Gẹnẹsisi 27 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 27:1-46

Isaaki súre fún Jakọbu

1Nígbà ti Isaaki di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tó bẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi.”

Esau sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

2Isaaki sì wí pé, “Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú. 3Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ—apó àti ọrún—nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó. 4Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn, kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.”

527.5: Gẹ 12.3; Nu 24.9.Ṣùgbọ́n Rebeka ń fetí léko gbọ́ nígbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Esau ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó, 6Rebeka sọ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń wí fún Esau ẹ̀gbọ́n rẹ pé, 7‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì ṣe oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n ba à le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’ 8Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi, kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ: 9Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára. 10Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun ba à lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ, kí ó tó kú.”

11Jakọbu sì wí fún Rebeka ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Esau ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára, bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ sì ni èmi, 12Bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ńkọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.”

13Ìyá rẹ̀ wá wí fun un pé, “Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, sá à ṣe ohun tí mo wí, kí o sì mú wọn wá fún mi.”

14Jakọbu sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rebeka sì ṣe oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Isaaki fẹ́ràn. 15Nígbà náà ni Rebeka mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Esau ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rebeka, ó sì fi wọ Jakọbu ọmọ rẹ̀ àbúrò. 16Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ọ̀bọ̀rọ́ ọrùn. 17Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jakọbu ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

18Jakọbu wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi.”

Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?”

19Jakọbu sì fèsì pé, “Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ, èmi ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ fún mi, jọ̀wọ́ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.”

20Isaaki tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?”

Jakọbu sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.”

21Nígbà náà ni Isaaki wí fún Jakọbu pé, “Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni nítòótọ́ tàbí òun kọ́.”

22Jakọbu sì súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀. Isaaki sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jakọbu; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Esau.” 23Kò sì dá Jakọbu mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ ní irun bí i ti Esau arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún un 24ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Esau ọmọ mi ni tòótọ́?”

Jakọbu sì dáhùn pé, “Èmi ni.”

25Nígbà náà ni Isaaki wí pé “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.”

Jakọbu sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú. 26Nígbà náà ni Isaaki baba rẹ̀ wí fun un pé, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnukò mí ní ẹnu.”

27Ó sì súnmọ́ ọn, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà tí Isaaki gbọ́ òórùn aṣọ rẹ̀, ó súre fún un ó wí pé:

“Wò ó òórùn ọmọ mi

dàbí òórùn oko

Olúwa ti bùkún.

28Kí Ọlọ́run kí ó fún ọ nínú ìrì ọ̀run

àti nínú ọ̀rá ilẹ̀

àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun.

29Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́,

kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ,

máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ,

kí àwọn iyèkan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ

Fífibú ni àwọn ẹni tó fi ọ́ bú,

Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ó súre fún ọ.”

30Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. 31Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.”

32Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?”

Ó sì dáhùn pé “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.”

33Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!”

34Nígbà tí Esau gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”

35Ṣùgbọ́n Isaaki wí pé, “Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ.”

3627.36: Gẹ 25.29-34.Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu (Arẹ́nijẹ) bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi! Háà! Baba mi, ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?”

37Isaaki sì dá Esau lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún un, àti ọkà àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”

38Esau sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi? Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau sì sọkún kíkankíkan.

39Isaaki baba rẹ̀ sì dá a lóhùn pé,

“Ibùjókòó rẹ

yóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀,

àti sí ibi ìrì ọ̀run láti òkè wá.

40Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé,

ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ,

ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára

ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀

kúrò lọ́rùn rẹ.”

Jakọbu sálọ sí ọ̀dọ̀ Labani

41Esau sì kórìíra Jakọbu nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi sá à ti fẹ́rẹ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jakọbu, arákùnrin mi.”

42Nígbà tí Rebeka sì gbọ́ ohun tí Esau àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jakọbu, ó sì wí fun un pé, “Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò à ti pa ọ́. 43Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ: Sálọ sọ́dọ̀ Labani ẹ̀gbọ́n mi ní Harani. 44Jókòó sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí ìbínú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀. 45Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá. Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?”

46Nígbà náà ni Rebeka wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí. Bí Jakọbu bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láààyè.”

