የኢየሱስ መፈተን
4፥1-11 ተጓ ምብ – ማር 1፥12፡13፤ ሉቃ 4፥1-13
1ከዚህ በኋላ መንፈስ ቅዱስ ኢየሱስን በዲያብሎስ ይፈተን ዘንድ ወደ ምድረ በዳ ወሰደው። 2አርባ ቀንና አርባ ሌሊት ከጾመ በኋላ ተራበ። 3ፈታኙም ወደ ኢየሱስ ቀርቦ፣ “የእግዚአብሔር ልጅ ከሆንህ እነዚህን ድንጋዮች እንጀራ እንዲሆኑ እዘዝ” አለው።
4ኢየሱስም፣ “ ‘ሰው ከእግዚአብሔር አፍ በሚወጣው ቃል ሁሉ እንጂ በእንጀራ ብቻ አይኖርም’ ተብሎ ተጽፏል” ሲል መለሰለት።
5ቀጥሎም ዲያብሎስ ኢየሱስን ወደ ቅድስት ከተማ በመውሰድ ከቤተ መቅደሱም ዐናት ላይ አውጥቶ፣ 6“የእግዚአብሔር ልጅ ከሆንህ ራስህን ወደ መሬት ወርውር፤ እንዲህ ተብሎ ተጽፏልና፤
“ ‘እግርህ በድንጋይ እንዳይሰናከል፣
በእጃቸው ያነሡህ ዘንድ፣
መላእክቱን ስለ አንተ ያዝዝልሃል።’ ”
7ኢየሱስም፣ “እንደዚሁም በመጻሕፍት፣ ‘እግዚአብሔር አምላክህን አትፈታተነው’ ተብሎ ተጽፏል” በማለት መለሰለት።
8እንደ ገናም ዲያብሎስ ኢየሱስን እጅግ ከፍ ወዳለ ተራራ አወጣው፤ የዓለምንም መንግሥታት ከነክብራቸው አሳየውና፣ 9“ወድቀህ ብትሰግድልኝ ይህን ሁሉ እሰጥሃለሁ” አለው።
10ኢየሱስም፣ “አንተ ሰይጣን ከፊቴ ራቅ! ‘ለአምላክህ ለእግዚአብሔር ስገድ፤ እርሱንም ብቻ አምልክ’ ተብሎ ተጽፏልና” አለው።
11ከዚያም ዲያብሎስ ትቶት ሄደ፤ መላእክትም መጥተው አገለገሉት።
ኢየሱስ ስብከት መጀመሩ
12ኢየሱስ የዮሐንስን መታሰር በሰማ ጊዜ ወደ ገሊላ ተመለሰ። 13የናዝሬትንም ከተማ ትቶ፣ በዛብሎንና በንፍታሌም አካባቢ በባሕሩ አጠገብ በምትገኘው በቅፍርናሆም ከተማ መኖር ጀመረ። 14በዚህም በነቢዩ ኢሳይያስ እንዲህ ተብሎ የተነገረው ትንቢት ተፈጸመ፤
15“የዛብሎን ምድር፣ የንፍታሌም ምድር፣
ከዮርዳኖስ ማዶ በባሕር መንገድ አጠገብ፣
ያለው የአሕዛብ ገሊላ፣
16በጨለማ የሚኖር ሕዝብ፣
ታላቅ ብርሃን አየ፤
በሞት ጥላ ምድር ላለው፣
ብርሃን ወጣለት።”
17ከዚያ ጊዜ አንሥቶ ኢየሱስ፣ “ንስሓ ግቡ፤ መንግሥተ ሰማያት ቀርባለችና” እያለ መስበክ ጀመረ።
የመጀመሪያዎቹ ደቀ መዛሙርት መጠራት
4፥18-22 ተጓ ምብ – ማር 1፥16-20፤ ሉቃ 5፥2-11፤ ዮሐ 1፥35-42
18ኢየሱስ በገሊላ ባሕር አጠገብ ሲያልፍ፣ ሁለት ወንድማማቾች ማለትም፣ ጴጥሮስ የተባለውን ስምዖንንና ወንድሙን እንድርያስን አያቸው። ዓሣ አጥማጆች ነበሩና መረባቸውን ወደ ባሕሩ ይጥሉ ነበር። 19ኢየሱስም፣ “ኑ፣ ተከተሉኝ፤ ሰዎችን አጥማጆች አደርጋችኋለሁ” አላቸው። 20ወዲያው መረባቸውን ትተው ተከተሉት።
21ዐለፍ እንዳለም፣ ሌሎች ሁለት ወንድማማቾች፣ የዘብዴዎስን ልጅ ያዕቆብንና ወንድሙን ዮሐንስን አየ። ከአባታቸው ከዘብዴዎስ ጋር በጀልባ ውስጥ መረባቸውን ያበጁ ነበር። ኢየሱስም ጠራቸው፤ 22ወዲያውኑ ጀልባቸውንም ሆነ አባታቸውን ትተው ተከተሉት።
የበሽተኞች መፈወስ
23ኢየሱስም በምኵራቦቻቸው እያስተማረ፣ የእግዚአብሔርን መንግሥት የምሥራች ቃል እየሰበከ፣ በሕዝቡ መካከል ማንኛውንም ደዌና ሕመም እየፈወሰ በመላው ገሊላ ይዘዋወር ነበር። 24ከዚህም የተነሣ ዝናው በመላዋ ሶርያ ተሰማ፤ ሕዝቡም በተለያዩ በሽታዎች የታመሙትን፣ በክፉ ደዌ የሚሠቃዩትን፣ አጋንንት ያደሩባቸውን፣ የሚጥል በሽታ ያለባቸውን፣ ሽባዎችን ሁሉ ወደ እርሱ አመጡ፤ ፈወሳቸውም። 25ከዚህም የተነሣ ከገሊላ፣ ከ “ዐሥሩ ከተሞች”፣ ከኢየሩሳሌም፣ ከይሁዳና ከዮርዳኖስ ማዶ የመጡ ብዙ ሰዎች ተከተሉት።
Ìdánwò Jesu
14.1-11: Mk 1.12-13; Lk 4.1-13; Hb 2.18; 4.15.Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jesu sí ijù láti dán an wò láti ọwọ́ èṣù. 24.2: El 34.28; 1Ọb 19.8.Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á. 3Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”
44.4: De 8.3.Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”
54.5: Mt 27.53; Ne 11.1; Da 9.24; If 21.10.Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. 64.6: Sm 91.11-12.Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé,
“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹ
wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn
kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
74.7: De 6.16.Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”
8Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. 9Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”
104.10: De 6.13; Mk 8.33.Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé, ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”
114.11: Mt 26.53; Lk 22.43.Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wàásù
124.12: Mk 1.14; Lk 4.14; Mt 14.3; Jh 1.43.Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili. 134.13: Jh 2.12; Mk 1.21; Lk 4.23.Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali. 14Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé,
154.15: Isa 9.1-2.“Ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali
ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani,
Galili ti àwọn kèfèrí.
16Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn
tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,
àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú
ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”
174.17: Mk 1.15; Mt 3.2; 10.7.Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”
Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
184.18-22: Mk 1.16-20; Lk 5.1-11; Jh 1.35-42.Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n. 19Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 20Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
21Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. 22Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Jesu ṣe ìwòsàn
234.23-25: Mk 1.39; Lk 4.15,44; Mt 9.35; Mk 3.7-8; Lk 6.17.Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. 25Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.