אגרת פולוס השנייה אל-טימותיוס 2 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרת פולוס השנייה אל-טימותיוס 2:1-26

1טימותיוס, בני, עליך להתחזק בכוח ובחסד שמעניק לך המשיח. 2למד אנשים אחראיים את דברי האמת אשר שמעת מפי בנוכחות עדים רבים, כדי שבבוא הזמן הם ילמדו את האחרים.

3קבל את חלקך בסבל למען המשיח, כמוני, כחייל גיבור במלחמת ישוע המשיח. 4וכחייל של ישוע המשיח אל תתערב יותר מדי בענייני העולם הזה, כדי שתוכל להשביע את רצונו של מי שגייס אותך לצבאו. 5בעשותך את אשר הטיל עליך האדון, עליך לנהוג לפי הכללים שלו. גם הספורטאי לא יזכה בפרס אם לא יתחרה לפי הכללים! 6האיכר החרוץ שמעבד את אדמתו זכאי לאכול ראשון את ביכורי הפרי. 7חשוב היטב על דברים אלה, ואלוהים יעזור לך להבינם.

8לעולם אל תשכח את הבשורה שאני מבשר; תקומתו של ישוע המשיח מן המתים, והיותו משושלת דוד המלך. 9הם כלאו אותי בבית־הסוהר כמו פושע, משום שהפצתי את האמת הזאת, אך דבר האלוהים אינו כלוא! 10אני מוכן לסבול הכול למען בחירי האלוהים, כדי שגם הם ייוושעו ויזכו בכבוד עולמים בישוע המשיח.

11אכן נכון השיר:

אם מתנו עם המשיח, גם נחיה איתו;

12אם נסבול למענו, גם נמלוך איתו;

אם נתכחש אליו, גם הוא יתכחש אלינו;

13אף אם לא נאמין, הוא תמיד נאמן,

כי אין הוא יכול לכחש בעצמו.

14הזכר לאנשיך דברים אלה וצווה עליהם, בשם האדון, לא להתווכח על דברים חסרי ערך. ויכוחים כאלה מבלבלים את השומעים ומזיקים להם. 15שקוד להשביע את רצון ה׳ – כפועל שאין לו כל סיבה להתבייש בעבודתו, וכאדם שיודע להשתמש בדבר האמת בצורה המועילה ביותר. 16התרחק מוויכוחים מטופשים אשר מרגיזים ומכעיסים, וכך מביאים לידי חטא. 17ויכוחים מטופשים אלה מתפשטים כמו ריקבון ומכאיבים לאנשים שמעורבים בהם. הומניוס ופיליטוס מעוררים ויכוחים כאלה. 18השניים, שהפנו עורף לאמת, מפיצים את השקר כאילו כבר הייתה תחיית המתים. במעשה זה הם החלישו ובלבלו את אמונתם של אלה שהאמינו להם.

19אולם דבר אינו יכול לערער את אמת האלוהים; היא עומדת איתנה כסלע שעליו חקוק: ”יודע ה׳ את אשר לו“. ו”הקורא לעצמו מאמין באלוהים צריך להתרחק מכל רע“.

20בבית העשיר יש כלים שעשויים מזהב ומכסף, ויש גם כלים שעשויים מעץ ומחמר. את הכלים היקרים מגישים לאורחים, ואילו בכלים הזולים משתמשים לעבודות המטבח או ככלי אשפה. 21כדי להשתייך לחשוב וליקר – להיות חפץ בעל־ערך לבעל הבית – עליך לטהר את עצמך ולהתרחק מכל חטא, ואז יוכל המשיח להשתמש בך למטרותיו הנעלות.

22ברח לך מתאוות הנעורים, והתקרב לכל דבר שמעודד אותך לעשות מעשים טובים. שאף לצדק, לשלום, לאמונה ולאהבה, ובקש את חברתם של האוהבים את אלוהים בלב טהור.

23אני חוזר ואומר: התרחק מוויכוחים טיפשיים וחסרי טעם, אשר רק מרגיזים אנשים וגורמים למריבות. 24המאמין באלוהים אינו צריך לריב עם אחרים, אלא עליו להיות אדיב וסובלני, וללמד את הדרך הטובה לאלה שאינם הולכים בה. 25כשאתה מוכיח את המתכחשים לדבר ה׳, נהג בהם בענווה ובעדינות, כי אז, בעזרת ה׳, הם עשויים לשוב מדרכם הרעה ולהאמין באמת. 26כך תשוב אליהם בינתם והם יברחו ממלכודת השטן – שלכד אותם כדי שישרתוהו – ויתחילו לעשות את רצון האלוהים.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Timotiu 2:1-26

1Nítorí náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kristi Jesu. 2Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòtítọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. 3Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi. 4Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn. 5Ní ọ̀nà kan náà, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń díje bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà 6Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso. 7Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.

8Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. 9Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 10Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé.

11Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:

Bi àwa bá bá a kú,

àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.

12Bí àwa bá faradà,

àwa ó sì bá a jẹ ọba:

Bí àwa bá sẹ́ ẹ,

òun náà yóò sì sẹ́ wa.

13Bí àwa kò bá gbàgbọ́,

òun dúró ni olóòtítọ́:

Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.

Òṣìṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn

14Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ fún wọn níwájú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́. 15Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ 16Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí tiwọn máa síwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run. 17Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Filetu wà; 18àwọn ẹni tí ó ti ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú. 192.19: Nu 16.5; Isa 26.13.Ṣùgbọ́n ìpìlẹ̀ Ọlọ́run tí ó dájú dúró ṣinṣin, ó ní èdìdì yìí, pé, “Olúwa mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Kí olúkúlùkù ẹni tí ń pé orúkọ Olúwa kúrò nínú àìṣòdodo.”

20Ṣùgbọ́n nínú ilé ńlá, kì í ṣe kìkì ohun èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá. 21Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.

22Máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èwe: sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá. 23Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní ẹ̀kọ́ nínú ni kí o kọ̀, bí o ti mọ̀ pe wọn máa dá ìjà sílẹ̀. 24Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù. 25Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́, 26wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdẹ̀kùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.