Numeri 3 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 3:1-51

Àwọn ẹ̀yà Lefi

1Ìwọ̀nyí ni ìdílé Aaroni àti Mose ní ìgbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai.

23.2: Nu 26.60.Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí, Nadabu ni àkọ́bí, Abihu, Eleasari àti Itamari. 3Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni ni ìwọ̀nyí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 4Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sinai, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Eleasari àti Itamari ló ṣiṣẹ́ àlùfáà nígbà ayé Aaroni baba wọn.

53.5-13: Nu 8.6-26.3.5-8: Nu 1.50-53; 3.21-37; 4.1-33; 8.19.Olúwa sọ fún Mose pé, 6“Kó ẹ̀yà Lefi wá, kí o sì fà wọ́n fún Aaroni àlùfáà láti máa ràn án lọ́wọ́. 7Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní àgọ́ ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́. 8Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Israẹli nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́. 9Fi ẹ̀yà Lefi jì Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Aaroni nínú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. 10Kí o sì yan Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.”

113.11-13: Nu 3.45; 8.18.Olúwa tún sọ fún Mose pé, 12“Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi, 13nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

Kíka àwọn ọmọ Lefi

14Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose ní aginjù Sinai pé, 153.15-34: Nu 4.34-49.“Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè” 16Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

173.17-20: Ek 6.16,22.Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

18Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:

Libni àti Ṣimei.

19Àwọn ìdílé Kohati ni:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

20Àwọn ìdílé Merari ni:

Mahili àti Muṣi.

Wọ̀nyí ni ìdílé Lefi gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

21Ti Gerṣoni ni ìdílé Libni àti Ṣimei; àwọn ni ìdílé Gerṣoni.

22Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500).

23Àwọn ìdílé Gerṣoni yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀-oòrùn lẹ́yìn àgọ́.

24Olórí àwọn ìdílé Gerṣoni ni Eliasafu ọmọ Láélì.

25Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gerṣoni nínú àgọ́ ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

27Ti Kohati ní ìdílé Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli, wọ̀nyí ni ìran Kohati.

28Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rin ó-lé-ẹgbẹ̀ta (8,600),

tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́.

29Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.

30Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli.

31Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

32Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.

33Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari.

34Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).

35Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili.

Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.

36Àwọn ìran Merari ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn; 37Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.

38Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀-oòrùn níwájú àgọ́ ìpàdé.

Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli.

Àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á.

39Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Lefi tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá (22,000).

40Olúwa sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn. 41Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.”

42Mose sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un. 43Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó-dínméje (22,273).

44Olúwa tún sọ fún Mose pé, 453.45: Nu 3.11-13; 8.18.Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi. Èmi ni Olúwa. 46Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Israẹli tó ju iye àwọn ọmọ Lefi lọ, 47ìwọ yóò gba ṣékélì márùn-ún (5) lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gera. 48Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli tó lé yìí, ni kí o kó fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀.

49Nígbà náà ni Mose gba owó ìràpadà àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi ti ra àwọn yòókù padà. 50Mose sì gba egbèje ṣékélì ó dín márùn-dínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli. 51Mose sì kó owó ìràpadà yìí fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

New Amharic Standard Version

ዘኍል 3:1-51

ሌዋውያን

1እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን በሲና ተራራ ላይ ባነጋገረው ጊዜ የአሮንና የሙሴ ትውልድ ይህ ነበር፤ 2የአሮን ልጆች የበኵሩ ስም ናዳብ፣ የሌሎቹም አብዩድ አልዓዛርና ኢታምር ይባላል። 3እርሱ ለክህነት አገልግሎት የለያቸው፣ ካህናት ለመሆን የተቀቡት የአሮን ወንድ ልጆች ስም ይህ ነው፤ 4ናዳብና አብዩድ ግን በሲና ምድረ በዳ ባልተፈቀደ እሳት ለእግዚአብሔር (ያህዌ) መሥዋዕት ባቀረቡ ጊዜ እዚያው እፊቱ ወድቀው ሞቱ። ወንዶች ልጆች ስላልነበሯቸውም አልዓዛርና ኢታምር ብቻ አባታቸው አሮን በሕይወት በነበረበት ዘመን በክህነት ያገለግሉ ነበር።

