Luku 23 – YCB & SZ-PL

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 23:1-56

123.1: Mt 27.1-2; Mk 15.1; Jh 18.28.Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pilatu. 223.2: Lk 20.25.Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.”

323.3: Mt 27.11-12; Mk 15.2-3; Jh 18.29-38; Lk 22.70.Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”

Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”

423.4: Lk 23.14,22,41; Mt 27.24; Jh 19.4,6; Ap 13.28.Pilatu sì wí fún àwọn olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọkùnrin yìí.”

5Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Judea, ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili títí ó fi dé ìhín yìí!”

6Nígbà tí Pilatu gbọ́ orúkọ Galili, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Galili. 7Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ abẹ́ àṣẹ Herodu ni, ó rán an sí Herodu, ẹni tí òun tìkára rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà.

823.8: Lk 9.9; Ap 4.27-28.Nígbà tí Herodu, sì rí Jesu, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ́ ó sá à ti ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ ààmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe. 923.9: Mk 15.5.Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá. 10Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn kàn án gidigidi. 1123.11: Mk 15.17-19; Jh 19.2-3.Àti Herodu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pilatu lọ. 12Pilatu àti Herodu di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ náà: nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.

13Pilatu sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ. 1423.14: Lk 23.4,22,41.Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà: sì kíyèsi i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn. 15Àti Herodu pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsi i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀. 1623.16: Lk 23.22; Jh 19.12-14.Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.” 17(Ṣùgbọ́n kò lè ṣe àìdá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)

1823.18-23: Mt 27.20-23; Mk 15.11-14; Ap 3.13-14; Jh 18.38-40; 19.14-15.Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Baraba sílẹ̀ fún wa!” 19Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.

20Pilatu sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀. 21Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ àgbélébùú!”

22Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kín ni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”

2323.23-25: Mt 27.26; Mk 15.15.Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélébùú, ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀. 24Pilatu sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́. 25Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

Wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú

2623.26: Mt 27.32; Mk 15.21; Jh 19.17.Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Simoni ara Kirene, tí ó ń ti ìgbèríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélébùú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jesu. 27Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún 2823.28-31: Lk 21.23-24; 19.41-44.Ṣùgbọ́n Jesu yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín. 29Nítorí kíyèsi i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fún ni mu rí!’ 30Nígbà náà ni

“ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Yí lù wá!”

Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’

31Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kín ni a ó ṣe sára igi gbígbẹ?”

32Àwọn méjì mìíràn bákan náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa. 3323.33-39: Mt 27.33-44; Mk 15.22-32; Jh 19.17-24.Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. 3423.34: Ap 7.60; Sm 22.18.Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn.

3523.35: Lk 4.23.Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”

3623.36: Mk 15.23; Sm 69.21.Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. 37Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”

38Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe:

èyí ni ọba àwọn júù.

39Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.”

40Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà? 4123.41: Lk 23.4,14,22.Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”

42Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.”

4323.43: 2Kọ 12.3; If 2.7.Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!”

Ikú Jesu

4423.44-49: Mt 27.45-56; Mk 15.33-41; Jh 19.25-30.Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́. 4523.45: Ek 26.31-35; Hb 9.8; 10.19.Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì, 4623.46: Sm 31.5.Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

47Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!” 48Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé. 4923.49: Lk 8.1-3; 23.55-56; 24.10.Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.

Ìsìnkú Jesu

5023.50-56: Mt 27.57-61; Mk 15.42-47; Jh 19.38-42; Ap 13.29.Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́. 51Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run. 52Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu. 53Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. 54Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́: ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.

55Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀. 5623.56: Mk 16.1; El 12.16; 20.10.Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórùn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); Wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.

Słowo Życia

Łukasza 23:1-56

Jezus przed Piłatem i Herodem

1Wtedy wszyscy razem zaprowadzili Jezusa do Piłata, rzymskiego gubernatora, 2i oskarżyli Go:

—Stwierdziliśmy, że ten oto człowiek podburza nasz naród, bo zabrania ludziom płacenia podatków cezarowi i twierdzi, że jest naszym Mesjaszem i Królem.

3Na to Piłat zapytał:

—Jesteś Królem Żydów?

—Sam to potwierdzasz—odpowiedział Jezus.

4Wówczas Piłat zwrócił się do najwyższych kapłanów i tłumu:

—Nie znajduję żadnej winy w tym człowieku!

5—Przecież naucza po całej Judei i buntuje lud—upierali się. —Zaczął w Galilei i dotarł aż tutaj!

6Słysząc to, Piłat zapytał, czy Jezus rzeczywiście pochodzi z Galilei. 7Gdy to potwierdzono, odesłał Go do Heroda Antypasa, ponieważ Galilea podlegała jego jurysdykcji, a on sam akurat przebywał w Jerozolimie.

8Herod bardzo się ucieszył na widok Jezusa, bo wiele o Nim słyszał i już od dłuższego czasu chciał Go poznać. Spodziewał się, że na jego oczach Jezus dokona jakiegoś cudu. 9Zasypywał Go więc pytaniami, lecz On w ogóle nie odpowiadał. 10Tymczasem obecni tam najwyżsi kapłani i przywódcy religijni bezlitośnie oskarżali Jezusa. 11W końcu Herod ze swoimi żołnierzami zaczął wyśmiewać Go. Ubrał Jezusa w królewski płaszcz i z powrotem odesłał do Piłata. 12Od tego dnia Herod i Piłat stali się przyjaciółmi, mimo że dotychczas byli do siebie wrogo nastawieni.

13Piłat zwołał najwyższych kapłanów, członków Rady oraz lud 14i rzekł:

—Przyprowadziliście do mnie tego człowieka, oskarżając go o podburzanie ludu przeciwko rzymskiej władzy. W waszej obecności przesłuchałem go jednak i nie znalazłem w nim żadnej winy, 15podobnie jak Herod, który odesłał go do mnie. Stwierdzam więc, że nie zrobił nic, co zasługuje na karę śmierci. 16Każę go więc wychłostać i wypuszczę.

