Isaías 17 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Isaías 17:1-14

Mensagem contra Damasco

1Advertência contra Damasco:

Damasco deixará de ser cidade;

vai se tornar um monte de ruínas.

2Suas cidades serão abandonadas;

serão entregues aos rebanhos que ali se deitarão,

e ninguém os espantará.

3Efraim deixará de ser uma fortaleza,

e Damasco uma realeza;

o remanescente de Arã será

como a glória dos israelitas,

anuncia o Senhor dos Exércitos.

4Naquele dia, a glória de Jacó se definhará,

e a gordura do seu corpo se consumirá.

5Será como quando um ceifeiro junta o trigo

e colhe as espigas com o braço,

como quando se apanham os feixes de trigo

no vale de Refaim.

6Contudo, restarão algumas espigas,

como, quando se sacode uma oliveira,

ficam duas ou três azeitonas nos galhos mais altos

e umas quatro ou cinco nos ramos mais produtivos,

anuncia o Senhor, o Deus de Israel.

7Naquele dia, os homens olharão para aquele que os fez

e voltarão os olhos para o Santo de Israel.

8Não olharão para os altares,

obra de suas mãos,

e não darão a mínima atenção aos postes sagrados

e aos altares de incenso que os seus dedos fizeram.

9Naquele dia, as suas cidades fortes, que tinham sido abandonadas por causa dos israelitas, serão como lugares entregues aos bosques e ao mato. E tudo será desolação.

10Porque vocês se esqueceram de Deus, do seu Salvador,

e não se lembraram da Rocha, da fortaleza de vocês.

Por isso, embora vocês cultivem as melhores plantas,

videiras importadas,

11as façam crescer no dia em que as semearem

e as façam florescer de manhã,

não haverá colheita

no dia da tristeza e do mal irremediável.

12Ah! O bramido das numerosas nações;

bramam como o mar!

Ah, o rugido dos povos;

rugem como águas impetuosas!

13Embora os povos rujam como ondas encapeladas,

quando ele os repreender, fugirão para longe,

carregados pelo vento como palha nas colinas,

como galhos arrancados pela ventania.

14Ao cair da tarde, pavor repentino!

Antes do amanhecer, já se foram!

Esse é o destino dos que nos saqueiam,

essa é a parte que caberá aos que roubam.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 17:1-14

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ní ti Damasku

117.1-3: Jr 49.23-27; Am 1.3-5; Sk 9.1.Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku:

“Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́

ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.

2Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀

fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,

láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.

3Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,

àti agbára ọba kúrò ní Damasku;

àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá

gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”

ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

4“Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá;

ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.

5Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn

irúgbìn tí ó dúró jọ

tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—

àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní Àfonífojì ti Refaimu.

6Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,

gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi,

tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù

sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,

mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”

ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.

7Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn

wọn yóò sì ṣíjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.

8Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,

èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn,

wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́

tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

9Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

10Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;

tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,

nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára

ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.

11Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,

àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n

ẹ mú kí wọ́n rúdí,

síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá

ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

12Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—

wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!

Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn

wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!

13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú

ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,

nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,

a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,

àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.

14Ní aginjù, ìpayà òjijì!

Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!

Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,

àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.