Jeremiah 52 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 52:1-34

Ìṣubú Jerusalẹmu

1Sedekiah jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Ọdún mọ́kànlá ló fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali ọmọ Jeremiah; láti Libina ló ti wá. 252.2: 2Ọb 24.18–25.30; 2Ki 36.11-13.Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe 3Nítorí ìbínú Olúwa ni gbogbo èyí ṣe ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu àti Juda àti ní ìkẹyìn. Ó sì gbà wọ́n gbọ́ ní iwájú rẹ̀.

Sedekiah ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.

4Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ti Sedekiah tí ń ṣe ìjọba ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹwàá Nebukadnessari ọba Babeli sì lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà; wọ́n sì mọ odi yíká rẹ̀. 5Ìlú náà sì wá lábẹ́ ìhámọ́ títí di ọdún kọkànlá ọba Sedekiah.

6Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù mẹ́rin ìyàn ìlú náà sì ti burú dé ibi pé kò sí oúnjẹ kankan mọ́ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 7Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ-ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrín odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Àwọn ará Babeli yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ. 8Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ogun Babeli lépa ọba Sedekiah wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká. 9Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn.

Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 10Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda. 11Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

12Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù karùn-ún, tí ó jẹ́ ọdún kọkàn-dínlógún Nebukadnessari ọba Babeli, ni Nebusaradani balógun ìṣọ́ wá sí Jerusalẹmu. 13Ó dáná sun pẹpẹ Olúwa, ààfin ọba àti gbogbo àwọn ilé Jerusalẹmu. Ó sì dáná sun gbogbo àwọn ilé ńláńlá. 14Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 15Nebusaradani balógun ìṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 16Ṣùgbọ́n Nebusaradani, balógun ìṣọ́ fi àwọn tálákà tó kú ní ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti ro oko.

17Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, Wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Babeli. 18Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ. 19Balógun ìṣọ́ náà kó àwokòtò wọ̀n-ọn-nì, ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, ṣíbí wọ̀n-ọn-nì àti ago wáìnì wọ̀n-ọn-nì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.

20Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ. 21Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́n yìí ni ga ní ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlógún; okùn ìgbọ̀nwọ́ méjìlá sì yí i ká. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú. 22Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èso pomegiranate ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èso pomegiranate tí ó jọra. 23Pomegiranate mẹ́rìn-dínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranate sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún kan.

24Balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ mu Seraiah olórí àwọn àlùfáà àti Sefaniah àlùfáà kejì àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 25Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú ìwẹ̀fà kan, tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà. 26Nebusaradani, balógun ìṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 27Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati.

Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

28Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.

Ní ọdún keje ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó-lé-mẹ́tàlélógún (3,023) ará Juda.

29Ní ọdún kejì-dínlógún Nebukadnessari

o kó ẹgbẹ̀rún ó-lé-méjì-dínlọ́gbọ̀n láti Jerusalẹmu.

30Ní ọdún kẹtàlélógún àwọn Júù

tí Nebusaradani kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì jẹ́ ọ̀tà-dínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín-márùn-ún (745).

Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún.

Ìtúsílẹ̀ Jehoiakimu

31Ní ọdún kẹtà-dínlógójì ti Jehoiakini ọba Juda ni Efili-Merodaki di ọba Babeli. Ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù kejìlá. 32Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli. 33Nítorí náà, Jehoiakini pàrọ̀ aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 34Ní ojoojúmọ́ ni ọba Babeli ń fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè, títí di ọjọ́ kú rẹ̀.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

耶利米书 52:1-34

犹大的灭亡

1西底迦二十一岁登基,在耶路撒冷执政十一年。他母亲叫哈慕她,是立拿耶利米的女儿。 2西底迦约雅敬一样做耶和华视为恶的事。 3因此,耶和华向耶路撒冷犹大的人发怒,把他们从祂面前赶走。

后来,西底迦背叛了巴比伦王。 4在他执政第九年十月十日,巴比伦尼布甲尼撒率领全军攻打耶路撒冷,在城外扎营,修筑围城的高台。 5城一直被围困到西底迦执政第十一年。 6那年四月九日,城里饥荒非常严重,百姓无粮可吃。 7城被攻破,西底迦和士兵便在夜间穿过御花园,从两城墙中间的门逃往亚拉巴。当时迦勒底人仍四面包围着城。 8迦勒底的军队追赶西底迦,在耶利哥平原追上了他。他的军队都四散而逃。 9迦勒底人擒住西底迦,把他押到哈马利比拉去见巴比伦王。巴比伦王在那里审判他, 10当着他的面杀了他的众子和犹大所有的首领, 11又剜去他的双眼,用铜链锁着他押往巴比伦,将他终生囚在牢里。

12巴比伦尼布甲尼撒执政第十九年五月十日,他的臣仆——护卫长尼布撒拉旦进入耶路撒冷13放火焚烧耶和华的殿、王宫及城内所有的房屋。他烧毁了所有重要建筑。 14他率领的迦勒底的军队拆毁了耶路撒冷四围的城墙。 15护卫长尼布撒拉旦掳去最贫穷的人、城中的余民、投降的人和剩下的技工, 16只留下一些最贫穷的人,让他们照料葡萄园、耕种田地。

17迦勒底人打碎耶和华殿中的铜柱、铜底座和铜海,把铜运往巴比伦18并带走了盆、铲、蜡剪、碗、碟及一切献祭用的铜器。 19护卫长还带走了杯、火鼎、碗、盆、灯台、碟和奠酒的杯等所有金银器皿。 20所罗门王为耶和华的殿所造的两根铜柱、一个铜海、铜海下面的十二头铜牛,以及一些铜底座,用的铜多得无法计算。 21两根铜柱中空,高八米,周长五点三米,铜壁厚四指。 22铜柱有柱冠,柱冠高二点三米,周围装饰着铜网和铜石榴。两根柱子都一样。 23每根铜柱周围装饰着九十六个石榴,网子四周共有一百个石榴。

24护卫长掳走祭司长西莱雅、副祭司长西番亚、三名殿门守卫, 25又从城中掳走一名将领、王的七个亲信、一名负责招兵的书记和六十名平民, 26把他们带到利比拉去见巴比伦王。 27巴比伦王在那里处死了他们。犹大人就这样被掳去,离开了家园。

28以下是尼布甲尼撒掳去的人数:他执政第七年掳去三千零二十三名犹大人; 29执政第十八年,从耶路撒冷掳去八百三十二人; 30执政第二十三年,他的护卫长尼布撒拉旦掳去七百四十五名犹大人。总共四千六百人。

31犹大约雅斤被掳后第三十七年,即巴比伦以未·米罗达元年十二月二十五日,巴比伦王恩待约雅斤,释放了他, 32并好言相待,使他的地位高过被掳到巴比伦的其他各王。 33约雅斤脱去了囚服,终生与巴比伦王一起吃饭。 34在他有生之年,巴比伦王供应他每天的需用,直到他去世。