1 Samuẹli 3 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 3:1-21

Olúwa pe Samuẹli

1Samuẹli ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Eli. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.

2Ní alẹ́ ọjọ́ kan Eli ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáradára, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìnwá. 3Nígbà tí iná kò tí ì kú Samuẹli dùbúlẹ̀ nínú tẹmpili Olúwa, níbi tí àpótí Olúwa gbé wà. 4Nígbà náà ni Olúwa pe Samuẹli.

Samuẹli sì dáhùn “Èmi nìyí” 5Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.”

Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀.

6Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.”

“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”

7Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.

8Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.”

Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà. 9Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

10Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!”

Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”

11Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. 12Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 13Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. 14Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

15Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli. 16Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.”

Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”

17Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.” 18Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni Olúwa; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”

19Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà. 20Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa. 21Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn án ní Ṣilo, nítorí Olúwa ti fi ará hàn án fún Samuẹli ní Ṣilo nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

1 Царств 3:1-21

Вечный призывает Самуила

1Мальчик Самуил служил перед Вечным при Илии. В те дни слово Вечного было редким, не часты были и видения.

2Как-то ночью Илий, чьи глаза ослабели настолько, что он едва мог видеть, лежал на своём обычном месте. 3Светильник Всевышнего ещё не догорел, и Самуил лежал в святилище Вечного, где находился сундук Всевышнего3:3 Сундук Всевышнего – см. пояснительный словарь, а также Исх. 25:10-22.. 4И Вечный позвал Самуила. Самуил ответил:

– Вот я!

5И подбежал к Илию, сказав:

– Вот я! Ты звал меня?

Но Илий сказал:

– Я не звал тебя, возвращайся и ложись спать.

Самуил пошёл и лёг.

6Вечный позвал его вновь:

– Самуил!

Самуил поднялся, пришёл к Илию и сказал:

– Вот я! Ты звал меня?

– Сын мой, – сказал Илий, – я не звал тебя, возвращайся и ложись спать.

7Самуил не знал ещё Вечного: слово Вечного ещё не открывалось ему.

8Вечный позвал Самуила в третий раз, и Самуил поднялся, пришёл к Илию и сказал:

– Вот я! Ты звал меня?

Тогда Илий понял, что мальчика зовёт Вечный. 9Илий сказал Самуилу:

– Иди и ложись, и если Он позовёт тебя, скажи: «Говори, Вечный, Твой раб слушает Тебя».

Самуил пошёл и лёг на своё место.

10Вечный пришёл и встал там, призывая, как в первый и во второй раз:

– Самуил! Самуил!

Тогда Самуил сказал:

– Говори, Твой раб слушает Тебя.

11И Вечный сказал Самуилу:

– Я собираюсь совершить в Исроиле такое, от чего у каждого, кто услышит об этом, зазвенит в ушах. 12Тогда Я исполню над Илием всё, что говорил против его семьи, – от начала до конца. 13Ведь Я говорил ему, что накажу его семью навеки из-за греха, о котором он знал, – его сыновья сделались презренными3:13 Или: «оскорбляли Всевышнего»., а он не обуздывал их. 14Поэтому Я клянусь дому Илия: «Вина дома Илия никогда не загладится жертвой или приношением».

15Самуил лежал до утра, а затем открыл двери дома Вечного. Он боялся передать Илию видение, 16но Илий позвал его и сказал:

– Самуил, сын мой!

Самуил ответил:

– Вот я.

17– Что Он сказал тебе? – спросил Илий. – Не скрывай от меня. Всевышний сурово накажет тебя, если ты скроешь от меня что-либо из того, что Он сказал тебе.

18Самуил рассказал ему всё, ничего не скрывая. Тогда Илий сказал:

– Он – Вечный, пусть поступает, как Ему угодно.

19Вечный был с Самуилом, когда тот вырос, и не оставил несбывшимся ни одного из его пророчеств. 20Весь Исроил от Дона на севере до Беэр-Шевы на юге признал, что Самуил – истинный пророк Вечного. 21Вечный продолжал являться в Шило, и там Он открывался Самуилу через Своё слово.