Размышления 8 – CARS & YCB

Священное Писание

Размышления 8:1-17

1Кто подобен мудрецу?

Кто понимает значение вещей?

Мудрость просвещает лицо человека

и смягчает его суровый вид.

Повинуйся царю

2Я говорю: повинуйся повелению царя, потому что ты поклялся перед Всевышним. 3Не спеши покинуть царя и не отстаивай худого дела, потому что он может сделать всё, что ему угодно. 4Слово царя властно, кто может сказать ему: «Что ты делаешь?»

5Кто повинуется его повелениям, не попадёт в беду,

мудрое сердце знает нужное время и правильное поведение,

6потому что у всякого дела есть своё время и свой устав,

но несчастья человека тяжким бременем лежат на нём.

7Человек не знает будущего,

и кто может сказать ему, что будет?

8Человек не властен удержать ветер8:8 Или: «дух».,

так же как он не властен и над днём своей смерти.

Воин не может получить увольнение во время битвы,

и нечестивый не спасётся своим нечестием.

Одна участь всему

9Всё это увидел я, когда решил постичь разумом всё, что делается под солнцем. Иногда человек властвует над другим ему во вред8:9 Или: «себе самому во вред».. 10Ещё я видел, что хоронили нечестивых, которые когда-то приходили в храм, но позже они были забыты в том городе, где творили зло. Это тоже пустое.

11Когда не скоро выносят приговор за преступление, сердца людей исполняются желанием совершать зло. 12Хотя грешник сто раз совершает грех и долго живёт, всё же я знаю, что будет лучше тем, кто боится Всевышнего и благоговеет перед Ним. 13А грешнику не будет процветания, и дни его, подобно тени, не продлятся долго, потому что он не боится Всевышнего.

14Есть ещё нечто пустое, что случается на земле: праведник получает то, что заслуживает нечестивый, а нечестивый получает то, что заслуживает праведник. И сказал я, что это тоже пустое. 15Итак, я воздаю хвалу веселью, потому что нет ничего лучше для человека под солнцем, как есть, пить и веселиться. И радость будет сопровождать его в трудах во все дни его жизни, которые Всевышний дал ему под солнцем.

16Когда я решил познать мудрость и понаблюдать за трудом человека на земле, из-за которого он не смыкает глаз ни днём ни ночью, 17тогда я увидел всё, что сделал Всевышний. Человек не может постичь того, что происходит под солнцем. Как бы человек ни старался постичь этого, он не сможет найти смысла. Даже если какой-нибудь мудрец скажет, что он-то знает, на самом деле он не постиг этого.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 8:1-17

1Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn?

Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?

Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán

ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

Pa òfin ọba mọ́

2Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run. 3Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn. 4Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

5Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,

àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.

6Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe,

ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.

7Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá,

ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀?

8Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró

nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀.

Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,

bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀;

bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,

bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.

9Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀. 10Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.

11Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. 13Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run.

14Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀. 15Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn.

16Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé. 17Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láìbìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.