Исаия 10 – CARSA & YCB

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Исаия 10:1-34

1Горе издающим несправедливые законы

и пишущим жестокие постановления,

2чтобы лишать бедняков их прав

и отнимать правосудие у слабых из Моего народа;

делающим вдов своей добычей

и обирающим сирот!

3Что вы будете делать в день кары,

когда издалека придёт беда?

К кому побежите за помощью?

Где оставите свои богатства?

4Остаётся только с пленниками согнуть колени

или пасть среди убитых.

Но и тогда гнев Его не отвратится,

и рука Его ещё будет занесена.

Суд Аллаха над Ассирией

5– Горе Ассирии, жезлу Моего негодования;

в её руке бич гнева Моего!

6Я посылаю её против этого безбожного народа,

Я отправляю её против народа, на который гневаюсь,

чтобы захватить добычу и взять поживу,

растоптать их, как уличную грязь.

7Но она это не осознаёт,

об этом не думает;

её замысел – губить,

истребить множество народов.

8«Не все ли цари – мои вельможи? – говорит она. –

9Не пришлось ли пасть городу Халне, как и Каркемишу,

Хамату, как и Арпаду,

Самарии, как и Дамаску?10:9 Все эти города подпали под власть Ассирии во второй половине VIII в. до н. э.

10Рука моя захватила множество царств,

чьи идолы превосходили иерусалимских и самарийских.

11Я так же разделаюсь с Иерусалимом и его истуканами,

как разделалась с Самарией и её идолами!»

12Когда Владыка завершит Своё дело против горы Сион и Иерусалима, Он скажет:

– Покараю хвастливую надменность царя Ассирии и его высокомерную гордыню. 13Ведь тот говорит:

«Силой моей руки я совершил это

и мудростью моей, потому что я умён.

Я стёр границы народов

и расхитил их запасы;

как силач, я низверг их правителей.

14Рука моя овладела богатствами народов,

будто разорила гнездо;

как собирают покинутые яйца,

я собрал все страны.

И никто не взмахнул крылом,

рта не раскрыл и не пискнул».

15Разве топор поднимается над тем, кто им рубит,

или пила кичится перед тем, кто ею пилит?

Как будто палка может поднять того, кто её поднимает,

или дубинка взмахнуть тем, кто не из дерева!

16Поэтому Владыка Вечный, Повелитель Сил,

нашлёт на крепких воинов Ассирии чахлость,

и под великолепием её вспыхнет пламя,

как от пылающего костра.

17Свет Исраила станет огнём,

святой Бог его – пламенем,

которое в один день сожжёт и пожрёт

терновник её и колючки;

18славные леса и сады её полностью уничтожит,

и станет Ассирия как угасающий больной;

19а деревьев от лесов останется так мало,

что и дитя сможет их пересчитать.

Остаток Исраила

20В тот день остаток Исраила,

уцелевшие потомки Якуба,

не станут уже полагаться на того,

кто разил их,

но истинно положатся на Вечного,

на святого Бога Исраила.

21Остаток вернётся10:21 Букв.: «шеар иашув»; также в ст. 22. Это имя старшего сына Исаии (см. 7:3)., остаток потомков Якуба

вернётся к могучему Богу.

22Хотя твой народ, Исраил, многочислен, как песок морской,

вернётся лишь остаток.

Уничтожение предначертано,

преисполнено праведностью.

23Владыка Вечный, Повелитель Сил, совершит истребление,

как и предначертано, по всей земле.

24Поэтому так говорит Владыка Вечный, Повелитель Сил:

– Мой народ, живущий на Сионе,

не бойся ассирийцев,

которые бьют тебя палкой

и поднимают на тебя дубинку,

как это делал Египет.

25Очень скоро Моё негодование на тебя пройдёт

и Мой гнев обратится им на погибель.

26Вечный, Повелитель Сил, поднимет на них бич,

как когда-то Он поразил Мадиан у скалы Орив10:26 См. Суд. 7:25.,

и поднимет Свой посох над водами,

как некогда в Египте10:26 См. Исх. 14:15-31..

27В тот день их бремя будет снято с твоих плеч

и их ярмо с твоей шеи,

и ярмо сломается

от твоей растущей силы10:27 Букв.: «от жира»..

28Они пришли в Гай,

прошли Мигрон,

сложили припасы в Михмасе.

29Прошли перевал,

ночуют в Геве.

Рама трепещет,

бежит Гива Шаула.

30Вой, Галлим!

Внимай, Лайша!

Отвечай, Анатот!

31Мадмена разбежалась;

жители Гевима скрываются.

32В этот же день они остановятся в Нове,

погрозят кулаком

горе Сиону,

холму Иерусалима10:28-32 Данные стихи описывают поход ассирийцев на Иерусалим, перечисляя с севера на юг завоёванные ими по дороге иудейские города..

33Вот Владыка Вечный, Повелитель Сил,

со страшной силой очистит деревья от сучьев.

Величественные деревья будут срублены,

и высокие деревья рухнут на землю.

34Чащи лесные Он вырубит топором,

и падут леса Ливана перед Могучим.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 10:1-34

1Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo

2láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn

àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò

níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,

Wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn.

Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.

3Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò

nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá?

Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?

Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?

4Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn

tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa.

Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,

ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Asiria

510.5-34: Nh; Sf 2.13-15.“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,

ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

6Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run

Mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú

láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun

láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

7Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,

èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;

èrò rẹ̀ ni láti parun,

láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.

8‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.

9‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?

Hamati kò ha dàbí i Arpadi,

àti Samaria bí i Damasku?

10Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,

ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.

11Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

12Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀. 13Nítorí ó sọ pé:

“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí

àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.

Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,

Mo sì ti kó ìṣúra wọn.

Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.

14Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,

bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.

Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè

kò sí èyí tí ó fi apá lu apá,

tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

15Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,

tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó?

Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,

tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

16Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí

àwọn akíkanjú jagunjagun,

lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ

gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

17Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,

Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,

ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run

àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.

18Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá

gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,

gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.

19Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀

yóò kéré níye,

tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Àwọn ìyókù Israẹli

20Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,

Àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,

kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà

tí ó lù wọ́n bolẹ̀,

ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

Ẹni Mímọ́ Israẹli.

21Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu

yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.

22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli

dàbí yanrìn ní Òkun,

ẹni díẹ̀ ni yóò padà.

A ti pàṣẹ ìparun

àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.

23Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,

ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí

gbogbo ilẹ̀ náà.

24Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,

“Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,

Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,

tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,

tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí

Ejibiti ti ṣe.

25Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin

n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n,

fún ìparun wọn.”

26Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani

ní òkè Orebu,

yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi

gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.

27Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín,

àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín

a ó fọ́ àjàgà náà,

nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.

28Wọ́n wọ Aiati,

Wọ́n gba Migroni kọjá

Wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mikmasi.

29Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,

“Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.”

Rama mì tìtì

Gibeah ti Saulu sálọ.

30Gbé ohùn rẹ sókè, ìwọ ọmọbìnrin Galimu!

Dẹ etí sílẹ̀, ìwọ Laiṣa!

Ìwọ òtòṣì Anatoti!

31Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ

Àwọn ènìyàn Gebimu ti fi ara pamọ́.

32Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu

wọn yóò kan sáárá,

ní òkè ọmọbìnrin Sioni

ní òkè Jerusalẹmu.

33Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,

yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára.

Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀

àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.

34Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,

Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.