Jobu 31 – YCB & KLB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 31:1-40

Àwíjàre Jobu

1“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú,

èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?

2Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá?

Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.

3Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún,

àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?

4Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi,

òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?

5“Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,

tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn;

6(Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo,

kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)

7Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà,

tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi,

tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,

8Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ,

àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.

9“Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan,

tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,

10Kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn,

kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.

11Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú

àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀

12Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun,

tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.

13“Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi

tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,

nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;

14Kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde?

Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?

15Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a?

Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?

16“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,

tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,

17Tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,

tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;

18nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba,

èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:

19Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,

tàbí tálákà kan láìní ìbora;

20Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,

tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;

21Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba,

nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,

22Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀,

kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.

23Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi,

àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.

24“Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,

tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi;’

25Bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀,

àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọpọ̀;

26Bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn,

tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,

27Bí a bá tàn ọkàn mi jẹ: Láti fi

ẹnu mi kò ọwọ́ mi:

28Èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò.

Nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.

29“Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi.

Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.

30Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀

nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.

31Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé,

ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?

32(Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí;

èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.)

33Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá,

ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi.

34Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí?

Tàbí ẹ̀gàn àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù?

Tí mo fi pa ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi sọ̀rọ̀ jáde?

35(“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí!

Kíyèsi i, ààmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn!

Kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ!

36Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi,

èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.

37Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un,

bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)

38“Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi

tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.

39Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owó

tàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,

40kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama,

àti èpò búburú dípò ọkà barle.”

Ọ̀rọ̀ Jobu parí.

Korean Living Bible

욥기 31:1-40

1“내가 내 눈과 서약하였으니 어찌 처녀를 정욕의 눈으로 볼 수 있겠는가?

2내가 만일 그렇게 한다면 위에 계신 전능하신 하나님에게 무엇을 기대할 수 있겠는가?

3의롭지 못하고 악을 행하는 자에게는 하나님이 재앙을 내려 벌하실 것이 아니겠는가?

4하나님은 내가 행하는 모든 일을 다 보고 계시며 내 걸음을 일일이 헤아리신다.

5“나는 거짓말을 한 적도 없고 다른 사람을 속인 일도 없다.

6만일 하나님이 나를 정직한 저울에 달아 보시면 나의 진실을 아실 것이다.

7내가 만일 바른 길에서 벗어났다던가 아니면 눈으로 본 것에 마음이 끌려 죄를 범했다던가 또 내 손이 죄로 더럽혀졌다면

8내가 심은 것을 다른 사람이 먹고 내가 기른 농작물이 뿌리째 뽑혀 못 쓰게 되어도 할 말이 없을 것이다.

9“내가 만일 어떤 여자에게 마음이 끌려서 그녀의 문 밖에 숨어 그녀를 엿본 적이 있다면

10내 아내가 다른 사람의 집에서 맷돌질을 하고 다른 사람의 침실에서 잠을 자도 마땅하다.

11이런 죄는 반드시 형벌을 받아야 할 무서운 악이며

12내가 가진 모든 것을 송두리째 삼켜 버리는 파괴적인 지옥 불과도 같은 것이다.

13내 종들이 나에게 불만을 말할 때에도 나는 그들의 말을 듣고 그들에게 정당한 대우를 해 주었다.

14내가 만일 그렇게 하지 않았다면 내가 어떻게 하나님을 대할 수 있으며 하나님이 나에게 그 일을 따지실 때 내가 무엇이라고 대답할 수 있겠는가?

15나를 만드신 하나님은 내 종들도 만드신 분이시다.

16“나는 가난한 자의 소원을 거절하거나 과부를 실망시킨 적이 없으며

17나는 배불리 먹으면서 불쌍한 고아를 굶겨 본 적도 없다.

18사실 나는 젊었을 때부터 고아들을 친자식처럼 돌보아 주었고 과부들을 보살펴 주었다.

19나는 또 너무 가난해서 입을 것이나 덮을 것이 없는 사람을 보면

20양털로 옷을 지어 입혔고 그들은 나에게 정성껏 복을 빌어 주었다.

21만일 내가 법정에서 나를 도와줄 자가 있음을 알고 고아를 등쳐먹었다면

22내 팔이 부러지고 어깻죽지에서 떨어져 나가도 할 말이 없을 것이다.

23나는 하나님의 형벌을 무서워할 뿐만 아니라 그의 위엄이 두려워서도 감히 그런 짓을 할 수가 없다.

24“나는 돈을 신뢰하거나

25재산이 많다고 기뻐한 적이 없으며

26또 하늘에 빛나는 태양이나 은빛 길을 걷는 달을 보고

27은근히 마음이 끌려 손을 모아 그것들을 숭배해 본 적도 없다.

28내가 만일 그런 짓을 했다면 이것 역시 재판을 받아야 할 죄이다. 그것은 내가 위에 계신 하나님을 배반한 셈이 되기 때문이다.

29“나는 나를 미워하는 자가 망하는 것을 보고 기뻐하거나 재앙을 만나 고통당하는 것을 보고 흐뭇한 표정을 지어 본 적도 없다.

30사실 나는 어떤 사람을 죽으라고 저주하여 내 입술로 범죄한 적이 없다.

31내 고기로 배를 채우지 않은 사람이 없다는 것은 내 집에서 일하는 자들도 다 아는 사실이다.

32나는 나그네를 길거리에서 자게 한 일이 없으며 길 가는 사람들을 위해 내 집 문을 항상 열어 두었다.

33-34나는 31:33-34 원문에는 ‘아담처럼’다른 사람들처럼 내 죄를 숨겨 본 일도 없고 사람들이 하는 말을 두려워하지도 않았으며 내가 그들의 비웃음을 무서워하여 할 말을 못하거나 바깥 출입을 하지 못하고 집 안에만 틀어박혀 있은 적도 없었다.

35“누구든지 내가 하는 말을 들어라. 내가 하는 변명에는 조금도 거짓이 없다. 나는 전능하신 하나님이 내 말에 대답해 주시기를 원하고 있다. 만일 내 대적이 내가 인정할 만한 소송장을 나에게 제시할 수 있었다면

36내가 그것을 어깨에 메기도 하고 면류관처럼 머리에 쓰기도 했을 것이며

37또 내가 행한 일을 일일이 다 그에게 말하고 내가 그를 왕족처럼 가까이했을 것이다.

38“내 토지가 나를 향해 부르짖고 그 이랑이 눈물로 젖은 일이 있는가?

39내가 만일 값을 지불하지 않고 그 농산물을 먹거나 소작인들을 굶어 죽게 한 일이 있다면

40그 땅에 밀 대신 찔레가 나고 보리 대신 잡초가 나도 할 말이 없을 것이다.” 이렇게 해서 욥의 말이 끝났다.