Esekiẹli 2 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 2:1-10

Ọlọ́run pe Esekiẹli

1Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀.” 2Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí sì wọ inú mi ó mú mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì ń gbọ́ tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀.

3Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní olónìí. 4Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí’ 5Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀—nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn. 6Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n. 7Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. 82.8–3.3: If 5.1; 10.8-10.Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má ṣe ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.”

9Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé kíká sì wà níbẹ̀, 10ó sì tú ìwé náà fún mi. Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ìpohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以西结书 2:1-10

以西结蒙召

1那声音对我说:“人子啊,你站起来,我要对你说话。” 2正说的时候,耶和华的灵就进入我里面,使我站起来。我听见那声音对我说: 3“人子啊,我派你去那背叛我的以色列人那里。他们和他们的祖先至今仍背叛我。 4我派你到那些顽固不化的人那里,向他们宣告,‘主耶和华这样说。’ 5不管那群叛逆的人听不听,他们都会知道有一位先知在他们当中。 6人子啊,不要怕他们和他们的话,虽然你周围布满荆棘和毒蝎,也不要害怕。他们是一群叛逆的人,你不要怕他们的话,也不要因为他们的脸色而惊慌。 7他们是叛逆的,不论他们听不听,你都要把我的话告诉他们。

8“人子啊,你要听我对你说的话,不要像他们那样叛逆,要张开口吃我赐给你的。” 9这时我看见一只手向我伸来,手中拿着书卷。 10那只手把那书卷打开,书卷的两面都写满了哀伤、叹息、悲痛的话。