Jesaja 52 – HTB & YCB

Het Boek

Jesaja 52:1-15

De Here heeft zijn volk getroost

1Word wakker, word wakker, Jeruzalem en bekleed u met de kracht van God. Doe uw mooiste kleren aan, o Sion, Heilige Stad, want wie onbesneden of onrein is zal niet langer door uw poorten naar binnen komen. 2Kom omhoog uit het stof, Jeruzalem, neem de slavenbanden van uw nek, gevangengenomen dochter van Sion. 3Want de Here zegt: toen Ik u als ballingen verkocht, vroeg Ik geen geld van uw onderdrukkers. Nu koop Ik u ook terug zonder iets te betalen. 4Mijn volk werd zonder reden getiranniseerd door Egypte en Assur en Ik stond dat toe. 5En nu, wat is dit? vraagt de Here. Waarom is mijn volk weer slaaf en wordt het zonder reden onderdrukt? Zij die het overheersen, roemen in hoogmoed en mijn naam wordt de hele dag door het slijk gehaald. 6Daarom zal Ik mijn naam aan mijn volk bekendmaken en het zal de kracht kennen die in die naam schuilt. Dan zal het ten slotte ontdekken dat Ik tegen hen spreek.

7Wat heerlijk zijn op de bergen de voeten van de brengers van het goede nieuws van vrede en heil, het nieuws dat de God van Israël regeert. 8De wachtposten schreeuwen en zingen van blijdschap, want met hun eigen ogen zien zij hoe de Here God zijn volk weer naar huis terugbrengt. 9Laten de ruïnes van Jeruzalem uitbarsten in blij gezang, want de Here heeft zijn volk getroost. Hij heeft Jeruzalem verlost. 10Aan alle volken heeft de Here laten zien hoe machtig Hij is, de verste uithoeken van de aarde zullen het heil van onze God zien. 11Ga uit, ga daar weg, raak het onreine niet aan. Laat Babel en alles wat het belichaamt, ver achter u. Het is onrein voor u. U bent het heilige volk van de Here, reinig uzelf, allen die vaten van de Here naar zijn huis dragen. 12U zult niet haastig vertrekken, rennend voor uw leven, want de Here zal voor u uit gaan en Hij, de God van Israël, zal u van achteren beschermen.

13Kijk, mijn dienaar krijgt voorspoed, Hij zal hoog worden verheven. 14-15 Zoals voorheen velen zich over Hem ontzetten, zelfs vorsten om Hem huiverden, omdat zijn uiterlijk misvormd en niet meer menselijk was, zo staan nu vele volken verbaasd en sluiten koningen hun mond, omdat zij zien wat hun nog nooit was verteld en omdat zij aanschouwen wat nog nooit was gehoord.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 52:1-15

152.1: If 21.27.Jí, jí, Ìwọ Sioni,

wọ ara rẹ ní agbára.

Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,

ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.

Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́

kì yóò wọ inú rẹ mọ́.

2Gbọn eruku rẹ kúrò;

dìde sókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jerusalẹmu.

Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,

ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.

3Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;

“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,

láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.

“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀

lọ sí Ejibiti láti gbé;

láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.

552.5: Ro 2.24.“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.

“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,

àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”

ni Olúwa wí.

“Àti ní ọjọọjọ́

orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.

6Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;

nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀

pé Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

752.7: Ap 10.36; Ro 10.15; Ef 6.15.Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè

ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìhìnrere ayọ̀ wá,

tí wọ́n kéde àlàáfíà,

tí ó mú ìhìnrere wá,

tí ó kéde ìgbàlà,

tí ó sọ fún Sioni pé,

“Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

8Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè

wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.

Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni,

wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.

9Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,

ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu,

nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,

ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.

1052.10: Lk 2.30; 3.6.Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀

ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè,

àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí

ìgbàlà Ọlọ́run wa.

1152.11: 2Kọ 6.17.Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín-yìí!

Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!

Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.

12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò

tàbí kí ẹ sáré lọ;

nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ,

Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.

Ìpọ́njú àti ògo ìránṣẹ́ náà

13Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;

òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga

a ó sì gbé e lékè gidigidi.

14Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—

ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.

1552.15: Ro 15.21.Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,

àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.

Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,

àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.