אגרת פולוס השנייה אל-טימותיוס 3 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרת פולוס השנייה אל-טימותיוס 3:1-17

1דע לך, טימותיוס, שבאחרית הימים יבואו זמנים קשים. 2האנשים יהיו אנוכיים ויאהבו רק את עצמם ואת כספם; הם יתהללו בעצמם, יתגאו, יקללו את אלוהים, ימרו את פי הוריהם, יהיו כפויי טובה ויעשו כל מעשה רע. 3הם יהיו חסרי אהבה וחסרי רחמים; הם ישמיצו אחרים ויהיו חסרי ריסון עצמי. הם יהיו אכזריים ושונאי כל דבר טוב. 4הם יבגדו בחבריהם, ימהרו לכעוס, יהיו גאוותנים ויאהבו תענוגות במקום שיאהבו את אלוהים. 5הם יעמידו פנים כאילו הם מאמינים באלוהים, ואפילו ישתתפו באסיפות הקהילה, אבל הם לא יאמינו למה שישמעו. היזהר מאנשים כאלה!

6הם מסוג האנשים המתגנבים אל בתי אחרים, ומתחברים עם נערות קלות דעת ומלאות חטאים, הנשלטות על־ידי תאוותיהן, ומלמדים אותן את תורת השקר שלהם. 7נערות כאלה תמיד נוטות ללכת אחרי מורים חדשים; הן מוכנות ללמוד מכל אחד, אבל לעולם אינן מסוגלות לבוא לידיעת האמת. 8כשם שיניס וימבריס התנגדו למשה רבנו, כך מתנגדים מורי השקר האלה באמת. מחשבותיהם טמאות ומושחתות, והם נלחמים באמונה המשיחית. 9אך הם לא יגיעו רחוק! יום אחד יתגלה השקר שלהם לכולם – כמו שקרה לחטא של יניס וימבריס.

10אך אתה טימותיוס, אתה יודע מה אני מלמד, מהו אורח־חיי ומהי מטרתי בחיים. אתה מכיר את אמונתי, סבלנותי, אהבתי והתמדתי. 11אתה יודע כמה סבלתי כתוצאה מכך שהטפתי את הבשורה. אתה יודע את כל אשר קרה לי כשביקרתי באנטיוכיה, באיקניון ובלוסטרא, אך האדון הצילני מכל הצרות, הרדיפות והסבל. 12למעשה, כל אלה שיבחרו לשרת את המשיח בחיי קדושה יסבלו מידי שונאיהם. 13האנשים הרעים ומורי השקר יגבירו את מעשיהם הרעים, וימשיכו להתעות את בני־האדם, כי הם עצמם הותעו על־ידי השטן.

14אולם אתה, טימותיוס, המשך להאמין במה שלמדת. אתה יודע שאלה הם דברי אמת, ושאתה יכול לבטוח באלה מאיתנו שלימדו אותך. 15עוד בילדותך ידעת והכרת את כתבי־הקודש, אשר החכימו אותך והכשירו אותך לקבלת ישועת האלוהים באמצעות האמונה בישוע המשיח. 16כל כתבי־הקודש נכתבו בהשראת אלוהים. הם מלמדים אותנו את אמת האלוהים, מתקנים את טעויותינו ומדריכים את חיינו בדרך הישרה והצודקת. 17זוהי דרכו של אלוהים להכשירנו לעשות תמיד מעשים טובים.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Timotiu 3:1-17

Ìwà àwọn ènìyàn ni ọjọ́ ìkẹyìn

1Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. 2Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. 3Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, 4oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. 5Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

6Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri 7Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. 83.8: Ek 7.11.Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. 9Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú Paulu sí Timotiu

10Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 113.11: Ap 13.14-52; 14.1-20; 16.1-5.Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni 13Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 16Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. 17Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.