Isaías 47 – OL & YCB

O Livro

Isaías 47:1-15

A queda da Babilónia

1Ó filha virgem, cidade da Babilónia, vem e senta-te no pó da terra! Ó filha da Caldeia, nunca mais tornarás a ser a encantadora e delicada princesa! 2Toma a mó e mói a farinha; tira o véu e abre o teu vestido; descobre-te à vista de toda a gente e atravessa os rios. 3Ficarás despida e envergonhada, vingar-me-ei de ti e não me arrependerei.”

4Assim fala o nosso Redentor, que tem como nome Senhor dos exércitos, o Santo de Israel.

5“Senta-te nas trevas e no silêncio, ó filha da Caldeia! Nunca mais serás chamada rainha dos reinos! 6É verdade que estive irado contra o meu povo de Israel e que os castiguei, deixando-os cair nas tuas mãos, ó Babilónia. Mas tu não foste compreensiva com eles; até os velhos obrigaste a carregar fardos insuportáveis. 7Pensaste que o teu reino não acabaria mais. Nem um bocadinho te preocupaste com o meu povo ou pensaste no destino que teriam os que lhe fizessem mal.

8Ó reino dos loucos prazeres da vida fácil! Tu dizes: ‘Sou única no mundo! Sou como Deus! Nunca ficarei viúva! Nunca perderei os meus filhos!’ 9Pois bem, estas duas coisas virão sobre ti duma só vez e num só dia: a viuvez e a perda dos teus filhos, apesar das tuas feitiçarias e artes de magia.

10Sentias-te segura na tua maldade. ‘Ninguém me pode ver!’, dizias. A tua sabedoria e o conhecimento que pensavas ter perverteram-te e dizias: ‘Além de mim, mais nada!’ 11É por essa razão que o mal virá sobre ti repentinamente, tão inesperadamente que nem te darás conta donde vem. Nessa altura, já não haverá mais possibilidade para ti de resgate dos teus pecados.

12Chama os bandos de demónios que adoraste durante todos estes anos. Pede-lhes para ferirem novamente de terror muitos corações. 13Tens muitos conselheiros, os teus astrólogos e videntes que tentam descobrir o futuro para ti. 14Ser-te-ão tão inúteis como restolho para queimar. Nem sequer a si mesmos se podem livrar! 15Não obterás deles ajuda absolutamente nenhuma, não te darão conforto nem proteção. Todos os teus amigos de infância desaparecerão da tua vista, fugirão e te deixarão, porque são incapazes de te socorrer.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 47:1-15

Ìṣubú Babeli

147.1-15: Isa 13.1–14.23; Jr 50.1–51.64; Hk 1–2.“Sọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku,

wúńdíá ọmọbìnrin Babeli;

jókòó ní ilẹ̀ láìsí ìtẹ́,

ọmọbìnrin àwọn ará Babeli.

A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.

2Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun;

mú ìbòjú rẹ kúrò.

Ká aṣọ ẹsẹ̀ rẹ sókè, ká aṣọ itan,

kí o sì la odò wọ̀n-ọn-nì kọjá.

3Ìhòhò rẹ ni a ó sí síta

àti ìtìjú rẹ ni a ó ṣí sílẹ̀.

Èmi yóò sì gba ẹ̀san;

Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”

4Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀

òun ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

5“Jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn,

ọmọbìnrin àwọn ará Babeli;

a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrin

àwọn ilẹ̀ ọba mọ́.

6Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mi

tí mo sì ba ogún mi jẹ́;

Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,

Ìwọ kò sì ṣíjú àánú wò wọ́n.

Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lú

ní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

7Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé—

ọbabìnrin ayérayé!’

Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí

tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

847.8: If 18.7.“Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá

tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ

tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,

‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.

Èmi kì yóò di opó

tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

947.9: If 18.8.Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ

láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:

pípàdánù ọmọ àti dídi opó.

Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,

pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ

àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.

10Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ

ó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’

Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà

nígbà tí o wí fún ara rẹ pé,

‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’

11Ìparun yóò dé bá ọ

bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.

Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́

tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;

òfò kan tí o kò le faradà ni

yóò wá lójijì sí oríì rẹ.

12“Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ

àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,

tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.

Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,

bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.

13Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni

ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!

Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,

Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀

láti oṣù dé oṣù,

jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.

14Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi;

iná ni yóò jó wọn dànù.

Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là

lọ́wọ́ agbára iná náà.

Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná

níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.

15Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí

gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀

tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀;

kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.