Saamu 96 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Saamu 96:1-13

Saamu 96

196.1-13: 1Ki 16.23-33.Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:

Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

2Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀

ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́

3Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè

àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

4Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;

òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ

5Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè

ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run

6Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀

agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

7Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn

Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa

8Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;

ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀

9Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;

ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

10Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”

a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;

ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo

jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun

gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.

12Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀

àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:

nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀

13Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,

nítorí tí ó ń bọ̀ wá,

Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé

yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé

àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.