5እግዚአብሔርም (ያህዌ) ሙሴን እንዲህ አለው፤ 6“የሌዊን ነገድ አምጥተህ ካህኑን አሮንን በአገልግሎቱ እንዲረዱት ከፊቱ አቁማቸው፤ 7በመገናኛው ድንኳን የማደሪያውን አገልግሎት በመፈጸም ለእርሱና ለማኅበረ ሰቡ ሁሉ የሚያስፈልጉትን ተግባሮች ያከናውኑ፤ 8የማደሪያውን ሥራ በመሥራትና የእስራኤላውያንን ግዴታ በመወጣት የመገናኛውን ድንኳን ሁሉ ይጠብቁ። 9ሌዋውያኑን ለአሮንና ለልጆቹ ስጥ፤ እነርሱም ከእስራኤላውያን ተለይተው ለእርሱ3፥9 ብዙ የማሶሬቲክ ቅጆች ከዚህ ጋር ይስማማሉ፤ ጥቂት የማሶሬቲክ፣ የኦሪተ ሳምራውያንና የሰባ ሊቃናት ቅጆች ግን ለእኔ ይላሉ። ፈጽመው የተሰጡ ናቸው። 10አሮንንና ልጆቹን ሹማቸው፤ እነርሱም ክህነታቸውን ይጠብቁ፤ ሌላ ሰው ማደሪያውን ቢቀርብ ግን ይገደል።”

11እግዚአብሔርም (ያህዌ) ሙሴን እንዲህ አለው፤ 12“እነሆ፤ በኵር ሆኖ በሚወለደው ሁሉ ምትክ ሌዋውያኑን ከእስራኤላውያን ወስጃለሁ፤ ስለዚህ ሌዋውያን የእኔ ናቸው፤ 13በኵር የሆነ ሁሉ የእኔ ነውና። በግብፅ ምድር በኵር የሆነውን ሁሉ በመታሁ ዕለት ከሰውም ሆነ ከእንስሳ ማናቸውንም የእስራኤልን በኵር ለራሴ ለይቻለሁ፤ የእኔ ይሁን። እኔ እግዚአብሔር (ያህዌ) ነኝ።”

14እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን በሲና ምድረ በዳ፣ 15“ሌዋውያንን በየቤታቸውና በየጐሣቸው ቍጠር፤ የምትቈጥረውም አንድ ወርና ከዚያ በላይ የሆነውን ወንድ ሁሉ ነው” አለው። 16ስለዚህ ሙሴ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ቃል በታዘዘው መሠረት እነዚህን ቈጠራቸው።

