Titu 2 – YCB & CRO

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Titu 2:1-15

Àwọn ẹ̀kọ́ tí a gbọdọ̀ kọ́ ní onírúurú àkójọpọ̀

1Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́. 2Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra.

3Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere. 4Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn, 5láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínúrere, kí wọ́n sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa ba à sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

6Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu. 7Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi àpẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òṣùwọ̀n 8ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro, tí a kò lè dá lẹ́bi, kí ojú kí ó ti ẹni tí ó ń sòdì, ní àìní ohun búburú kan láti wí sí wa.

9Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, 10wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.

11Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fi ara hàn fún gbogbo ènìyàn. 12Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí, 13bí a ti ń wọ́nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. 142.14: Sm 130.8; El 37.23; De 14.2.Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.

15Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kí ìwọ kí ó máa kọ wọn. Gbani níyànjú kí ó sì máa fi gbogbo àṣẹ bá ni wí. Máa jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó gàn ọ́.

Knijga O Kristu

Titu 2:1-15

Promicati zdravo učenje

1Ali ti poučavaj životu koji je u skladu sa zdravim učenjem. 2Pouči starije muškarce da budu trijezni i razboriti te zdravi u vjeri, ljubavi i strpljivosti.

3Pouči starije žene da se ponašaju pobožno i predano. Ne smiju ogovarati i neka ne robuju prevelikom vinu. Radije neka budu učiteljice dobra. 4Neka odgajaju mlađe žene da žive mirno, da ljube svoje muževe i djecu, 5da budu razborite i čista srca, da marljivo rade u svojim domovima, da budu dobre i poslušne muževima kako drugi zbog njih ne bi vrijeđali Božju riječ.

6Mladiće također potiči da budu razumni. 7Sam im budi uzor čineći dobra djela. Poučavaj zdravo i ozbiljno. 8Neka ti učenje bude tako zdravo da se tvoji protivnici posrame jer nemaju što loše reći.

9Robovi se u svemu moraju pokoravati svojim gospodarima i truditi se da im ugode. Ne smiju im proturječiti 10niti ih potkradati, nego se moraju pokazati pouzdanima. Tako će učenje o Bogu, našem Spasitelju, učiniti privlačnim u svakom pogledu.

11Objavljena je Božja milost koja donosi spasenje svim ljudima. 12Odgojila nas je da se odreknemo bezbožnog života i grešnih svjetovnih požuda te da u ovome svijetu živimo uzdržljivo, pravedno i pobožno 13iščekujući blaženu nadu: da se veliki Bog, naš Spasitelj Isus Krist, pojavi u slavi. 14On je dao sebe umjesto nas da nas oslobodi od svakoga grijeha, da nas očisti i da budemo njegov izabrani narod koji revno čini dobra djela.

15To poučavaj i opominji ljude da tako čine. Kori ih kad je to potrebno jer imaš tu vlast. Nemoj da te tko prezire!