Oniwaasu 2 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 2:1-26

Ìgbádùn

1Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán. 2“Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” 3Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.

42.4-8: 1Kọ 10.23-27; 2Ki 9.22-27.Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńláńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. 5Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. 6Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. 72.7: 1Ki 4.23.Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. 8Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. 9Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.

10Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́.

N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn.

Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi,

èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.

11Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe

àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní:

gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni

gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn;

ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.

12Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,

àti ìsínwín àti àìgbọ́n

kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe

ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ.

13Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀

gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.

14Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,

nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,

ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀

wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.

15Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,

“Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú

kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”

Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,

“Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”

16Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;

gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.

Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

Asán ni iṣẹ́ ṣíṣe

17Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. 18Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. 19Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú. 20Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn. 21Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnrarẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá. 22Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? 23Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú.

242.24: Su 3.13; 5.18; 9.7; Isa 56.12; Lk 12.19; 1Kọ 15.32.Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. 25Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn? 26Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

傳道書 2:1-26

1我心裡想:「來吧,不如盡情享樂,好好享受!」唉!結果這也是虛空。 2我說:「歡笑只不過是一陣狂妄,享樂又有什麼用!」 3於是,我決意用酒使自己快樂,在體驗愚昧的同時仍然保持理智,直到我明白在短暫的人生歲月中做何事才有益。 4我大動工程,為自己建造房屋,栽種葡萄園, 5開墾花圃園囿,種植各種果樹, 6開鑿池塘,澆灌茂林。 7我買了僕婢,又有生在家中的僕婢,擁有的牛羊遠超過有史以來耶路撒冷的任何人。 8我為自己積聚金銀,搜羅列王和各省的奇珍異寶,得到男女歌優及許多妃嬪——都是世人所想望的。 9這樣,我便財勢日增,享譽盛名,超過耶路撒冷歷來所有的人。然而,我仍然保持智慧。 10凡我眼睛愛看的、心裡渴慕的,我都隨心所欲,盡情享受。我的心從勞碌中得到歡樂,這是我勞碌所得的回報。 11然而,當我回顧雙手辛勤經營的一切成就時,唉,卻發現都是虛空,都是捕風;日光之下的一切都毫無益處。 12於是,我轉念思考什麼是智慧、狂妄和愚昧。其實以後接替君王的人除了重演歷史之外,還能做什麼呢? 13我領悟到智慧勝過愚昧,如同光明勝過黑暗。 14智者高瞻遠矚,愚人卻在黑暗中摸索。但我知道兩者終必有同樣的命運。 15於是,我想:「既然愚人的命運也將是我的命運,我有智慧又怎麼樣呢?我只能說,『這也是虛空。』」 16因為智者和愚人一樣,不過被人記得一時,日後都會被遺忘。兩者都難逃死亡。 17所以,我憎惡生命,因為在日光之下所做的一切都令我愁煩。唉!這一切都是虛空,都是捕風。 18我憎惡自己在日光之下勞碌得來的一切,因為這些必留給後人。 19誰知道那人是智者還是愚人呢?然而,他卻要接管我在日光之下用智慧辛勤經營的產業。這也是虛空。 20因此,我對自己在日光之下一切的勞碌感到絕望。 21一個人用智慧、知識和技能所得來的一切,卻要留給不勞而獲的人享用,這也是虛空,是極大的不幸! 22世人在日光之下勞心勞力,究竟得到什麼呢? 23他們一生充滿痛苦,勞碌中盡是愁煩,即使夜間心裡也不安寧。這也是虛空。 24對人而言,沒有什麼比吃喝並享受勞碌之樂更好,我看這也是出自上帝的手。 25離了上帝,誰還能吃喝享受呢? 26上帝把智慧、知識和喜樂賜給祂喜悅的人,卻讓罪人忙於積攢財富,然後把他們的財富賜給祂喜悅的人。這也是虛空,也是捕風。