17Był bowiem zobowiązany zwolnić jakiegoś więźnia z okazji święta. 18Wszyscy zaczęli jednak krzyczeć:

—Nie! Jego zabij, a wypuść nam Barabasza!

19Barabasz zaś był uwięziony za wywołanie w Jerozolimie rozruchów oraz za morderstwo. 20Ponieważ Piłat chciał uwolnić Jezusa, ponownie przedstawił im swoje stanowisko. 21Lecz oni nalegali, wołając:

—Ukrzyżuj, ukrzyżuj go!

22—Co złego uczynił?—zapytał ich więc już po raz trzeci. —Ja nie znalazłem żadnego powodu, aby skazać go na śmierć. Każę go wychłostać i wypuszczę.

23Lecz tłum coraz głośniej domagał się ukrzyżowania Jezusa. 24W końcu Piłat uległ ich żądaniu i wydał wyrok. 25Wypuścił z więzienia Barabasza, skazanego za wywołanie rozruchów i morderstwo, a Jezusa oddał w ich ręce.

Ukrzyżowanie

26Tłum poprowadził więc Jezusa na miejsce egzekucji. Tą samą drogą wracał właśnie z pola do Jerozolimy niejaki Szymon z Cyreny. Żołnierze zmusili go do niesienia za Jezusem Jego krzyża. 27A podążały za nimi ogromne tłumy, wśród nich wiele kobiet, rozpaczających nad losem Jezusa. 28On w pewnym momencie odwrócił się i rzekł do nich:

—Kobiety z Jerozolimy! Nie płaczcie nade Mną, ale nad sobą i waszymi dziećmi. 29Nadchodzą bowiem dni, gdy będą mówić: „Szczęśliwe są bezpłodne kobiety i te, które jeszcze nie rodziły i nie karmiły”. 30Ludzie będą wtedy ze strachu błagać góry i pagórki:

„Padnijcie na nas

i zasypcie na zawsze”.

31Jeśli takie rzeczy robią z żywym jeszcze drzewem, to jak potraktują drzewo suche?

32Razem z Jezusem prowadzono na śmierć dwóch przestępców. 33Gdy dotarli na miejsce zwane Czaszką, ukrzyżowali ich wszystkich—Jezusa w środku, a dwóch skazanych po Jego prawej i lewej stronie.

34Jezus modlił się:

—Ojcze, przebacz im, bo nie wiedzą, co robią.

Ci zaś, którzy Go ukrzyżowali, rzucili losy o Jego ubranie, aby ustalić, co kto ma wziąć. 35Całej egzekucji przyglądał się niemały tłum, a przywódcy naśmiewali się z Jezusa:

—Innych potrafił ratować, niech więc teraz uratuje siebie, skoro jest Mesjaszem, Bożym wybrańcem!

36Również żołnierze, podając Mu kwaśne wino, śmiali się z Niego:

37—Jeśli jesteś Królem Żydów, uratuj się!

38Nad głową Jezusa znajdowała się bowiem tabliczka z napisem: „To jest król Żydów”.

39Jeden z przestępców, wiszących obok Jezusa, również naśmiewał się z Niego:

—Przecież jesteś Mesjaszem! Ratuj się więc! A przy okazji nas!

40—Czy dlatego nie boisz się już Boga, że zostałeś skazany razem z Jezusem?—upomniał go drugi. 41—My za swoje czyny zasłużyliśmy na śmierć, ale On nie uczynił nic złego. 42Jezusie, pamiętaj o mnie, gdy znajdziesz się w swoim królestwie!—dodał.

43—Zapewniam cię, że jeszcze dziś będziesz ze Mną w raju—odrzekł Jezus.

Śmierć Jezusa

44Nagle, około południa, całą ziemię okrył mrok i aż do godziny trzeciej było ciemno. 45Słońce utraciło swój blask, a zasłona w świątyni, oddzielająca miejsce najświętsze, rozdarła się na dwie części. 46Wtedy Jezus głośno zawołał:

—Ojcze, Tobie oddaję mojego ducha!—i po tych słowach skonał.

47A rzymski dowódca, widząc, co się dzieje, oddał chwałę Bogu, mówiąc:

—To był prawy człowiek!

48Ludzie, którzy tłumnie zebrali się, aby zobaczyć ukrzyżowanie Jezusa, wracali do domu w głębokim smutku. 49Natomiast przyjaciele Jezusa—wśród nich kobiety, które towarzyszyły Mu aż od Galilei—przyglądali się wszystkiemu z daleka.

Pogrzeb Jezusa

50-51Był wśród nich Józef, dobry i prawy człowiek, pochodzący z judejskiego miasta—Arymatei. Oczekiwał on nadejścia królestwa Bożego. Mimo że sam był członkiem Wysokiej Rady, sprzeciwiał się jej decyzjom oraz działaniom. 52Po śmierci Jezusa udał się do Piłata z prośbą o wydanie mu Jego ciała. 53Następnie zdjął je z krzyża, owinął w długie lniane płótno i złożył w nieużywanym dotąd grobie, który był wykuty w skale. 54Był to piątkowy wieczór, czas przygotowania do szabatu.

55Kobiety z Galilei, które towarzyszyły wcześniej Jezusowi, obejrzały grób oraz jak złożono Jego ciało. 56Gdy wróciły do domu, przygotowały wonne zioła i olejki do namaszczania zwłok. W czasie szabatu jednak, zgodnie z przepisami religijnymi, nie mogły zajmować się zmarłym.