Filipi 3 – YCB & NSP

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Filipi 3:1-21

Kò sí ìgbẹ́kẹ̀lé ẹlẹ́ran ara

1Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò. 2Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà. 33.3: Ro 2.28-29; Ga 6.14-15.Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara. 43.4-7: Ap 8.3; 22.3-21; 23.6; 26.4-23; Ro 11.1; 2Kọ 11.18-31.Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara.

Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀: 5Ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi; 6Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.

7Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. 8Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi, 9Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; 10Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀; 11nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.

12Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá. 13Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná: Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú. 14Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu.

15Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín. 16Kìkì pé, ki a ma gbe ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bi èyí ti a ri gba.

173.17: 1Kọ 4.15-17.Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ. 18Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n: 19Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé. 20Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. 213.21: 1Kọ 15.35-58; Kl 3.4.Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.

New Serbian Translation

Филипљанима 3:1-21

Праведност по вери – не по делима

1Уосталом, браћо моја, радујте се у Господу! Мени заиста не пада тешко да вам исто пишем, а то је и ради ваше постојаности.

2Чувајте се паса, чувајте се неваљалих радника, чувајте се сакаћења. 3Ми смо, наиме, право „обрезање“, ми који Духом Божијим служимо Богу и поносимо се Христом Исусом, а не поуздајемо се у тело, 4премда сам могу да се поуздам у тело.

Ако неко мисли да може да се поузда у тело, ја могу још више. 5Обрезан сам осмога дана, од рода сам Израиљева, из Венијаминовог племена, Јеврејин од Јевреја, у погледу Закона био сам фарисеј, 6у својој ревности прогонио сам Цркву, по праведности прописаној Законом био сам беспрекоран.

7Али оно што ми је некада било добитак, то сад, Христа ради, сматрам губитком. 8Шта више, ја све сматрам губитком ради спознања мога Господа Христа Исуса, које све надилази. Због њега сам све изгубио и све сматрам за смеће, да бих Христа добио 9и са њиме се нашао, немајући своје праведности од вршења Закона, него праведност која се вером у Христа стиче, праведност од Бога, која долази од вере, 10да бих упознао њега и силу његовога васкрсења, и суделовао у његовим патњама, наликујући њему у његовој смрти, 11да бих, некако, досегао васкрсење из мртвих.

12Ја, наиме, нисам то већ постигао, нити сам већ дошао до савршенства, али се упрежем, како бих се домогао тога ради чега се Христос Исус домогао мене. 13Браћо, не мислим да сам се већ домогао тога, али једно чиним: заборављам оно што је за мном, и сежем ка ономе што је преда мном, 14трчим према циљу, ка награди на коју нас Бог по Христу Исусу позива на небесима.

15Према томе, ми који смо зрели треба да размишљамо на овај начин. Па ако и имате у чему различито мишљење, Бог ће вам то разјаснити. 16Само се држимо онога до чега смо стигли.

17Следите мене као пример, браћо, и посматрајте оне који живе по узору на нас. 18Јер, многи о којима сам вам често говорио, а сада вам и плачући говорим, живе као непријатељи Христовог крста. 19Њихова судбина је пропаст, стомак је њихов бог, слава им је у срамоти, они мисле на земаљске ствари. 20А наша отаџбина је на небесима, одакле очекујемо Спаситеља, Господа Исуса Христа. 21Он ће преобразити наше понижено тело и учинити га онаквим какво је његово славно тело, дејством силе којом све може да подложи себи.