Prediker 1 – HTB & YCB

Het Boek

Prediker 1:1-18

Wijsheid heeft niets te betekenen

1De schrijver van dit boek wordt Prediker genoemd. Hij is koning in Jeruzalem en zoon van David.

2Naar mijn mening is niets van blijvende waarde, alles is zinloos.

3Want wat bereikt een mens met al zijn harde werken hier op aarde? 4Generaties gaan en generaties komen, maar er verandert niets wezenlijks. 5De zon komt op en gaat onder en haast zich rond de aarde om opnieuw op te gaan. 6De wind blaast vanuit het zuiden en het noorden, hier en daar, steeds wisselend van kracht en richting, zonder ooit een doel te bereiken. 7De rivieren monden uit in de zee, maar de zee raakt nooit vol. Het water keert weer terug naar de rivieren en vloeit weer naar de zee.

8Alles is onuitsprekelijk vermoeiend. Hoeveel wij ook zien, het is nooit genoeg. Hoeveel wij ook horen, tevreden zijn wij nooit. 9De geschiedenis herhaalt zich steeds weer. Niets is werkelijk nieuw, 10alles is al eens gezegd of gedaan. Kunt u iets nieuws aanwijzen? Hoe weet u of het eeuwen geleden ook al niet bestond? 11Wij kunnen niet meer achterhalen wat in vroeger tijden gebeurde en toekomstige generaties zullen zich niet meer herinneren wat wij in onze tijd hebben gedaan.

12Ik, Prediker, was koning van Israël en regeerde vanuit Jeruzalem. 13Ik nam mij voor de zin van alles wat onder de hemel gebeurde, te willen begrijpen. Dat is een vermoeiende bezigheid die God de mens heeft gegeven om hem nederig te maken. 14Alle arbeid is een opeenvolging van zinloosheid, het bouwen van luchtkastelen. 15Wat verkeerd is, kan niet worden goedgepraat en wat niet bestaat, kan niet worden onderzocht, het heeft geen enkel nut na te denken over wat had kunnen gebeuren. 16Ik zei tegen mijzelf: ‘Kijk, ik heb meer onderzocht dan welke andere koning ook die voor mij in Jeruzalem regeerde. Ik ben wijzer en heb meer inzicht.’ 17Daarom deed ik mijn uiterste best wijs te zijn in plaats van dwaas, maar nu realiseer ik mij dat zelfs dát een luchtkasteel is. 18Want hoe wijzer ik werd, des te bezorgder werd ik. Hoe meer iemand weet, des te meer verdriet hij heeft.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 1:1-18

Asán ni ohun ayé

1Ọ̀rọ̀ Oniwaasu, ọmọ Dafidi, ọba Jerusalẹmu:

2“Asán inú asán!”

oníwàásù náà wí pé,

“Asán inú asán!

Gbogbo rẹ̀ asán ni.”

3Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,

lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?

4Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,

síbẹ̀ ayé dúró títí láé.

5Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,

ó sì sáré padà sí ibi tí ó ti yọ.

6Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù,

Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,

a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.

7Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun,

síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún.

Níbi tí àwọn odò ti wá,

níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí.

8Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá,

ju èyí tí ẹnu le è sọ.

Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn,

bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.

9Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn

òun ni a ó tún máa ṣe padà

kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.

10Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé,

“Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”?

Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́,

o ti wà ṣáájú tiwa.

11Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú

bẹ́ẹ̀ ni ìrántí kì yóò sí fún

ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀

lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.

Asán ni ọgbọ́n ènìyàn

12Èmi, Oniwaasu ti jẹ ọba lórí Israẹli ní Jerusalẹmu rí. 13Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn: 14Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

15Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́,

ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.

16Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.” 17Nígbà náà ni mo fi ara jì láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti òmùgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

18Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá,

bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.