17የሌዊ ልጆች ስም

ጌድሶን፣ ቀዓትና ሜራሪ ነው።

18የጌድሶን ልጆች ጐሣ ስም

ሎቢኒና ሰሜኢ ነው።

19የቀዓት ጐሣዎች፤

እንበረም፣ ይስዓር፣ ኬብሮን፣ ዑዝኤል።

20የሜራሪ ጐሣዎች፤

ሞሖሊና ሙሲ።

እንግዲህ የሌዋውያን ጐሣዎች በየቤተ ሰባቸው ሲቈጠሩ እነዚህ ናቸው።

21የሎቤናና የሰሜአ ጐሣዎች ከጌርሶን ወገን ናቸው፤ እነዚህ የጌርሶን ጐሣዎች ነበሩ።

22አንድ ወርና ከዚያ በላይ ሆኗቸው የተቈጠሩት ወንዶች በሙሉ ብዛታቸው ሰባት ሺሕ አምስት መቶ ነበር።

23የጌርሶን ጐሣዎች በምዕራብ በኩል ከማደሪያው ድንኳን ጀርባ ይሰፍራሉ።

24የጌርሶን ጐሣዎች ቤተ ሰቦች አለቃ የዳኤል ልጅ ኤሊሳፍ ይሆናል።

25የጌድሶናውያን ኀላፊነት በመገናኛው ድንኳን ማደሪያውንና ድንኳኑን፣ መደረቢያዎቹን እንዲሁም በመገናኛው ድንኳን ደጃፍ ላይ ያለውን መጋረጃ፣ 26የአደባባዩን መጋረጃዎች፣ ማደሪያ ድንኳኑንና መሠዊያውን የሚጋርደውን የአደባባዩን መግቢያ መጋረጃ፣ ገመዶቹንና ከነዚሁ ጋር ተያይዞ አገልግሎት የሚሰጠውን ሁሉ መጠበቅ ይሆናል።

27የእንበረማውያን፣ የይሰዓራውያን፣ የኬብሮናውያንና የዑዝኤላውያን ጐሣዎች ከቀዓት ወገን ናቸው፤ እነዚህ የቀዓት ጐሣዎች ነበሩ።

28አንድ ወርና ከዚያ በላይ ሆኗቸው የተቈጠሩት ወንዶች በሙሉ ብዛታቸው ስምንት ሺሕ ስድስት መቶ3፥28 የዕብራይስጡ ትርጕም ከዚህ ጋር ይስማማል አንዳንድ የሰባ ሊቃናት ቅጆች ግን ስምንት ሺሕ ሦስት መቶ ይላሉ። ሲሆን፣ ቀዓታውያንም መቅደሱን የመጠበቅ ኀላፊነት ነበራቸው።

29የቀዓት ጐሣዎች ከማደሪያው ድንኳን በደቡብ በኩል ይሰፍራሉ።

30የቀዓት ጐሣዎች ቤተ ሰቦች አለቃ የዑዝኤል ልጅ ኤሊሳፈን ይሆናል።

31እነርሱም ታቦቱን፣ ጠረጴዛውን፣ መቅረዙን፣ መሠዊያዎቹን፣ ለመቅደሱ አገልግሎት የሚውሉትን ዕቃዎች፣ መጋረጃዎችንና ከነዚህ ጋር ተያይዞ አገልግሎት የሚሰጠውን ሁሉ ይጠብቃሉ።

32ዋናው የሌዋውያን አለቃ የካህኑ የአሮን ልጅ አልዓዛር ነው፤ እርሱም መቅደሱን ለመጠበቅ ኀላፊ በሆኑት ላይ ተሹሞ ነበር።

33የሞሖላውያንና የሙሳያውያን ጐሣዎች ከሜራሪ ወገን ናቸው፤ እነዚህም የሜራሪ ጐሣዎች ነበሩ።

34አንድ ወርና ከዚያ በላይ ሆኗቸው የተቈጠሩት ወንዶች ሁሉ ብዛታቸው ስድስት ሺሕ ሁለት መቶ ነበር።

35የሜራሪም ጐሣዎች ቤተ ሰቦች አለቃ የአቢካኢል ልጅ ሱሪኤል ይሆናል፤ የሜራሪም ጐሣዎች ከማደሪያው ድንኳን በሰሜን በኩል ይሰፍራሉ።

36ሜራሪያውያንም የማደሪያውን ድንኳን ሳንቃዎች፣ መወርወሪያዎች፣ ምሰሶዎች፣ ምሰሶዎቹ የሚቆሙባቸውን እግሮች፣ የማደሪያ ዕቃዎችን ሁሉና ከነዚሁ ጋር ተያይዞ አገልግሎት የሚሰጠውን ሁሉ ለመጠበቅ ተሹመው ነበር። 37እንዲሁም የአደባባዩን ዙሪያ ምሰሶዎች ከነመቆሚያ እግሮቻቸው፣ ከነካስማቸውና ከነገመዶቻቸው ይጠብቃሉ።

