Ezequiel 16 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Ezequiel 16:1-63

Infidelidad de Jerusalén

1La palabra del Señor vino a mí y me dijo: 2«Hijo de hombre, confronta a Jerusalén con sus abominaciones. 3Adviértele que así dice el Señor y Dios: “Jerusalén, tú eres cananea de origen y de nacimiento; tu padre era amorreo y tu madre, hitita. 4El día en que naciste no te cortaron el cordón umbilical, no te bañaron, no te frotaron con agua salada ni te envolvieron en pañales. 5Nadie se apiadó de ti ni te mostró compasión brindándote estos cuidados. Al contrario, el día en que naciste te arrojaron al campo como un objeto despreciable.

6»”Pasé junto a ti y te vi revolcándote en tu propia sangre. Estando en tu propia sangre te dije: ¡Vive! 7Te hice crecer como hierba del campo.

»”Creciste, te desarrollaste y entraste a la pubertad. Después se formaron tus senos y te brotó el vello, pero seguías completamente desnuda.

8»”Tiempo después pasé de nuevo junto a ti y te miré. Estabas en la edad del amor. Entonces te extendí mi manto y cubrí tu desnudez. Me comprometí, hice alianza contigo y fuiste mía, afirma el Señor y Dios.

9»”Te bañé, te limpié la sangre y te perfumé. 10Te puse un vestido bordado y te calcé con finas sandalias de cuero. Te vestí con ropa de tela de lino y de seda. 11Te adorné con joyas: puse pulseras en tus muñecas, collares en tu cuello, 12un arete en la nariz, pendientes en tus orejas y una hermosa corona en la cabeza. 13Quedaste adornada de oro y plata, vestida de tela de lino fino, de seda y de telas bordadas. Te alimentabas con harina refinada, con miel y aceite de oliva. Llegaste a ser muy hermosa y creciste para ser reina. 14Tan perfecta era tu belleza que tu fama se extendió por todas las naciones, pues yo te adorné con mi esplendor, afirma el Señor y Dios.

15»”Sin embargo, confiaste en tu belleza y, valiéndote de tu fama, te prostituiste. ¡Sin ningún pudor te entregaste a cualquiera que pasaba! 16Tomaste tus mismos vestidos para hacer altares paganos de vistosos colores y allí te prostituiste. ¡Algo nunca visto! 17Con las joyas de oro y plata que yo te había obsequiado, hiciste imágenes masculinas; con ellas te prostituiste ofreciéndoles culto. 18Les pusiste tus vestidos bordados, y les ofreciste mi aceite y mi incienso. 19Como ofrenda de olor grato les presentaste el alimento que yo te había dado: la harina refinada, el aceite de oliva y la miel, afirma el Señor y Dios.

20»”Tomaste también a los hijos y a las hijas que tuviste conmigo y los entregaste como alimento a esas imágenes. ¡No te bastaron tus prostituciones! 21Sacrificaste a mis hijos y los pasaste por fuego como ofrenda en honor de esos ídolos. 22En todas tus prácticas abominables y prostituciones no te acordaste de los días de tu adolescencia, cuando estabas completamente desnuda y pisoteando tu propia sangre.

23»”¡Ay de ti, ay de ti!, afirma el Señor y Dios. Para colmo de tus perversidades, 24construiste altares y un santuario en todas las plazas. 25¡En cada esquina construiste santuarios y degradaste tu belleza! Te abriste de piernas a cualquiera que pasaba, y fornicaste sin cesar. 26Te prostituiste con los egipcios, tus vecinos de grandes genitales, y para enfurecerme multiplicaste tus fornicaciones. 27Yo levanté mi mano para castigarte y reduje tu territorio; te entregué al deseo de tus enemigos, las ciudades16:27 ciudades. Lit. hijas. filisteas, que se avergonzaban de tu conducta depravada. 28Una y otra vez fornicaste con los asirios, porque eras insaciable. 29También creció tu promiscuidad para incluir a los comerciantes de Babilonia16:29 Lit. Caldea. y ni así quedaste satisfecha.

30»”¡Qué mente tan depravada la tuya!, afirma el Señor y Dios. ¡Te comportabas como una vil prostituta! 31Pero cuando en cada santuario armabas un prostíbulo y te exhibías en cada esquina, no te comportabas como una prostituta, ¡pues no cobrabas nada!

32»”¡Adúltera! Prefieres a los extraños, en vez de a tu marido. 33A todas las prostitutas se les paga; tú, en cambio, pagas a tus amantes. Los sobornas para que vengan de todas partes a acostarse contigo. 34En tu prostitución has sido diferente a otras mujeres: como nadie se te ofrecía, tú pagabas en vez de que te pagaran a ti. ¡En eso sí eras diferente a las demás!

