Romu 10 – YCB & NVI

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 10:1-21

1Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi sí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Israẹli ni kí wọ́n le ní ìgbàlà. 210.2-4: Ro 9.31.Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀. 310.3: Ro 1.17.Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run. 410.4: Ga 3.24; Ro 3.22; 7.1-4.Nítorí Kristi ni òpin òfin sí òdodo fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbà á gbọ́.

510.5: Le 18.5; Ne 9.29; El 20.11,13,21; Ro 7.10.Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 610.6: De 30.12-13; Ro 9.30.Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀) 7“tàbí, ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). 810.8: De 30.14.Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù; 910.9: Mt 10.32; Lk 12.8; Ap 16.31.Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. 10Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. 1110.11: Isa 28.16; Ro 9.33.Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” 1210.12: Ro 3.22,29; Ga 3.28; Kl 3.11; Ap 10.36.Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. 13“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”

14Ǹjẹ́ wọn ó ha ti ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o ha sì ti ṣe gbọ́ láìsí oníwàásù? 1510.15: Isa 52.7.Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìhìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”

1610.16: Isa 53.1; Jh 12.38.Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìhìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?” 17Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 1810.18: Sm 19.4; Kl 1.6,23.Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́:

“Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀,

àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.”

1910.19: De 32.21; Ro 11.11,14.Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé,

“Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú.

Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”

2010.20: Isa 65.1; Ro 9.30.Ṣùgbọ́n Isaiah tilẹ̀ láyà, ó wí pé,

“Àwọn tí kò wá mi rí mi;

Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.”

2110.21: Isa 65.2.Ṣùgbọ́n nípa ti Israẹli ni ó wí pé,

“Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi

sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”

Nueva Versión Internacional

Romanos 10:1-21

1Hermanos, el deseo de mi corazón y mi oración a Dios por los israelitas es que lleguen a ser salvos. 2Puedo declarar en favor de ellos que muestran celo por Dios, pero su celo no se basa en el conocimiento. 3No conociendo la justicia que proviene de Dios y procurando establecer la suya propia, no se sometieron a la justicia de Dios. 4De hecho, Cristo es la culminación de la Ley para que todo el que cree sea justificado.

5Así describe Moisés la justicia que se basa en la Ley: «Quien practique estas cosas vivirá por ellas».10:5 Lv 18:5. 6Pero la justicia que se basa en la fe afirma: «No digas en tu corazón: “¿Quién subirá al cielo?”10:6 Dt 30:12. (es decir, para hacer bajar a Cristo), 7o “¿Quién bajará al abismo?”» (es decir, para hacer subir a Cristo de entre los muertos). 8¿Qué afirma entonces? «La palabra está cerca de ti, la tienes en la boca y en el corazón».10:8 Dt 30:14. Esta es la palabra de fe que predicamos: 9que si confiesas con tu boca que Jesús es el Señor y crees en tu corazón que Dios lo levantó de entre los muertos, serás salvo. 10Porque con el corazón se cree para ser justificado, pero con la boca se confiesa para ser salvo. 11Así dice la Escritura: «Todo el que confíe en él no será defraudado».10:11 Is 28:16. 12No hay diferencia entre judíos y los que no son judíos, pues el mismo Señor es Señor de todos y bendice abundantemente a cuantos lo invocan, 13porque «todo el que invoque el nombre del Señor será salvo».10:13 Jl 2:32.

14Ahora bien, ¿cómo invocarán a aquel en quien no han creído? ¿Y cómo creerán en aquel de quien no han oído? ¿Y cómo oirán si no hay quien predique? 15¿Y cómo predicarán sin ser enviados? Así está escrito: «¡Qué hermosos son los pies de los que anuncian las buenas noticias!».10:15 Is 52:7.

16Sin embargo, no todos los israelitas aceptaron las buenas noticias. Isaías dice: «Señor, ¿quién ha creído a nuestro mensaje?».10:16 Is 53:1. 17Así que la fe viene como resultado de oír el mensaje y el mensaje que se oye es la palabra de Cristo.10:17 Cristo. Var. Dios. 18Pero pregunto: ¿Acaso no oyeron? ¡Claro que sí!

«Por toda la tierra se difundió su voz,

¡sus palabras llegan hasta los confines del mundo!».10:18 Sal 19:4.

19Pero insisto: ¿Acaso no entendió Israel? En primer lugar, Moisés dice:

«Yo haré que ustedes sientan envidia de los que no son nación;

voy a irritarlos con una nación insensata».10:19 Dt 32:21.

20Luego Isaías se atreve a decir:

«Dejé que me hallaran los que no me buscaban;

me di a conocer a los que no preguntaban por mí».10:20 Is 65:1.

21En cambio, respecto de Israel, dice:

«Todo el día extendí mis manos

hacia un pueblo desobediente y rebelde».10:21 Is 65:2.