Onidajọ 18 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Onidajọ 18:1-31

Àwọn ìran Dani tẹ̀dó sí Laiṣi

1Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba.

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tiwọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 2Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Dani rán àwọn jagunjagun márùn-ún lọ láti Sora àti Eṣtaoli láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínní fínní.”

Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika, níbi tí wọ́n sùn ní òru náà. 3Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e Mika, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, “Tá ni ó mú ọ wa sí ibi? Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín-yìí? Èéṣe tí o fi wà ní ibí?”

4Ó sọ ohun tí Mika ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, “Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀.”

5Wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere.”

6Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Ọlọ́run pàdé.”

7Àwọn ọkùnrin márààrún náà kúrò, wọ́n sì wá sí Laiṣi, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Sidoni, láìsí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Sidoni, wọn kò fi ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀.

8Nígbà tí wọ́n padà sí Sora àti Eṣtaoli, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?”

9Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ síbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà. 10Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ yóò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.”

11Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dani, jáde lọ láti Sora àti Eṣtaoli ní mímú ra láti jagun. 12Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí. 13Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika.

14Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Laiṣi wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní ẹ̀wù efodu, àwọn yòókù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.” 15Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà, sí ilé Mika, wọ́n sì béèrè àlàáfíà rẹ̀. 16Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará Dani náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi. 17Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà.

18Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Mika lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?”

19Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?” 20Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ. 21Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.

22Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Mika, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbègbè Mika kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá. 23Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dani yípadà wọ́n sì bi Mika pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”

24Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ”

25Àwọn ọkùnrin Dani náà dáhùn pé, “Má ṣe bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbìínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.” 26Àwọn ọkùnrin Dani náà sì bá ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí Mika rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀.

27Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Mika ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Laiṣi, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run. 28Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Sidoni, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bàá a Beti-Rehobu.

Àwọn ará Dani sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀. 29Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dani, ẹni tí wọ́n bí fún Israẹli: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Laiṣi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí. 30Àwọn ọmọ Dani sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jonatani ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn. 31Wọ́n tẹ̀síwájú láti lo àwọn ère tí Mika ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣilo.

New International Version

Judges 18:1-31

The Danites Settle in Laish

1In those days Israel had no king.

And in those days the tribe of the Danites was seeking a place of their own where they might settle, because they had not yet come into an inheritance among the tribes of Israel. 2So the Danites sent five of their leading men from Zorah and Eshtaol to spy out the land and explore it. These men represented all the Danites. They told them, “Go, explore the land.”

So they entered the hill country of Ephraim and came to the house of Micah, where they spent the night. 3When they were near Micah’s house, they recognized the voice of the young Levite; so they turned in there and asked him, “Who brought you here? What are you doing in this place? Why are you here?”

4He told them what Micah had done for him, and said, “He has hired me and I am his priest.”

5Then they said to him, “Please inquire of God to learn whether our journey will be successful.”

6The priest answered them, “Go in peace. Your journey has the Lord’s approval.”

7So the five men left and came to Laish, where they saw that the people were living in safety, like the Sidonians, at peace and secure. And since their land lacked nothing, they were prosperous.18:7 The meaning of the Hebrew for this clause is uncertain. Also, they lived a long way from the Sidonians and had no relationship with anyone else.18:7 Hebrew; some Septuagint manuscripts with the Arameans

8When they returned to Zorah and Eshtaol, their fellow Danites asked them, “How did you find things?”

9They answered, “Come on, let’s attack them! We have seen the land, and it is very good. Aren’t you going to do something? Don’t hesitate to go there and take it over. 10When you get there, you will find an unsuspecting people and a spacious land that God has put into your hands, a land that lacks nothing whatever.”

11Then six hundred men of the Danites, armed for battle, set out from Zorah and Eshtaol. 12On their way they set up camp near Kiriath Jearim in Judah. This is why the place west of Kiriath Jearim is called Mahaneh Dan18:12 Mahaneh Dan means Dan’s camp. to this day. 13From there they went on to the hill country of Ephraim and came to Micah’s house.

14Then the five men who had spied out the land of Laish said to their fellow Danites, “Do you know that one of these houses has an ephod, some household gods and an image overlaid with silver? Now you know what to do.” 15So they turned in there and went to the house of the young Levite at Micah’s place and greeted him. 16The six hundred Danites, armed for battle, stood at the entrance of the gate. 17The five men who had spied out the land went inside and took the idol, the ephod and the household gods while the priest and the six hundred armed men stood at the entrance of the gate.

18When the five men went into Micah’s house and took the idol, the ephod and the household gods, the priest said to them, “What are you doing?”

19They answered him, “Be quiet! Don’t say a word. Come with us, and be our father and priest. Isn’t it better that you serve a tribe and clan in Israel as priest rather than just one man’s household?” 20The priest was very pleased. He took the ephod, the household gods and the idol and went along with the people. 21Putting their little children, their livestock and their possessions in front of them, they turned away and left.

22When they had gone some distance from Micah’s house, the men who lived near Micah were called together and overtook the Danites. 23As they shouted after them, the Danites turned and said to Micah, “What’s the matter with you that you called out your men to fight?”

24He replied, “You took the gods I made, and my priest, and went away. What else do I have? How can you ask, ‘What’s the matter with you?’ ”

25The Danites answered, “Don’t argue with us, or some of the men may get angry and attack you, and you and your family will lose your lives.” 26So the Danites went their way, and Micah, seeing that they were too strong for him, turned around and went back home.

27Then they took what Micah had made, and his priest, and went on to Laish, against a people at peace and secure. They attacked them with the sword and burned down their city. 28There was no one to rescue them because they lived a long way from Sidon and had no relationship with anyone else. The city was in a valley near Beth Rehob.

The Danites rebuilt the city and settled there. 29They named it Dan after their ancestor Dan, who was born to Israel—though the city used to be called Laish. 30There the Danites set up for themselves the idol, and Jonathan son of Gershom, the son of Moses,18:30 Many Hebrew manuscripts, some Septuagint manuscripts and Vulgate; many other Hebrew manuscripts and some other Septuagint manuscripts Manasseh and his sons were priests for the tribe of Dan until the time of the captivity of the land. 31They continued to use the idol Micah had made, all the time the house of God was in Shiloh.