 14.26.Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.

23Nígbà tí ó sì wà ní Jerusalẹmu, ní àjọ ìrékọjá, lákokò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì tí ó ṣe. 24Ṣùgbọ́n Jesu kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn. 252.25: Jh 1.47; 6.61; 13.11; Mk 2.8.Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn: nítorí tí o mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.

Persian Contemporary Bible

یوحنا 2:1-25

معجزه در عروسی

1دو روز بعد، مادر عیسی در یک جشن عروسی در دهکدهٔ قانا در جلیل میهمان بود. 2عیسی و شاگردان او نیز به عروسی دعوت شده بودند. 3هنگام جشن، شراب تمام شد. مادر عیسی با نگرانی نزد او آمد و گفت: «شراب ندارند!»

4عیسی فرمود: «بانوی گرامی، چرا مرا درگیر این کار می‌سازی؟ زمان من هنوز فرا نرسیده است.»

5با این حال، مادر عیسی به خدمتکاران گفت: «هر چه به شما می‌گوید، انجام دهید.»

6در آنجا شش خمرهٔ سنگی بود که فقط در مراسم مذهبی یهودیان از آن استفاده می‌شد و گنجایش هر یک حدود صد لیتر بود.

7عیسی به خدمتکاران فرمود: «این خمره‌ها را پر از آب کنید.» 8وقتی پر کردند، فرمود: «حالا کمی از آن را بردارید و نزد رئیس مجلس ببرید!»

9رئیس مجلس خبر نداشت آن آب را که شراب شده بود، از کجا آورده‌اند (هرچند خدمتکاران می‌دانستند). پس وقتی آن را چشید، داماد را صدا زد 10و گفت: «میزبانان همیشه با شراب خوب از میهمانان پذیرایی می‌کنند و بعد که همه سرشان گرم شد، شراب ارزانتر را می‌آورند. ولی تو شراب خوب را برای آخر نگه داشته‌ای.»

11بدین ترتیب عیسی نخستین نشانۀ معجزه‌آسای خود را در قانای جلیل به ظهور آورد و جلال خود را آشکار ساخت و شاگردانش به او ایمان آوردند.

عیسی در معبد

12سپس عیسی با مادر، برادران و شاگردان خود برای چند روز به شهر کَفَرناحوم رفت.

13عید پِسَح که یکی از اعیاد بزرگ یهود بود، نزدیک می‌شد. پس عیسی به شهر اورشلیم رفت. 14آنجا، در معبد، مردم را دید که برای انجام مراسم قربانی، به خرید و فروش گاو، گوسفند و کبوتر مشغولند. صرّافان پولها را روی میزها چیده بودند و با مشتری‌ها داد و ستد می‌کردند.

15عیسی با طناب، تازیانه‌ای ساخت و همه را از آنجا بیرون کرد. او گاوان و گوسفندان را بیرون راند و سکه‌های صرافان را بر زمین ریخت و میزهای ایشان را واژگون ساخت. 16سپس به سراغ کبوترفروشان رفت و گفت: «اینها را از اینجا بیرون ببرید و خانهٔ پدر مرا به بازار تبدیل نکنید.»

17آنگاه شاگردان او آن نبوّت کتب مقدّس را به یاد آوردند که می‌فرماید: «اشتیاقی که برای خانۀ تو دارم، مثل آتش در من زبانه می‌کشد.»2‏:17 مزمور ۶۹‏:۹.

18سران قوم یهود از عیسی پرسیدند: «تو چه اجازه و اختیاری داری که این کارها را انجام دهی؟ اگر خدا اجازۀ این را به تو داده، با نشانه‌ای معجزه‌آسا آن را به ما ثابت کن!»

19عیسی جواب داد: «بسیار خوب، معجزه‌ای که برای شما می‌کنم این است: این معبد را خراب کنید تا من در عرض سه روز آن را دوباره بسازم!»

20گفتند: «چه می‌گویی؟ چهل و شش سال طول کشید تا این خانه را ساختند. تو می‌خواهی در سه روز آن را بسازی؟»

21ولی منظور عیسی از «این معبد»، بدن خودش بود. 22پس از اینکه عیسی از میان مردگان برخاست و زنده شد، شاگردانش این گفتهٔ او را به یاد آوردند. آنگاه به کتب مقدّس و نیز به کلام عیسی ایمان آوردند.

23به خاطر نشانه‌های معجزآسای او در روزهای عید، بسیاری در اورشلیم به او ایمان آوردند. 24ولی عیسی به آنها اعتماد نکرد، چون از قلب مردم آگاه بود، 25و لازم نبود کسی به او بگوید که مردم چقدر زود تغییر عقیده می‌دهند، چون او انسان را خوب می‌شناخت.