2 Kronika 2 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 2:1-18

Àwọn ètò fún kíkọ́ ilé Olúwa

1Solomoni pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀ 2Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn (70,000) ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn (80,000) ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìn-dínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.

32.3-16: 1Ọb 5.2-11.Solomoni rán iṣẹ́ yìí sí Hiramu ọba Tire:

“Rán àwọn igi kedari sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dafidi. Nígbà tí ó fi igi kedari ránṣẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé. 4Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé.

5“Ilé Olúwa tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn lọ. 6Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run tó ga jùlọ, kò le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún Olúwa, bí kò ṣe kìkì àti sun ẹbọ sun ẹbọ níwájú rẹ̀?

7“Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní àwọ̀ ojú ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú iṣẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Juda àti Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí baba à mi Dafidi pèsè.

8“Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ. 9Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nítorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀. 10Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ẹgbàáwàá (20,000), alikama ilẹ̀ àti ẹgbàáwàá (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ẹgbàáwàá (20,000), bati ọtí wáìnì àti ẹgbàáwàá (20,000) bati òróró olifi.”

11Hiramu ọba Tire fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Solomoni:

“Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti ṣe ọ́ ní ọba wọn.”

12Hiramu fi kún un pe:

“Ìyìn ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye, tí yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti ààfin fún ara rẹ̀.

13“Èmi ń rán Huramu-Abi, ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye sí ọ. 14Ọmọbìnrin kan nínú àwọn ọmọbìnrin Dani àti tí baba a rẹ̀ wá láti Tire tí ó gbọ́ngbọ́n àti ṣiṣẹ́ ní wúrà àti ní fàdákà, ní idẹ, ní irin, ní òkúta àti ní ìtì igi, ní èse-àlùkò, ní aláró, àti ní ọ̀gbọ̀ tí ó dára, àti òdòdó, láti gbẹ́ onírúurú ohun gbígbẹ́ pẹ̀lú, àti láti ṣe àwárí ìmọ̀ ẹ̀rọ irú ẹ̀yàkẹ́yà tí a ó fún un ṣe. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n olúwa mi, Dafidi baba a rẹ.

15“Nísinsin yìí, jẹ́ kí olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní alikama àti barle àti òróró Olifi náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí. 16Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lebanoni tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi Òkun lọ sí Joppa. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu.”

17Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbèjì-lélọ́gbọ̀n (153,600). 18Ó sì yan ẹgbàá-márùn-dínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbèjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

歷代志下 2:1-18

預備建聖殿

1所羅門決定為耶和華的名建造殿宇,也為自己興建王宮。

2他徵用七萬名搬運工、八萬名在山上鑿石的匠人、三千六百名監工, 3並派人去見泰爾希蘭,說:「你曾運香柏木給我父親建造王宮,請你也照樣幫助我。 4現在,我要為我的上帝耶和華的名建一座殿,我要把殿獻給祂,在祂面前燒芬芳的香,經常獻上供餅,在每天早晚、安息日、朔日2·4 朔日」即每月初一。及我們的上帝耶和華所定的節期獻上燔祭。這是以色列人應當永遠遵守的定例。 5我要建造的殿宇極其宏偉,因為我們的上帝超越一切神明。 6諸天尚且容納不下祂,誰能為祂建造殿宇呢?我是誰,怎能為祂建造殿宇?我不過是建個向祂燒香的地方。 7現在,請你派一位巧匠來,他要懂得雕刻,會用金銀銅鐵鑄造物品,會編織紫色、朱紅色和藍色的布,好與我父大衛猶大耶路撒冷所預備的巧匠一起工作。 8也請你從黎巴嫩運些香柏木、松木和檀香木來,因為我知道你的僕人擅長砍伐黎巴嫩的樹木。我會派人與你的僕人一起工作。 9我要建的殿宇非常宏偉,所以需要的木料非常多。 10我會供給你的伐木工人四百四十萬升小麥、四百四十萬升大麥、四十四萬升酒和四十四萬升油。」

11泰爾希蘭寫信給所羅門說:「耶和華愛祂的子民,所以立你做他們的王。 12創造天地的以色列的上帝耶和華當受稱頌!祂賜給大衛王一個有智慧、謀略和悟性的兒子來為耶和華建殿,也為他自己建造王宮。 13現在,我派聰明能幹的巧匠戶蘭去你那裡。 14他的母親是支派的人,父親是泰爾人。他精於雕刻和設計,善用金銀銅鐵和木石製造物品,又會編織紫色、藍色、朱紅色的布和細麻布。你可以讓他與你的工匠和你父親大衛的工匠一起工作。 15現在,請我主把許諾的小麥、大麥、油和酒運給僕人。 16我們會在黎巴嫩砍伐你需要的木材,紮成木筏,經海道運到約帕,你可以從那裡將木材轉運到耶路撒冷。」

17所羅門依照他父親大衛的方法,統計所有寄居在以色列的外族人,共有十五萬三千六百人。 18他指派其中的七萬人做搬運工,八萬人在山上採鑿石頭,三千六百人做監工。