Onidajọ 1 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Onidajọ 1:1-36

Orílẹ̀-èdè Israẹli bá àwọn ará Kenaani tókù jagun

1Lẹ́yìn ikú Joṣua, ni orílẹ̀-èdè Israẹli béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé “Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kenaani jagun fún wa?”

2Olúwa sì dáhùn pé, “Juda ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”

3Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Juda béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Simeoni arákùnrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kenaani jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ogun Simeoni sì bá àwọn ọmọ-ogun Juda lọ.

4Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Juda sì kọlu wọ́n, Olúwa sì fi àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Beseki. 5Ní Beseki ni wọ́n ti rí Adoni-Beseki, wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kenaani àti Peresi. 6Ọba Adoni-Beseki sá àsálà, ṣùgbọ́n ogun Israẹli lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀.

7Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀.

8Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà.

9Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun. 101.10: Jo 15.13-19.1.10-15: Jo 15.14-19.Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai. 11Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).

12Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” 13Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.

14Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

15Aksa sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.

16Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.

17Ó sì ṣe, àwọn ológun Juda tẹ̀lé àwọn ológun Simeoni arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé Sefati jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátápátá, ní báyìí àwa yóò pe ìlú náà ní Horma (Horma èyí tí ń jẹ́ ìparun). 18Àwọn ogun Juda sì ṣẹ́gun Gasa àti àwọn agbègbè rẹ̀, Aṣkeloni àti Ekroni pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká.

19Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Juda, wọ́n gba ilẹ̀ òkè, ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin. 20Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta. 21Àwọn ẹ̀yà Benjamini ni wọn kò le lé àwọn Jebusi tí wọ́n ń gbé Jerusalẹmu, nítorí náà wọ́n ń gbé àárín àwọn Israẹli títí di òní.

22Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn. 23Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). 24Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.” 25Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si. 26Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lusi, èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.

271.27,28: Jo 17.11-13.Ṣùgbọ́n Manase kò lé àwọn ará Beti-Ṣeani àti ìlú rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jáde, tàbí àwọn ará Taanaki àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Dori àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Ibleamu àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Megido àti àwọn ìgbèríko tí ó yí i ká, torí pé àwọn ará Kenaani ti pinnu láti máa gbé ìlú náà. 28Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kenaani sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. 291.29: Jo 16.10.Efraimu náà kò lé àwọn ará Kenaani tí ó ń gbé Geseri jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kenaani sì ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà Efraimu. 30Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni. 31Bẹ́ẹ̀ ni Aṣeri kò lé àwọn tí ń gbé ní Akko tàbí ní Sidoni tàbí ní Ahlabu tàbí ní Aksibu tàbí ní Helba tàbí ní Afiki tàbí ní Rehobu. 32Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà. 33Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá. 34Àwọn ará Amori fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dani dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. 35Àwọn ará Amori ti pinnu láti dúró lórí òkè Heresi àti òkè Aijaloni àti ti Ṣaalbimu, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu di alágbára wọ́n borí Amori wọ́n sì mú wọn sìn. 36Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Akrabbimu kọjá lọ sí Sela àti síwájú sí i.

New International Reader’s Version

Judges 1:1-36

The Israelites Fight Against the Remaining Canaanites

1Joshua died. After that, the Israelites spoke to the Lord. They asked him, “Who of us will go up first and fight against the Canaanites?”

2The Lord answered, “The tribe of Judah will go up. I have handed the land over to them.”

3Then the men of Judah spoke to their fellow Israelites, the men of Simeon. They said, “Come up with us. Come into the territory Joshua gave us. Help us fight against the Canaanites. Then we’ll go with you into your territory.” So the men of Simeon went with them.

4When the men of Judah attacked, the Lord helped them. He handed the Canaanites and Perizzites over to them. They struck down 10,000 men at Bezek. 5The men of Judah found Adoni-Bezek there. They fought against him. They struck down the Canaanites and Perizzites. 6But Adoni-Bezek ran away. The men of Judah chased him and caught him. Then they cut off his thumbs and big toes.

7Adoni-Bezek said, “I cut off the thumbs and big toes of 70 kings. I made them pick up scraps under my table. Now God has paid me back for what I did to them.” The men of Judah brought Adoni-Bezek to Jerusalem. That’s where he died.

