Numeri 36 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 36:1-13

Ogún ọmọbìnrin Ṣelofehadi

1Àwọn olórí ìdílé Gileadi, ọmọkùnrin Makiri ọmọ Manase tí ó wá láti ara ìdílé ìran Josẹfu wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mose àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Israẹli. 236.2: Nu 27.7.Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Ṣelofehadi arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. 3Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Israẹli mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbà á kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa. 4Nígbà tí ọdún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ baba ńlá wọn.”

5Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mose pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìran Josẹfu ń sọ tọ̀nà. 6Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi: Wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn. 7Kò sí ogún kan ní Israẹli tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Israẹli ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn pamọ́. 8Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Israẹli lè ní ìpín nínú ogún baba wọn. 9Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Israẹli gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”

10Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 11Nítorí pé a gbé Mahila, Tirsa, Hogla, Milka, àti Noa, àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn. 12Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìran Manase, ọmọ Josẹfu ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn.

13Wọ̀nyí ni àṣẹ àti ìdájọ́ tí Olúwa ti ipasẹ̀ Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani létí Jeriko.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

民数记 36:1-13

女子继承产业的律例

1基列约瑟之子玛拿西的孙子,玛吉的儿子。他宗族中的各族长来见摩西和做以色列人首领的各族长,说: 2“耶和华曾吩咐我主用抽签的方式把土地分给以色列人,还吩咐我主将我们兄弟西罗非哈的产业分给他的女儿们。 3但如果她们嫁给其他支派的人,从我们祖业中分给她们的产业就会归入她们夫家的支派。这样的话,我们抽签分到的土地就会减少。 4到了以色列人的禧年,这些女儿的产业就会归给她们丈夫的支派,我们支派的祖业就会失去她们那份产业。”

5摩西照耶和华的话吩咐以色列人说:“约瑟支派的人说的对。 6关于西罗非哈的女儿们,耶和华说她们可以自由嫁人,但必须嫁给本支派的人。 7以色列人的产业不可从一个支派转到另一个支派,各支派必须守住本支派的祖业。 8继承了产业的女子必须嫁给本支派的人,以便以色列人都能守住自己的祖业。 9以色列人的产业不可从一个支派转到另一个支派,各支派必须守住本支派的产业。”

10于是,西罗非哈的女儿们遵行了耶和华对摩西的吩咐。 11玛拉得撒曷拉密迦挪阿都嫁给了她们叔伯的儿子, 12约瑟之子玛拿西支派的人。这样,她们的产业仍留在本支派中。

13以上是在耶利哥对面、约旦河边的摩押平原,耶和华借摩西颁布给以色列人的命令和律例。