Oniwaasu 5 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 5:1-20

Dídúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run

1Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti ṣe ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.

2Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ,

má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run

Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run

ìwọ sì wà ní ayé,

nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n

3Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìlépa púpọ̀ wà

bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.

4Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ. 5Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ. 6Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ, kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́? 7Asán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Asán ni ọrọ̀ jẹ́

8Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì. 9Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.

10Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,

ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn

pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.

11Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i

náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i

Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé,

kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn?

12Oorun alágbàṣe a máa dùn,

yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,

ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀

kì í jẹ́ kí ó sùn rárá.

13Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn

ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan.

14Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere,

nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin

kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un.

15Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,

bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò

kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀

tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.

16Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá:

Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ

kí wá ni èrè tí ó jẹ

nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?

17Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀,

pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.

18Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí. 19Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí. 20Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.