8The men of Judah attacked Jerusalem and captured it. They set the city on fire. They killed its people with their swords.

9After that, the men of Judah went down to fight against some Canaanites. Those Canaanites were living in the central hill country. They also fought against those living in the Negev Desert and the western hills. 10Then the men of Judah marched out against the Canaanites living in Hebron. Hebron used to be called Kiriath Arba. The men of Judah won the battle over Sheshai, Ahiman and Talmai. 11From Hebron they marched out against the people living in Debir. It used to be called Kiriath Sepher.

12Caleb said, “I will give my daughter Aksah to be married. I’ll give her to the man who attacks and captures Kiriath Sepher.” 13Othniel captured it. So Caleb gave his daughter Aksah to him to be his wife. Othniel was the son of Kenaz. He was Caleb’s younger brother.

14One day Aksah came to Othniel. She begged him to ask her father for a field. When she got off her donkey, Caleb asked her, “What can I do for you?”

15She replied, “Do me a special favor. You have given me some land in the Negev Desert. Give me springs of water also.” So Caleb gave her the upper and lower springs.

16Moses’ father-in-law was a Kenite. His family went up from Jericho. Jericho was also known as the City of Palm Trees. His family went up with the people of Judah to the Desert of Judah. They went there to live among its people. Those people were living in the Negev Desert near Arad.

17The men of Judah marched out with their fellow Israelites, the men of Simeon. They attacked the people of Canaan living in Zephath. They set the city apart to the Lord in a special way to be destroyed. That’s why the city was called Hormah. 18The men of Judah captured Gaza, Ashkelon and Ekron. They also captured the territory around each of those cities.

19The Lord was with the men of Judah. They took over the central hill country. But they weren’t able to drive the people out of the plains. That’s because those people used chariots that had some iron parts. 20Moses had promised to give Hebron to Caleb. So Hebron was given to Caleb. He drove the three sons of Anak out of it. 21But the people of Benjamin did not drive out the Jebusites living in Jerusalem. So to this day they live there with the people of Benjamin.

22The tribes of Joseph attacked Bethel. The Lord was with them. 23They sent men to Bethel to check it out. It used to be called Luz. 24Those who were sent saw a man coming out of the city. They said to him, “Show us how to get into the city. If you do, we’ll see that you are treated well.” 25So he showed them how to get in. The men of Joseph killed the people in the city with their swords. But they spared the man from Bethel. They also spared his whole family. 26Then he went to the land of the Hittites. He built a city there. He called it Luz. That’s still its name to this day.

27But the tribe of Manasseh didn’t drive out the people of Beth Shan. They didn’t drive out the people of Taanach, Dor, Ibleam and Megiddo. And they didn’t drive out the people of the settlements that are around those cities either. That’s because the Canaanites had made up their minds to continue living in that land. 28Later, Israel became stronger. Then they forced the Canaanites to work hard for them. But Israel never drove them out completely. 29The tribe of Ephraim didn’t drive out the Canaanites living in Gezer. So the Canaanites continued to live there among them. 30The tribe of Zebulun didn’t drive out the Canaanites living in Kitron and Nahalol. So these Canaanites lived among them. But the people of Zebulun forced the Canaanites to work hard for them. 31The tribe of Asher didn’t drive out the people living in Akko and Sidon. They didn’t drive out the people of Ahlab, Akzib, Helbah, Aphek and Rehob. 32So the people of Asher lived among the Canaanites who were in the land. 33The tribe of Naphtali didn’t drive out the people living in Beth Shemesh and Beth Anath. So the people of Naphtali lived among the Canaanites who were in the land. The people of Beth Shemesh and Beth Anath were forced to work hard for them. 34The Amorites made the people of Dan stay in the central hill country. They didn’t let them come down into the plain. 35The Amorites made up their minds to stay in Mount Heres. They also stayed in Aijalon and Shaalbim. But the power of the tribes of Joseph grew. Then the Amorites were forced to work hard for them. 36The border of the Amorites started at Scorpion Pass. It went to Sela and even past it.