38ሙሴ፣ አሮንና ልጆቹ ከማደሪያው ድንኳን በምሥራቅ በኩል በፀሓይ መውጫ ከመገናኛው ድንኳን ፊት ለፊት ይሰፍራሉ፤ እነርሱም እስራኤላውያንን ወክለው ማደሪያ ድንኳኑን ለመጠበቅ ኀላፊዎች ይሆናሉ፤ ወደ ማደሪያው ድንኳን የሚቀርብ ማንኛውም ሌላ ሰው ግን ይገደል።

39አንድ ወርና ከዚያ በላይ ሆኗቸው፣ ሙሴና አሮን በእግዚአብሔር ትእዛዝ በየጐሣቸው የቈጠሯቸው የሌዋውያን ወንዶች ልጆች ጠቅላላ ብዛት ሃያ ሁለት ሺሕ ነበር።

40እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን እንዲህ አለው፤ “በኵር ሆነው የተወለዱትን፣ አንድ ወርና ከዚያ በላይ የሆናቸውን እስራኤላውያን ወንዶች ሁሉ ቍጠር፤ ዝርዝራቸውንም ያዝ። 41በኵር በሆኑት በእስራኤላውያን ልጆች ሁሉ ምትክ ሌዋውያንን እንዲሁም በኵር በሆኑት በእስራኤላውያን ከብቶች ሁሉ ምትክ የሌዋውያንን ከብቶች ለእኔ አድርጋቸው፤ እኔ እግዚአብሔር (ያህዌ) ነኝ።”

42ስለዚህ ሙሴ እግዚአብሔር ባዘዘው መሠረት የእስራኤላውያንን በኵር ሁሉ ቈጠረ፤ 43አንድ ወርና ከዚያ በላይ ሆኗቸው በየስማቸው የተመዘገቡት ወንድ በኵሮች ሁሉ ብዛታቸው ሃያ ሁለት ሺሕ ሁለት መቶ ሰባ ሦስት ነበር።

44ደግሞም እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን እንዲህ አለው፤ 45“በእስራኤላውያን በኵሮች ምትክ ሌዋውያኑን፣ በከብቶቻቸውም ምትክ የሌዋውያኑን ከብቶች ውሰድ፤ ሌዋውያኑም የእኔ ይሁኑ፤ እኔ እግዚአብሔር (ያህዌ) ነኝ። 46ቍጥራቸው ከሌዋውያን ቍጥር በሁለት መቶ ሰባ ሦስት በልጦ የተገኘውን እስራኤላውያን በኵሮች ለመዋጀት፣ 47ለእያንዳንዱ በኵር ክብደቱ ባለ ሃያ አቦሊ በሆነው በቤተ መቅደሱ ሰቅል3፥47 አምሳ አምስት ግራም ያህል ነው። ሚዛን ልክ አምስት አምስት ሰቅል ተቀበል፤ 48የተረፉትንም እስራኤላውያን ለመዋጀት ገንዘቡን ለአሮንና ለልጆቹ ስጥ።”

49ስለዚህ ሙሴ በሌዋውያኑ ተዋጅተው ቍጥራቸው ትርፍ ከሆነው በኵሮች ላይ የመዋጃውን ገንዘብ ተቀበለ፤ 50ከእስራኤላውያን በኵሮች ላይ በቤተ መቅደሱ ሰቅል ልክ አንድ ሺሕ ሦስት መቶ ስድሳ አምስት ሰቅል3፥50 ዐሥራ አምስት ኪሎ ግራም ተኩል ያህል ነው። ሰበሰበ። 51ሙሴም በእግዚአብሔር (ያህዌ) ቃል በታዘዘው መሠረት የመዋጃውን ገንዘብ ለአሮንና ለልጆቹ ሰጣቸው።