Jesaja 38 – HTB & YCB

Het Boek

Jesaja 38:1-22

Hizkiaʼs ziekte

1In de tijd dat deze gebeurtenissen plaatshadden, werd Hizkia ernstig ziek. De profeet Jesaja zocht hem op en gaf hem de boodschap van de Here: ‘Regel uw zaken, want uw einde nadert, u zult niet herstellen van deze ziekte.’ 2Toen Hizkia dat hoorde, draaide hij zijn gezicht naar de muur en bad: 3‘Och Here, herinnert U Zich niet meer dat ik U altijd trouw ben geweest en ik altijd heb geprobeerd U te gehoorzamen in alles wat U zei?’ En hij huilde.

4Daarom stuurde de Here een andere boodschap naar Jesaja: 5‘Ga naar Hizkia en zeg hem: “De Here God van uw voorvader David hoort uw bidden en ziet uw tranen. Hij zal u nog vijftien jaar laten leven. 6Hij zal u en deze stad uit de macht van de koning van Assur verlossen. Ik zal u beschermen,” ’ zegt de Here, 7‘en dit is het bewijs dat Ik, de Here, dit woord dat Ik heb gesproken ook echt zal doen: 8Ik zal de schaduw van de zon op de zonnewijzer van Achaz tien graden laten teruggaan!’ En de zon liep de tien graden terug die hij al had afgelegd!

9Toen koning Hizkia weer beter was, schreef hij een gedicht over deze gebeurtenis: 10‘Mijn leven is pas half voorbij en ik moet het al verlaten. Ik betreed het dodenrijk, verloren zijn mijn toekomstige jaren. 11Ik zal de Here nooit meer zien in het land der levenden. Mijn vrienden in deze wereld moet ik achterlaten. 12Mijn leven wordt weggeblazen als een herderstent, het wordt afgesneden zoals een wever zijn werk van het weefgestoelte afsnijdt. In één dag komt mijn leven aan een zijden draad te hangen. 13Ik kon de hele nacht niet slapen van verdriet, het was alsof leeuwen mij verscheurden. 14In het nauw gedreven, tjilp ik als een zwaluw en kir ik als een duif. Ik kijk verlangend omhoog en roep: “Och Here, ik ben bang, help mij toch.” 15Maar wat moet ik zeggen? Want Hij stuurde deze ziekte. Ik ben verbitterd en ik kan de slaap niet vatten. 16Och Here, uw leefregels zijn goed, zij zorgen voor leven en gezondheid. Genees mij en breng mij weer tot leven! 17Ja, nu begrijp ik dat deze bitterheid goed voor mij is geweest. U hebt mij liefdevol uit de macht van de dood verlost. U hebt mij al mijn zonden vergeven. 18Want doden kunnen U niet prijzen. Zij die in het graf zijn, kennen geen hoop en vreugde. 19De levenden, alleen de levenden, kunnen U prijzen zoals ik nu doe. Laten de vaders het aan hun kinderen doorvertellen. 20Denk u eens in! De Here genas mij! Van nu af aan zal ik, zolang ik leef, elke dag in de tempel van de Here lofliederen zingen op de muziek van de instrumenten.’ 21Jesaja had tegen Hizkiaʼs dienaren gezegd: ‘Neem een plak gedroogde vijgen en wrijf daar de ontstoken plek mee in, dan zal hij weer beter worden.’ 22En Hizkia had gevraagd: ‘Welk teken zal de Here mij geven als bewijs dat Hij mij zal genezen?’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 38:1-22

Àìsàn Hesekiah

1Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí Olúwa wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”

2Hesekiah yí ojú u rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí Olúwa, 3“Rántí, Ìwọ Olúwa, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.

4Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Isaiah wá pé 5“Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé: Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ; Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. 6Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.

7“ ‘Èyí yìí ni ààmì tí Olúwa fún ọ láti fihàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ: 8Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

9Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán:

10Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi

èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú

kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”

11Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́,

àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè;

èmi kì yóò lè ṣíjú wo ọmọ ènìyàn mọ́,

tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń

gbe orílẹ̀ ayé báyìí.

12Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi

ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi.

Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà;

ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

13Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́,

ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi;

ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.

14Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀,

Èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà.

Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run.

Ìdààmú bá mi; Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”

15Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ?

Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun

tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí.

Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi

nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.

16Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;

àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú.

Ìwọ dá ìlera mi padà

kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè

17Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni,

ní ti pé mo ní ìkorò ńlá.

Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́,

kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;

ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.

18Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́,

ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;

àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun

kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.

19Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,

gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;

àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.

20Olúwa yóò gbà mí là

bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn

ní gbogbo ọjọ́ ayé wa

nínú tẹmpili ti Olúwa.

21Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”

22Hesekiah si sọ pé, “Kí ni yóò jẹ́ ààmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa?”