35»”Por tanto, prostituta, escucha la palabra del Señor. 36Así dice el Señor y Dios: Has expuesto tu lujuria y exhibido tu desnudez al fornicar con tus amantes y con tus detestables ídolos; a estos has ofrecido la sangre de tus hijos. 37Por tanto, reuniré a todos tus amantes, a quienes brindaste placer; tanto a los que amaste como a los que odiaste. Los reuniré contra ti de todas partes y expondré tu desnudez ante ellos; ¡te verán completamente desnuda! 38Te juzgaré como a una adúltera y homicida; derramaré sobre ti mi ira y mi celo. 39Te entregaré en sus manos; ellos derribarán tus altares y demolerán tus santuarios. Te arrancarán la ropa y te despojarán de tus joyas, dejándote completamente desnuda. 40Convocarán a la asamblea contra ti, te apedrearán y te descuartizarán a filo de espada. 41Incendiarán tus casas y en presencia de muchas mujeres ejecutarán la sentencia contra ti. Yo pondré fin a tu prostitución; ya no volverás a pagarles a tus amantes. 42Así calmaré mi ira contra ti y se apaciguarán mis celos; me quedaré tranquilo y sin enojo.

43»”Yo te hago responsable de tu conducta por haberte olvidado de los días de tu adolescencia, por haberme irritado con todas estas cosas y por haber agregado infamia a tus prácticas abominables, afirma el Señor y Dios.

44»”Los que acostumbran citar refranes dirán esto de ti: ‘De tal palo, tal astilla’. 45Tú eres igual a tu madre, que despreció a su marido y a sus hijos; eres igual a tus hermanas, que despreciaron a sus maridos y a sus hijos. La madre de ustedes era hitita y su padre, amorreo. 46Tu hermana mayor era Samaria, ubicada al norte de ti con sus aldeas.16:46 aldeas. Lit. hijas; así en el resto de este capítulo. Tu hermana menor era Sodoma, ubicada al sur de ti con sus aldeas. 47No solo has seguido su conducta, sino que has actuado según sus prácticas abominables. En poco tiempo llegaste a ser peor que ellas. 48Yo, el Señor y Dios, tan cierto como que yo vivo, declaro que: ni tu hermana Sodoma ni sus aldeas hicieron jamás lo que tú y tus aldeas han hecho.

49»”Tu hermana Sodoma y sus aldeas pecaron de soberbia, gula, apatía e indiferencia hacia el pobre y el indigente. 50Se creían superiores a otras y en mi presencia se entregaron a las abominaciones. Por eso, tal como lo has visto, las he destruido. 51¡Pero ni Samaria ni sus aldeas cometieron la mitad de tus pecados! Te entregaste a más prácticas abominables que ellas, haciendo que ellas parecieran justas en comparación contigo. 52Ahora tú, carga con tu desgracia; porque son tantos tus pecados que has favorecido a tus hermanas al hacerlas parecer más justas que tú. ¡Avergüénzate y carga con tu desgracia! Has hecho que tus hermanas parezcan más justas que tú.

53»”Pero yo restauraré su fortuna, la fortuna de Sodoma y de Samaria, con sus respectivas aldeas, y haré lo mismo contigo. 54Así cargarás con tu desgracia, te avergonzarás de todo lo que hiciste y les servirás de consuelo. 55Tus hermanas, Sodoma y Gomorra, con sus respectivas hijas, volverán a ser como antes. Y tú y tus hijas regresarán al estado anterior. 56¿Acaso no te burlabas de tu hermana Sodoma en tu época de orgullo, 57antes de que se hiciera pública tu maldad? Ahora te has vuelto motivo de burla de las aldeas edomitas y filisteas, que te desprecian. 58Sobre tus hombros llevas el peso de tu infamia y de tus prácticas abominables, afirma el Señor.

59»”Así dice el Señor y Dios: Te daré tu merecido, porque has menospreciado el juramento y quebrantado el pacto. 60Sin embargo, yo sí me acordaré del pacto que hice contigo en los días de tu adolescencia, y estableceré contigo un pacto eterno. 61Tú te acordarás de tu conducta pasada y te avergonzarás cuando acojas a tus hermanas, la mayor y la menor, para dártelas como hijas, aunque no participan de mi pacto contigo. 62Yo estableceré mi pacto contigo y sabrás que yo soy el Señor. 63Cuando yo te perdone por todo lo que has hecho, tú te acordarás de tu maldad, te avergonzarás y en tu humillación no volverás a jactarte, afirma el Señor y Dios”».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 16:1-63

Òwe nípa àìṣòdodo Jerusalẹmu

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, mú kí Jerusalẹmu mọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀. 316.3: El 16.45.Sọ pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Jerusalẹmu: Ìran rẹ àti ilẹ̀ ìbí rẹ wà ní ilẹ̀ Kenaani; ará Amori ni baba rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará Hiti. 4Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fi omi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára rárá, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi aṣọ wé ọ. 5Kò sí ẹni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ dé bi à ti ṣe nǹkan kan nínú ìwọ̀nyí fún ọ, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ.