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

创世记 27:1-46

以撒为儿子祝福

1以撒年老的时候,眼睛昏花,几乎看不见。他把大儿子以扫叫来,说:“我儿啊!”以扫说:“我在这里。” 2以撒说:“我年老了,不知道还能活多久。 3现在,带着你的弓箭去田野为我打些野味来, 4照我喜欢的口味,做成美食给我吃,以便我在死前给你祝福。”

5利百加听见了以撒跟儿子以扫说的话。以扫出去打猎后, 6利百加就对她儿子雅各说:“我听见你父亲对你哥哥以扫说, 7‘你去打些野味回来,做成美食给我吃,以便我死之前在耶和华面前给你祝福。’ 8现在,孩子,你要听我的话,照我的吩咐去做。 9你到羊群里选两头上好的山羊羔,我好照你父亲喜爱的口味做成美食, 10由你拿去给他吃,让他死前为你祝福。”

11雅各对母亲利百加说:“哥哥以扫浑身是毛,我的皮肤光滑。 12如果父亲用手摸我,一定会发觉我骗他,那时候我不但得不到祝福,反会招来咒诅。” 13他母亲利百加对他说:“孩子啊,有咒诅,我来承担。你只管听我的话,把羊羔牵来。”

14于是,雅各把羊牵来交给母亲,他母亲就照他父亲喜爱的口味做成美食。 15利百加又拿了大儿子以扫留在家里最好的衣服,给小儿子雅各穿上, 16再用山羊皮把雅各光滑的手和脖子都包起来, 17然后把做好的美味和饼交给雅各

18雅各来到父亲跟前,叫了一声:“父亲。”以撒回答说:“我在这里,孩子,你是谁?” 19雅各对父亲说:“我是你的大儿子以扫,你吩咐我的事,我已经办好了。请你坐起来,吃我打的野味,然后给我祝福。” 20以撒对他说:“孩子,你怎么这么快就打到野味了?”雅各回答说:“因为你的上帝耶和华让我碰见好机会。” 21以撒说:“孩子,过来,让我摸摸看你是不是我儿以扫。” 22雅各挨到父亲跟前,以撒摸着他说:“声音是雅各的声音,手却是以扫的手。” 23因为雅各手上有毛,与他哥哥以扫的手一样,以撒分辨不出来,就给他祝福。 24以撒又问:“你真是我的儿子以扫吗?”雅各回答说:“是。” 25以撒便说:“把野味拿给我,我吃了你打的野味就为你祝福。”雅各递上野味,以撒吃了;雅各又拿酒给他喝,他也喝了。 26以撒对他说:“孩子,你过来亲吻我。” 27雅各就挨上前去亲了父亲。以撒闻到他衣服上的气味,就祝福他说:

“我儿子的香气就像蒙耶和华赐福之田地的香气。

28愿上帝赐你天上的甘霖、肥沃的土地并丰富的五谷和新酒。

29愿万民都臣服于你,

万国都向你下拜。

愿你成为你弟兄的主人,

愿你母亲的儿子向你下拜。

咒诅你的,愿他受咒诅;

祝福你的,愿他蒙祝福。”

以扫求父亲祝福

30雅各接受了以撒的祝福才刚离开,他的哥哥以扫就打猎回来了。 31以扫把野味煮好,拿到父亲跟前,说:“父亲,请起来吃你儿子煮的野味,然后给我祝福。” 32他父亲以撒问道:“你是谁?”以扫回答说:“我是你的长子以扫。” 33以撒大为震惊,说:“你没有来之前,拿野味来给我吃的是谁呢?我已经吃了,也给那人祝福了,他将来必蒙祝福。”

34以扫听了放声痛哭,说:“父亲啊,求你也为我祝福!” 35以撒说:“你弟弟已经用诡计把你的福分夺去了。” 36以扫说:“怪不得他叫雅各,他已经骗了我两次,先前把我长子的名分夺去,现在又夺去我的福分!”接着他对父亲说:“难道你没有留下别的祝福可以给我吗?”

37以撒以扫说:“我已经立他做你的主人,使他的众弟兄做他的仆人,并给他五谷和新酒。孩子啊,我还能为你做什么呢?” 38以扫对父亲说:“父亲啊,你只有一个祝福吗?父亲啊,求你也为我祝福!”以扫又放声大哭。 39以撒对他说:

“你住的地方必远离肥沃的土地,

也不会有天上的甘霖。

40你必倚靠刀剑生活,

又必服侍你的弟弟。

到你无法忍受的时候,

你必挣脱颈上的重轭。”

雅各逃往舅父家

41以扫因为父亲把祝福给了雅各,就对雅各怀恨在心,暗自思量说:“父亲已经不久人世,他死后,我要把雅各杀掉!” 42以扫的计谋传到利百加耳中。她就派人把雅各叫来,对他说:“你哥哥以扫想要杀你泄愤! 43孩子,听我的话,现在就逃到哈兰你舅舅拉班那里, 44与他住些日子,一直住到你哥哥的气消了。 45等他气消了,忘了你对他所做的事,我会派人接你回来。我何必在一天之内失去你们两个呢?” 46利百加以撒说:“我被这些人女子烦死了。如果雅各也像以扫一样娶那些人女子为妻,我活着还有什么意思呢?”