帖撒羅尼迦前書 2 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

帖撒羅尼迦前書 2:1-20

保羅在帖撒羅尼迦的工作

1弟兄姊妹,你們自己知道,我們那次探望你們並沒有白費。 2你們也知道,我們之前在腓立比遭受了迫害和凌辱,遇到強烈的反對,但仍然靠著我們的上帝放膽向你們傳揚祂的福音。 3我們的勸勉並非出於謬誤、不良動機或詭詐。 4我們得到了上帝的認可,受委派傳福音。我們不是要取悅人,而是要取悅鑒察我們內心的上帝。

5你們知道,我們沒有花言巧語奉承人,也沒有心存貪念,上帝可以為我們作證。 6我們不求得到你們或其他任何人的讚揚。 7身為基督的使徒,我們理當受到你們的尊重,然而我們像母親撫育嬰兒一樣溫柔地對待你們。 8我們深愛你們,對你們有深厚的感情,不僅樂意把上帝的福音傳給你們,甚至把生命給你們也在所不惜。

9弟兄姊妹,你們一定記得我們的勞苦和艱難。我們一面向你們傳福音,一面晝夜辛勤工作,免得成為你們任何人的負擔。 10我們怎樣以聖潔、公義、純全的方式對待你們眾信徒,你們自己可以作證,上帝也可以作證。 11你們也知道,我們對待你們就像父親對待自己的孩子一樣。 12我們安慰你們,勸勉你們,督促你們,好叫你們行事為人對得起上帝,祂呼召你們進入祂的國、享受祂的榮耀。

13我們不住地感謝上帝,因為你們從我們這裡聽了上帝的道後就接受了,確信這不是人的道理,而是上帝的道。這道正在你們信的人心裡發揮作用。

14弟兄姊妹,你們的遭遇和猶太地區基督耶穌的眾教會的遭遇一樣。你們受到了自己同胞的迫害,他們也受到了猶太人的迫害。 15這些猶太人殺死了主耶穌和眾先知,又迫害我們。他們不但冒犯上帝,還與所有的人為敵, 16阻止我們傳福音給外族人,唯恐他們得救。這些人惡貫滿盈,上帝的烈怒終於臨到了他們頭上。

保羅渴望去帖撒羅尼迦

17弟兄姊妹,我們暫時與你們分離,心靈卻與你們在一起。我們非常渴望見到你們。 18我們想去你們那裡,我保羅也一次又一次地想去,只是遭到撒旦的攔阻。 19我們主耶穌再來的時候,我們在祂面前的盼望、喜樂和可誇耀的冠冕是什麼呢?不就是你們嗎? 20因為你們是我們的榮耀和喜樂。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Tẹsalonika 2:1-20

Iṣẹ́ Paulu ní ìjọ Tẹsalonika

1Ẹ̀yin pàápàá mọ̀ ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán. 22.2: Ap 16.19-24; 17.1-9; Ro 1.1.Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìhìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle. 3Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè. 4Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìhìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò. 52.5: Ap 20.33.A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa. 62.6: 1Kọ 9.1.A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín. 72.7: 1Tẹ 2.11; Ga 4.19.Ṣùgbọ́n àwa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrín yín tí a sì ṣe ìtọ́jú yín.

Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀, 82.8: 2Kọ 12.15; 1Jh 3.16.bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa. 9Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín. 10Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 112.11: 1Kọ 4.14.Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ 122.12: 1Pt 5.10.ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.

132.13: 1Tẹ 1.2.Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 14Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù, 152.15: Lk 24.20; Ap 2.23; 7.52.àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn 162.16: Ap 9.23; 13.45,50; 14.2,5,19; 17.5,13; 18.12; 21.21,27; 25.2,7; 1Kọ 10.33; Gẹ 15.16; 1Tẹ 1.10.nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìhìnrere dúró láàrín àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń di púpọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.

Paulu n fẹ́ láti rí àwọn ìjọ Tẹsalonika

172.17: 1Kọ 5.3.Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín. 18Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Paulu, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n èṣù ú dè wá lọ́nà. 192.19: Fp 4.1; 1Tẹ 3.13; 4.15; 5.23; Mt 16.27; Mk 8.38.Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó ṣògo níwájú Jesu Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ́ ni? 202.20: 2Kọ 1.14.Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.