6“ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!” Nítòótọ́, nígbà tí ìwọ wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé “Yè” 7Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòhò láìfi nǹkan kan bora.

8“ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ̀ẹ́ rẹ ti tó, mo fi ìṣẹ́tí aṣọ mi bo ìhòhò rẹ. Mo búra fún ọ, èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú ìwọ sì di tèmi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

9“ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò ní ara rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára. 10Mo fi aṣọ oníṣẹ́-ọnà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ. Mo fi aṣọ funfun gbòò àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́. 11Mo fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà ọwọ́ sí ọ ní ọwọ́, mo fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn sí ọ ní ọrùn, 12Mo sì tún fi òrùka sí ọ ní imú, mo fi yẹtí sí ọ ní etí, mo sì fi adé tó rẹwà dé ọ ní orí. 13Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà; tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun gbòò, aṣọ olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí. Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ. Ó di arẹwà títí ó fi dé ipò ayaba. 14Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀-èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ ní àṣepé, ni Olúwa Olódùmarè wí.

15“ ‘Ṣùgbọ́n, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, ìwọ sì di alágbèrè nítorí òkìkí rẹ. Ìwọ sì fọ́n ojúrere rẹ káàkiri sí orí ẹni yówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ. 16Ìwọ mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi gíga òrìṣà tí ìwọ ti ń ṣe àgbèrè. Èyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá. 17Ìwọ tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀. 18Ìwọ sì wọ aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn. 19Ìwọ tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ—ìyẹ̀fun dáradára, òróró àti oyin—fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Olódùmarè wí.

20“ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rú ẹbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí? 21Tí ìwọ ti pa àwọn ọmọ mí, ìwọ sì fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, 22Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbèrè rẹ, ìwọ kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tí ìwọ wà ní ìhòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.’

23“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ‘Ègbé! Ègbé ni fún ọ. Lẹ́yìn gbogbo ìwà búburú rẹ, 24Ìwọ kọ́lé amọ̀ fún ara rẹ, ìwọ sì kọ́ ojúbọ gíga sí gbogbo òpin ojú pópó. 25Ní gbogbo ìkóríta ni ìwọ lọ kọ ojúbọ gíga sí, tí ìwọ sọ ẹwà rẹ di ìkórìíra, ìwọ sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ nípa fífi ara rẹ sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ. 26Ìwọ ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú ará Ejibiti tí í ṣe aládùúgbò rẹ láti mú mi bínú ìwọ sì ti sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀. 27Nítorí náà ni mo fi na ọwọ́ mi lé ọ lórí, mo sì ti bu oúnjẹ rẹ̀ kù; èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to kórìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Filistini ti ìwàkiwà rẹ tì lójú, 28Nítorí àìnítẹ́lọ́rùn rẹ ìwọ ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara Asiria; ìwọ ti bá wọn ṣe àgbèrè, síbẹ̀síbẹ̀, kò sì lè tẹ́ ọ lọ́rùn. 29Ìwọ si ti sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ láti ilẹ̀ Kenaani dé ilẹ̀ Kaldea; síbẹ̀ èyí kò sì tẹ́ ọ lọ́rùn níhìn-ín yìí.’

30Olúwa Olódùmarè wí pé, ‘Báwo ni ọkàn rẹ ṣe jẹ aláìlera tó tí o ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, bí iṣẹ́ àwọn agídí alágbèrè! 31Ni ti pé ìwọ kọ́ ilé gíga rẹ ni gbogbo ìkóríta, tí ìwọ sì ṣe gbogbo ibi gíga rẹ ni gbogbo ìta, ìwọ kò sì wa dàbí panṣágà obìnrin, ní ti pé ìwọ gan ọ̀yà.

32“ ‘Ìwọ alágbèrè aya! Ìwọ fẹ́ràn ọkùnrin àjèjì ju ọkọ rẹ lọ! 33Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn panṣágà ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe. 34Nínú àgbèrè rẹ ìwọ yàtọ̀ sí àwọn alágbèrè obìnrin yòókù; nínú àgbèrè rẹ tí ẹnìkan kò tẹ̀lé ọ láti ṣe àgbèrè; àti ní ti pé ìwọ ń tọrẹ tí a kò sì tọrẹ fún ọ, nítorí náà ìwọ yàtọ̀.

