Ìfihàn 1 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 1:1-20

Ọ̀rọ̀ ìṣáájú

1Ìfihàn ti Jesu Kristi, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fihàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fún Johanu, ìránṣẹ́ rẹ̀: 2Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. 3Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Ọ̀rọ̀ ìkíni àti ìyìn

41.4: Ek 3.14.Johanu,

Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia:

Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀; 51.5: Sm 89.27.àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.

Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, 61.6: Ek 19.6; Isa 61.6.tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.

71.7: Da 7.13; Mt 24.30; Mk 14.62; Sk 12.10.Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀;

gbogbo ojú ni yóò sì rí i,

àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú;

àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.

81.8: Ek 3.14. “Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”

Ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ènìyàn

9Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi. 10Mo wà nínú Ẹ̀mí ní ọjọ́ Olúwa, mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi, bí ìró ìpè, 11Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.”

12Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje; 131.13: Da 7.13; 10.5.àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. 14Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná; 151.15: El 1.24.Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. 161.16: Ek 34.29.Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.

171.17: Isa 44.2,6.Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.

19“Kọ̀wé nítorí náà ohun tí ìwọ ti rí, àti ti ohun tí ń bẹ, àti ti ohun tí yóò hù lẹ́yìn èyí; 20ohun ìjìnlẹ̀ tí ìràwọ̀ méje náà tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ọ̀pá wúrà fìtílà méje náà. Ìràwọ̀ méje ni àwọn angẹli ìjọ méje náà: àti ọ̀pá fìtílà méje náà ní àwọn ìjọ méje.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

启示录 1:1-20

1以下是上帝赐给耶稣基督的启示,让祂把将来要发生的事指示祂的众奴仆。因此,祂差遣天使告诉祂的奴仆约翰2约翰便为自己所看见的一切——上帝的道和耶稣基督做见证。 3那位宣读这预言的人和那些听见并遵守其中内容的人有福了,因为日期近了。

问候七教会

4-5约翰写信给你们亚细亚的七间教会。愿昔在、今在、以后永在的上帝,祂宝座前的七灵1:4-5 七灵”指的就是圣灵,数字七代表完全,不是说有七个灵。和耶稣基督赐给你们恩典和平安。耶稣基督是忠心的见证人,是首先从死里复活的,是世上君王的首领。祂爱我们,用自己的血救我们脱离罪恶, 6使我们成为祭司的国度1:6 成为祭司的国度”或译“成为国度,做祭司”。来事奉祂的父上帝。愿祂得到一切荣耀和权柄,一直到永永远远。阿们!

7看啊!祂要驾云降临,世人都要看见祂,包括曾经刺祂的人。地上的万族都必因祂而哀哭。这事必定实现。阿们!

8主上帝说:“我是阿拉法,我是俄梅加1:8 阿拉法”和“俄梅加”分别是希腊文第一个和最后一个字母,故此句意即“我是始,我是终”。,我是昔在、今在、以后永在的全能者。”

基督的显现

9约翰是你们的弟兄,在耶稣里和你们患难与共、同享国度、一起忍耐。我因传扬上帝的道、为主耶稣做见证而到了拔摩海岛上。 10主日,我被圣灵感动,听见身后有号角般响亮的声音说: 11“把你所看见的写在书上,然后送给以弗所士每拿别迦摩推雅推喇撒狄非拉铁非老底嘉七间教会。”

12我转身看究竟是谁在对我说话,我看见七个金灯台, 13有一位好像人子耶稣的站在这些灯台中间。祂长袍垂脚,金带围胸, 14头与发白如羊毛、洁白如雪,眼睛像火焰, 15双脚像炉中冶炼过的铜一样光亮,声音如同洪涛之声。 16祂右手拿着七颗星,口中吐出一把两刃的利剑,面貌如烈日放光。

17我一看见祂,便扑倒在祂脚前,像死了一样。祂把右手按在我身上,说:“不要害怕!我是首先的,我是末后的, 18我是永活者。我曾经死过,但看啊,我永永远远活着。我掌握死亡和阴间的钥匙。 19所以,你要将所看见的一切——现在和将来要发生的事都记录下来。 20你所看见在我右手中的七颗星和七个金灯台的奥秘是,七颗星代表七间教会的天使1:20 天使”或译“信使”或“使者”,下同,可能指教会的守护天使,或者是教会的领袖。,七个灯台代表七间教会。