阿摩司書 7 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

阿摩司書 7:1-17

各種災禍的異象

1以下是主耶和華讓我看見的異象:看啊,祂造了一大群蝗蟲。那時,王室的作物已經收割,第二季作物剛開始發苗。 2蝗蟲吃盡地上的青苗時,我說:「主耶和華啊,求你赦免!雅各那麼弱小,他怎麼受得了呢?」 3於是,耶和華心生憐憫,說:「我不降這災了。」

4以下是主耶和華讓我看見的異象:看啊,主耶和華降下審判的大火。大火燒乾了深海,正在吞噬土地。 5那時,我說:「主耶和華啊,求你停止吧!雅各那麼弱小,他怎麼受得了呢?」 6於是,耶和華心生憐憫,說:「我也不降這災了。」

7以下是祂讓我看見的異象:看啊,主站在一道按照準繩建造的牆邊,手裡拿著準繩。 8耶和華對我說:「阿摩司,你看見什麼?」我答道:「一條準繩。」主說:「我要在我的以色列子民中吊起準繩,量度他們,我不會再饒恕他們。 9以撒子孫的邱壇必遭毀壞,以色列的廟宇必成廢墟,我要用刀攻擊耶羅波安王朝。」

阿摩司被逐

10伯特利的祭司亞瑪謝派人告訴以色列耶羅波安:「阿摩司以色列家圖謀背叛你,我們國家無法容忍他的言論。 11因為阿摩司這樣說,『耶羅波安將喪身刀下,以色列人必被擄去,遠離家鄉。』」

12亞瑪謝對我說:「先見啊,走吧!逃回猶大去吧!你要在那裡掙吃的,在那裡說預言。 13不可再在伯特利說預言,這裡是王的聖所,是國廟。」

14我答道:「我本不是先知,也不是先知的門徒。我只是一個牧人,也替人看護桑樹。 15但耶和華不再讓我看守羊群,祂對我說,『去!向我的以色列子民說預言。』 16亞瑪謝啊,你說,『不要說攻擊以色列的預言,不要傳講攻擊以撒子孫的信息。』現在你要聽耶和華對你說的話。 17耶和華說,『你的妻子必在這城裡淪為妓女,你的兒女必喪身刀下,你的田地必被人丈量、瓜分,你自己必死在異鄉7·17 異鄉」希伯來文是「不潔之地」,指不信上帝的國家。以色列人必被擄去,遠離家鄉。』」

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Amosi 7:1-17

Eṣú, iná àti ìwọ̀n okùn

1Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Ó pèsè ọwọ́ eṣú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀. 2Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

3Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.

“Èyí kò ni ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.

4Èyí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Olúwa Olódùmarè ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run. 5Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

6Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.

“Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí.

7Èyí ni ohun tí ó fihàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀. 8Olúwa sì bi mi pé, “Amosi, kí ni ìwọ rí?”

Mo dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n.”

Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wò ó, Èmí ń gbé okùn ìwọ̀n kalẹ̀ láàrín àwọn Israẹli ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́.

9“Ibi gíga Isaaki wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro

àti ibi mímọ Israẹli wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro.

Èmi yóò sì fi idà dìde sí ilé Jeroboamu.”

Amosi àti Amasiah

10Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. 11Nítorí èyí ni ohun ti Amosi ń sọ:

“ ‘Jeroboamu yóò ti ipa idà kú,

Lóòtítọ́ Israẹli yóò lọ sí ìgbèkùn,

jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”

12Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀. 13Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.”

14Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore. 15Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ 16Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé,

“ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli

Má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’

17“Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí:

“ ‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú,

àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú.

A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in

àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́.

Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn,

kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”