35“ ‘Nítorí náà, ìwọ alágbèrè, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! 36Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ìwọ tú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ jáde, ìwọ sì fi ìhòhò rẹ hàn, nípa ṣíṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ rẹ, àti nítorí gbogbo òrìṣà ìríra tí o fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ṣe ìrúbọ fún, 37nítorí náà, Èmi yóò ṣa gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ jọ, àwọn ẹni ti ìwọ ti bá jayé àti gbogbo àwọn tí ìwọ ti fẹ́ àti àwọn tí ìwọ kórìíra. Èmi yóò sa gbogbo wọn káàkiri jọ, láti mú wọn lòdì sí ọ, èmi yóò sí aṣọ rẹ, níwájú wọn, wọn yóò sì rí ìhòhò rẹ. 38Èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti dá obìnrin tó ba ìgbéyàwó jẹ́, tí wọn sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀; Èmi yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ ìbínú àti owú mi wá sórí rẹ. 39Nígbà náà ni èmi yóò fà ọ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn yóò sì wó gbogbo òkìtì rẹ pẹ̀lú àwọn ojúbọ rẹ palẹ̀. Wọn yóò tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ ni wọn yóò gbà, wọn yóò sì fi ọ sílẹ̀ ní ìhòhò àti ní àìwọṣọ. 40Wọn yóò pe àjọ ènìyàn jọ lé ọ lórí, àwọn tí yóò sọ ọ́ ní òkúta, tiwọn yóò sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́. 41Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin. Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ. Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́. 42Nígbà náà ni ìbínú mi sí o yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ; inú mi yóò rọ̀, èmi kò sì ní bínú mọ́.

43“ ‘Nítorí pé ìwọ kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sí orí rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí, Ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ mọ́?

44“ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.” 45Ìwọ ni ọmọ ìyá rẹ ti ó kọ ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀; ìwọ ni arábìnrin àwọn arábìnrin rẹ tí ó kọ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn: ara Hiti ni ìyá rẹ, ara Amori sì ni baba rẹ. 46Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaria, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá àríwá rẹ, àti àbúrò rẹ obìnrin ní ń gbé ọwọ́ òsì rẹ̀: àti àbúrò rẹ obìnrin ti ń gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin. 47Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà ìríra wọn ṣùgbọ́n ní àárín àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ 48Olúwa Olódùmarè wí pé, Bí mo ṣe wà láààyè, Sodomu tí í ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kò ṣe to ohun tí ìwọ àti ọmọbìnrin rẹ ṣe.

49“ ‘Wò ó, ẹ̀ṣẹ̀ tí Sodomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ṣẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran tálákà àti aláìní lọ́wọ́ 50Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti rò ó, nítorí ìgbéraga àti àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe. 51Samaria kò ṣe ìdajì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe. 52Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Nítorí náà rú ìtìjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.

53“ ‘Bi o tilẹ̀ jẹ pe: èmi yóò mú ìgbèkùn wọn padà, ìgbèkùn Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, pẹ̀lú Samaria àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, nígbà náà ni èmi yóò tún mú ìgbèkùn àwọn òǹdè rẹ wá láàrín wọn, 54kí ó bá à le rú ìtìjú rẹ, àti ẹ̀gàn gbogbo ohun tí ìwọ ṣe láti tù wọ́n nínú. 55Nígbà tí àwọn arábìnrin rẹ, Sodomu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ; Samaria àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ba padà si ipò tí wọn wà tẹ́lẹ̀, ìgbà náà ni ìwọ náà yóò padà sí ipò àtijọ́ rẹ. 56Ìwọ ko tilẹ̀ ní dárúkọ arábìnrin rẹ Sodomu ni ọjọ́ ìgbéraga rẹ, 57Kó tó di pé àṣírí ìwà búburú rẹ tú síta, báyìí ìwọ di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Edomu, Siria àti gbogbo agbègbè rẹ, àti lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Filistini àti lọ́dọ̀ àwọn tó yí ọ ká, tiwọn si ń kẹ́gàn rẹ. 58Èmi yóò gba ẹ̀san ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àwọn iṣẹ́ ìríra rẹ ní Olúwa wí.’

59“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ‘Èmi yóò hùwà sí ọ gẹ́gẹ́ bi ó ṣe tọ́ sí ọ, nítorí ó ti kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dídà májẹ̀mú. 60Síbẹ̀ èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ ṣe nígbà èwe rẹ, èmi yóò sì bá ọ dá májẹ̀mú láéláé. 61Nígbà náà ni ìwọ yóò rántí àwọn ọ̀nà rẹ ojú yóò sì tì ọ́ nígbà tí mo bá gba àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ obìnrin padà: Fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe lórí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá. 62Èmi yóò gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì mọ pé èmi ni Olúwa. 63Nígbà tí mo bá sì ti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tan, Èmi yóò sì rántí, ojú yóò tì ọ́, ìwọ kò sì ní le ya ẹnu rẹ mọ́ nítorí ìtìjú rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”