Ezequiel 15 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Ezequiel 15:1-8

Jerusalén, una vid inútil

1La palabra del Señor vino a mí y me dijo: 2«Hijo de hombre, ¿en qué supera la madera de la vid a la madera de los árboles del bosque? 3¿Se extrae madera para hacer algo útil? ¿O se usa como soporte para colgar objetos? 4¡Escasamente sirve para alimentar el fuego! Pero ¿de qué sirve cuando sus extremos se consumen y ya se ha quemado por dentro? 5Si cuando estaba entera no servía para nada, ¡mucho menos cuando ya ha sido consumida por el fuego!

6»Por tanto, así dice el Señor y Dios: Como la leña de la vid, la cual aparté de los árboles del bosque y eché al fuego; así haré con los habitantes de Jerusalén. 7Voy a enfrentarme a ellos; ¡se han librado de un fuego, pero serán consumidos por otro! Cuando me enfrente a ellos, ustedes sabrán que yo soy el Señor. 8Dejaré a este país en ruinas, porque ha sido infiel, afirma el Señor y Dios».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 15:1-8

Jerusalẹmu, àjàrà tí kò wúlò

1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrín igi yòókù nínú igbó? 3Ǹjẹ́ a wa lè mú igi lára rẹ̀ ṣe nǹkan tí ó wúlò bí? Tàbí kí ènìyàn fi ṣe èèkàn tí yóò fi nǹkan kọ́? 4Lẹ́yìn èyí, ṣe a jù ú sínú iná gẹ́gẹ́ bí epo ìdáná, gbogbo igun rẹ̀ jóná pẹ̀lú àárín rẹ, ṣé o wà le wúlò fún nǹkan kan mọ́? 5Tí kò bá wúlò fún nǹkan kan nígbà tó wà lódidi, báwo ni yóò ṣe wá wúlò nígbà tí iná ti jó o, tó sì dúdú nítorí èéfín?

6“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Bí mo ṣe sọ igi àjàrà tó wà láàrín àwọn igi inú igbó yòókù di igi ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe ṣe gbogbo ènìyàn tó ń gbé Jerusalẹmu. 7Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan, síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. 8Èmi yóò sọ ilé náà di ahoro nítorí ìwà àìṣòótọ́ wọn, ni Olúwa Olódùmarè wí.”