2 Kronika 3 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 3:1-17

Solomoni kọ́ ilé Olúwa

13.1-13: 1Ọb 6.1-28.Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moriah, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè. 2Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.

3Ìpìlẹ̀ tí Solomoni gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ 4Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́.

Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà. 5Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n. 6Ó ṣe ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu. 7Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa Pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.

8Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ọgọ́rin mẹ́fà tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára. 9Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.

10Ní ibi mímọ́ jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà. 11Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn. 12Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́. 13Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá naà.

143.14: Ek 26.31.Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a ṣe sórí i rẹ̀.

153.15-17: 1Ọb 7.15-21.Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn-ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 16Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rin pomegiranate (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà 17Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

歷代志下 3:1-17

建造聖殿

1所羅門耶路撒冷摩利亞山上動工興建耶和華的殿,殿址在耶布斯阿珥楠的麥場,就是大衛指定的地方。耶和華曾在那裡向他父親大衛顯現。 2所羅門在執政第四年二月二日動工建殿。 3按照古時的尺度,他建造的上帝殿宇的地基長二十七米,寬九米。 4殿前的門廊長九米,與殿的寬度一樣,高九米3·4 高九米」希伯來文是「高五十四米」。,裡面都貼上純金。 5大殿裡鑲上松木板,貼上純金,又刻上棕樹和鏈子。 6所羅門用寶石和巴瓦音的純金裝飾殿。 7殿的棟樑、牆壁、門檻和門扇也都貼上金子;牆上還刻上基路伯天使。

8所羅門又動工建造至聖所,長九米,寬九米,與殿的寬度一樣,裡面共貼了二十一噸純金。 9所用的金釘重六百克。樓房也都貼上了金子。 10他又在至聖所製造兩個基路伯天使的翅膀,包上金子。 11-13兩個基路伯天使的翅膀共九米長,每個翅膀長二點二五米。兩個基路伯天使面向大殿站立,他們展開的翅膀共九米長,各有一個翅膀觸到殿牆,一個翅膀互相連接。 14他用藍色、紫色和朱紅色的線以及細麻織成幔子,並在上面繡上基路伯天使。

15所羅門在殿前造了兩根柱子,每根高八米,上面的柱冠高二點二五米。 16他也造了鏈子3·16 他也造了鏈子」希伯來文是「他在聖所內造了鏈子」。,裝飾在柱冠上。他又造了一百個石榴,安在鏈子上。 17這兩根柱子一左一右立在殿的入口處,他給右邊那根取名叫雅斤,給左邊那根取名叫波阿斯