Saamu 103 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Saamu 103:1-22

Saamu 103

Ti Dafidi.

1Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.

2Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀

3Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́

tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,

4Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú

ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,

5Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn

kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

6Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún

gbogbo àwọn tí a ni lára.

7Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;

8103.8: Jk 5.11.Olúwa ni aláàánú àti olóore,

ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.

9Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo

bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;

10Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa

bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́

bí àìṣedéédéé wa.

11Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn

bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;

14Nítorí tí ó mọ dídá wa,

ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.

15Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko,

ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó;

16Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀,

kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́.

17103.17: Lk 1.50.Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́

Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ

18Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́

àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

19Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run,

ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.

20Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́

21Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo,

ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

22Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní

ibi gbogbo ìjọba rẹ̀.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.