Romu 1 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 1:1-32

Ọ̀rọ̀ ìkíni Paulu sí àwọn àyànfẹ́

11.1: Ap 9.15; 13.2; 1Kọ 1.1; 2Kọ 1.1; Ga 1.15.Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìhìnrere Ọlọ́run, 2ìhìnrere tí ó ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ nínú ìwé Mímọ́. 3Ní ti Ọmọ rẹ̀, ẹni tí a bí láti inú irú-ọmọ Dafidi nípa ti ara, 4ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jesu Kristi Olúwa wa. 51.5: Ap 26.16-18; Ro 15.18; Ga 2.7,9.Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ aposteli gbà, fún ìgbọ́ràn ìgbàgbọ́ láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí orúkọ rẹ̀. 6Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jesu Kristi.

71.7: 1Kọ 1.3; 2Kọ 1.2; Ga 1.3; Ef 1.2; Fp 1.2; Kl 1.2; 1Tẹ 1.2; 2Tẹ 1.2; 1Tm 1.2; 2Tm 1.2; Tt 1.4; Fm 3; 2Jh 3.Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Romu tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́:

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.

Ìfojúsọ́nà Paulu láti bẹ Romu wò

81.8: Ro 16.19.Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé. 9Ọlọ́run ṣá à ni ẹlẹ́rìí mi, ẹni tí èmí ń fi gbogbo ẹ̀mí mi sìn nínú ìhìnrere Ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsimi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi 101.10: Ro 15.23,32; Ap 19.21.nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó ṣí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.

11Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa, 12èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. 131.13: Ro 15.22.Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù.

141.14: 1Kọ 9.16.Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. 15Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìhìnrere Ọlọ́run sí i yín.

161.16: 1Kọ 1.18,24.Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 171.17: Ro 3.21; Ga 3.11; Fp 3.9; Hb 10.38; Hk 2.4.Nítorí nínú ìhìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”

Ìbínú Ọlọ́run sí orílẹ̀ ayé

181.18: Ef 5.6; Kl 3.6.Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 201.20: Sm 19.1-4.Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

211.21: Ef 4.17-18.Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, 231.23: Ap 17.29.wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

24Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. 25Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

26Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. 27Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.

28Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe: 29Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ a fi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́. 30Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, 31aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú: 32Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

King James Version

Romans 1:1-32

1Paul, a servant of Jesus Christ, called to be an apostle, separated unto the gospel of God, 2(Which he had promised afore by his prophets in the holy scriptures,) 3Concerning his Son Jesus Christ our Lord, which was made of the seed of David according to the flesh; 4And declared to be the Son of God with power, according to the spirit of holiness, by the resurrection from the dead: 5By whom we have received grace and apostleship, for obedience to the faith among all nations, for his name: 6Among whom are ye also the called of Jesus Christ: 7To all that be in Rome, beloved of God, called to be saints: Grace to you and peace from God our Father, and the Lord Jesus Christ.

8First, I thank my God through Jesus Christ for you all, that your faith is spoken of throughout the whole world. 9For God is my witness, whom I serve with my spirit in the gospel of his Son, that without ceasing I make mention of you always in my prayers; 10Making request, if by any means now at length I might have a prosperous journey by the will of God to come unto you. 11For I long to see you, that I may impart unto you some spiritual gift, to the end ye may be established; 12That is, that I may be comforted together with you by the mutual faith both of you and me. 13Now I would not have you ignorant, brethren, that oftentimes I purposed to come unto you, (but was let hitherto,) that I might have some fruit among you also, even as among other Gentiles. 14I am debtor both to the Greeks, and to the Barbarians; both to the wise, and to the unwise. 15So, as much as in me is, I am ready to preach the gospel to you that are at Rome also. 16For I am not ashamed of the gospel of Christ: for it is the power of God unto salvation to every one that believeth; to the Jew first, and also to the Greek. 17For therein is the righteousness of God revealed from faith to faith: as it is written, The just shall live by faith.

18For the wrath of God is revealed from heaven against all ungodliness and unrighteousness of men, who hold the truth in unrighteousness; 19Because that which may be known of God is manifest in them; for God hath shewed it unto them. 20For the invisible things of him from the creation of the world are clearly seen, being understood by the things that are made, even his eternal power and Godhead; so that they are without excuse: 21Because that, when they knew God, they glorified him not as God, neither were thankful; but became vain in their imaginations, and their foolish heart was darkened. 22Professing themselves to be wise, they became fools, 23And changed the glory of the uncorruptible God into an image made like to corruptible man, and to birds, and fourfooted beasts, and creeping things.

24Wherefore God also gave them up to uncleanness through the lusts of their own hearts, to dishonour their own bodies between themselves: 25Who changed the truth of God into a lie, and worshipped and served the creature more than the Creator, who is blessed for ever. Amen. 26For this cause God gave them up unto vile affections: for even their women did change the natural use into that which is against nature: 27And likewise also the men, leaving the natural use of the woman, burned in their lust one toward another; men with men working that which is unseemly, and receiving in themselves that recompence of their error which was meet. 28And even as they did not like to retain God in their knowledge, God gave them over to a reprobate mind, to do those things which are not convenient; 29Being filled with all unrighteousness, fornication, wickedness, covetousness, maliciousness; full of envy, murder, debate, deceit, malignity; whisperers, 30Backbiters, haters of God, despiteful, proud, boasters, inventors of evil things, disobedient to parents, 31Without understanding, covenantbreakers, without natural affection, implacable, unmerciful: 32Who knowing the judgment of God, that they which commit such things are worthy of death, not only do the same, but have pleasure in them that do them.