Jobu 42 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 42:1-17

Ìrònúpìwàdà Jobu

1Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé:

2“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo,

àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

3Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀?

Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀,

ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.

4“Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí,

èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,

ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’

5Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,

ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.

6Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,

mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”

Ọlọ́run bùkún Jobu

7Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ. 8Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe. 9Bẹ́ẹ̀ ní Elifasi, ara Temani, àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Olúwa sì gbọ́ àdúrà Jobu.

10Olúwa sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí 11Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a: Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.

12Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá-méje àgùntàn, ẹgbàá-mẹ́ta ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 13Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta. 14Ó sì sọ orúkọ àkọ́bí ní Jemima, àti orúkọ èkejì ni Kesia àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kereni-Happuki. 15Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.

16Lẹ́yìn èyí Jobu wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin. 17Bẹ́ẹ̀ ni Jobu kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

约伯记 42:1-17

1约伯回答耶和华说:

2“我知道你无所不能,

你的旨意无不成就。

3你问,‘谁用无知的话使我的旨意晦暗不明?’

诚然,我对自己所谈论的事一无所知,

这些事太奇妙,我无法明白。

4你说,‘你且听着,我要发言。

我来提问,你来回答。’

5我从前风闻有你,

现在亲眼看见你。

6因此我厌恶自己,

在尘土和炉灰中忏悔。”

结语

7耶和华对约伯说完这些话后,就对提幔以利法说:“你和你的两个朋友令我愤怒,因为你们对我的议论不如我仆人约伯说的有理。 8现在你们要取七头公牛和七只公羊,到我仆人约伯那里,为自己献上燔祭,因为你们对我的议论不如我仆人约伯说的有理。我仆人约伯会为你们祷告,我会悦纳他的祷告,不按你们的愚妄惩罚你们。” 9于是,提幔以利法书亚比勒达拿玛琐法遵命而行,耶和华悦纳了约伯的祷告。

10约伯为朋友们祷告后,耶和华恢复了他以前的昌盛,并且耶和华赐给他的比以前多一倍。 11约伯的兄弟姊妹和从前的朋友都来探望他,在他家里一同吃饭,为他遭受耶和华所降的种种灾难而安抚、慰问他。他们每人送他一块银子和一个金环。

12耶和华赐给约伯晚年的福分比起初更多:他有一万四千只羊、六千只骆驼、一千对牛和一千头母驴。 13他还有七个儿子和三个女儿。 14他给长女取名叫耶米玛、次女叫基洗亚、三女叫基连·哈朴15那地方找不到像约伯三个女儿那样美丽的女子。约伯让她们与弟兄一同承受产业。 16此后,约伯又活了一百四十年,得见四代子孙。 17约伯年纪老迈,寿终正寝。