エゼキエル書 29 – JCB & YCB

Japanese Contemporary Bible

エゼキエル書 29:1-21

29

エジプトについての預言

1エホヤキン王が投獄されて十年目の第十の月の十二日に、主から次のようなことばがありました。

2「人の子よ、エジプトの王と民に預言しなさい。

3神である主がこう語る、と告げよ。

川の真ん中にいる巨竜のようなエジプトの王よ。

わたしはおまえの敵となる。

おまえが、『ナイル川は私のものだ。

私が自分のためにつくったのだ』と言っているからだ。

4わたしは、おまえのあごに鉤をかけ、

うろこについた魚ごと岸に引き上げる。

5おまえを魚もろとも、死ぬまで荒野に放っておく。

遺体を葬る者はいない。

わたしがおまえを野獣や鳥のえじきとしたからだ。

6イスラエルがわたしに頼る代わりに

おまえに助けを求めた時、

おまえにはそれだけの力がなかった。

そのことから、おまえたちはみな、

わたしが主であることを知るようになる。

7イスラエルはおまえに寄りかかった。

だがおまえは、ひびの入った杖のように折れた。

イスラエルは肩を砕き、痛みのあまりよろめいた。」

8それで、神である主は語ります。「ああ、エジプトよ。わたしは軍隊を送っておまえを攻め、人も家畜もみな滅ぼす。 9エジプトは荒れはてる。その時、エジプト人は、このようにしたのは主であるわたしだと知る。おまえは、『ナイル川は私のもの。私がつくったのだ』と言っている。 10それゆえわたしは、おまえとその川に向かって立ち上がり、ミグドルからセベネ、さらに南のエチオピヤとの国境に至るまで、エジプト全地を完全に滅ぼす。 11四十年間、誰ひとり、獣一匹さえエジプトを通らないだろう。もちろん、住む者もいなくなる。 12エジプトばかりか周囲の国々も荒廃させ、町々も四十年間、荒れ放題にする。わたしはエジプト人を他の国々に追い散らす。」

13主は語ります。「四十年が過ぎたら、エジプト人を散らされていた国々から連れ戻そう。 14エジプトの富を回復し、彼らが生まれ育った地、南エジプトのパテロスに帰らせる。だが、もうエジプトは、何の影響力もない小国となる。 15すべての国々の中でも最小の国となり、二度と他の国の上に立つこともない。今までのような大国には決してなれない。 16イスラエルも、二度とエジプトに助けを求めたりはしない。助けを求めようとするたびに、以前の苦い失敗を思い出すからだ。こうしてイスラエルは、わたしだけが神であることを認めるようになる。」

17エホヤキン王の捕囚から二十七年目の第一の月の一日、次のような主のことばがありました。 18「人の子よ。バビロンの王ネブカデネザルの軍隊がツロを激しく攻撃した。兵士たちは、土をいっぱい入れた重いバケツを載せて運んだために頭がはげ、肩は包囲攻撃に使う石の重さですりむけ、手にはまめができた。そうまでしても、ネブカデネザル王は何の戦利品も得られず、兵士たちに何も報いることができなかった。」 19そこで、神である主は語ります。「わたしは、バビロンの王ネブカデネザルにエジプトの地を与えよう。彼はエジプトの財宝を取り上げ、すべての物を奪って部下への報いとする。 20そう、わたしは、エジプトの地を報酬として彼に与える。彼はツロで十三年間、わたしのために働いたからだ。」このように主が語ります。

21「やがて、わたしがイスラエルに、昔の栄えを回復する日がくる。その日には、イスラエルの発言が重視される。こうしてエジプトは、わたしが主であることを知る。」

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 29:1-21

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ejibiti

129.1–32.32: Isa 19; Jr 46; Sk 14.18-19.Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. 3Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti

ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí

àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ

èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;

èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”

4Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ

èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ

gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.

Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,

àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.

5Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù

ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:

ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko

a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.

Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó

àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

6Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. 7Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

8“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: kéyèsi Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. 9Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.

“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; Èmi ni mo ṣe é,” 10Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.

13“ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀. 15Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”

Èrè Nebukadnessari

17Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18“Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀. 20Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

21“Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”