Matiu 2 – YCB & HHH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 2:1-23

Ìbẹ̀wò àwọn amòye

12.1: Lk 2.4-7; 1.5.Lẹ́yìn ìgbà tí a bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, ni àkókò ọba Herodu, àwọn amòye ti ìlà-oòrùn wá sí Jerusalẹmu. 22.2: Jr 23.5; Sk 9.9; Mk 15.2; Jh 1.49; Nu 24.17.Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrùn, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”

3Nígbà tí ọba Herodu sì gbọ́ èyí, ìdààmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerusalẹmu pẹ̀lú rẹ̀ 4Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kristi? 52.5: Jh 7.42.Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹtilẹhẹmu ti Judea, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé:

62.6: Mik 5.2.“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judea,

ìwọ kò kéré jù láàrín àwọn ọmọ-aládé Juda;

nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde,

Ẹni ti yóò ṣe ìtọ́jú Israẹli, àwọn ènìyàn mi.’ ”

7Nígbà náà ni Herodu ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀. 8Ó sì rán wọn lọ sí Bẹtilẹhẹmu, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínní fínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”

9Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà. 10Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn. 112.11: Mt 1.18; 12.46.Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá. 122.12: Mt 2.22; Ap 10.22; Hb 11.7.Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Herodu lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn.

A gbé Jesu sálọ sì Ejibiti

13Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.”

14Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, 152.15: Ho 11.1.ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”

16Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà. 17Nígbà náà ni èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wá ṣẹ pé:

182.18: Jr 31.15.“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,

ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá,

Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀.

Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀

nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

Ìpadà sí Nasareti

192.19: Mt 1.20; 2.13.Lẹ́yìn ikú Herodu, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu lójú àlá ní Ejibiti 20Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí ń wá ẹ̀mí ọmọ ọwọ́ náà láti pa ti kú.”

21Nítorí náà, o sì dìde, ó gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Israẹli. 22Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Akelausi ni ó ń jẹ ọba ní Judea ní ipò Herodu baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Galili lọ, 232.23: Lk 1.26; Mk 1.24.ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Nasareti. Nígbà náà ni èyí tí a sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ: “A ó pè é ní ará Nasareti.”

Habrit Hakhadasha/Haderekh

הבשורה על-פי מתי 2:1-23

1ישוע נולד בעיר בית־לחם שבאזור יהודה, בימי המלך הורדוס. זמן קצר לאחר לידתו, הופיעו בירושלים מספר חוזי־כוכבים שבאו מארץ רחוקה במזרח, ושאלו: 2”היכן התינוק שנועד להיות מלך היהודים? ראינו את כוכבו במזרח ובאנו להשתחוות לו.“

3הורדוס נבהל מאוד משאלתם, וכמוהו נבהלו כל אנשי ירושלים. 4הוא כינס את מנהיגי היהודים ושאל אותם: ”האם אמרו לנו הנביאים היכן ייוולד המשיח?“

5ענו לו: ”כן, בבית לחם. הרי מיכה הנביא אמר:2‏.5 ב 5 מיכה ה 1 6’ואתה, בית־לחם בארץ יהודה, אינך צעיר באלופי יהודה, כי ממך יצא מושל אשר ירעה את־עמי ישראל‘. “

7הורדוס הזמין את חוזי־הכוכבים לפגישה סודית, ושאל אותם מתי בדיוק ראו לראשונה את הכוכב. 8לאחר מכן אמר להם: ”לכו לבית־לחם וחפשו את הילד. כשתמצאו אותו, שובו אלי והודיעו לי זאת, כדי שאוכל גם אני ללכת להשתחוות לו.“

9לאחר הפגישה עם המלך יצאו חוזי־הכוכבים לדרך, ולפתע הכוכב שראו במזרח הופיע לנגד עיניהם. הם הלכו בעקבות הכוכב עד שנעמד בדיוק מעל המקום שבו היה התינוק. 10הם שמחו מאוד.

11כשנכנסו חוזי־הכוכבים אל הבית שבו היה התינוק ומרים אמו, נפלו לפניו, השתחוו לו, ולאחר מכן פתחו את חבילותיהם ונתנו לו מתנות: זהב, לבונה ומור.

12בינתיים הזהיר אותם אלוהים בחלום שלא לחזור אל הורדוס, ומשום כך שבו חוזי־הכוכבים לארצם בדרך אחרת.

13לאחר שעזבו, נגלה מלאך ה׳ ליוסף בחלום ואמר: ”קום, ברח למצרים עם התינוק ועם אמו, והישאר שם עד שאומר לך לחזור, כי הורדוס רוצה להרוג את הילד.“ 14באותו לילה יצא יוסף עם מרים ועם הילד למצרים, 15ונשאר אתם שם עד מותו של הורדוס. כך התקיימה הנבואה:2‏.15 ב 15 הושע יא 1 ”וממצרים קראתי לבני.“

16כשהורדוס הבין שחוזי־הכוכבים התחמקו ממנו, הוא מאוד כעס. הוא שלח חיילים לבית־לחם וציווה עליהם להרוג כל ילד זכר עד גיל שנתיים (כי החוזים סיפרו לו שראו את הכוכב כשנתיים קודם לכן), בבית לחם עצמה ובכל כפרי הסביבה. 17מעשה אכזרי זה של הורדוס קיים את הנבואה של ירמיהו:2‏.17 ב 17 ירמיהו לא 15

18”קול ברמה נשמע, נהי בכי תמרורים,

רחל מבכה על בניה,

מאנה להינחם על בניה כי איננו.“

19לאחר מותו של הורדוס נגלה מלאך ה׳ בחלום ליוסף במצרים, ואמר לו: 20”קום, קח את התינוק ואת אמו לישראל, כי אלה שרצו להרוג את הילד כבר מתו.“ 21יוסף לקח את ישוע ואת מרים ויצא אתם בדרך לישראל.

22בהיותם בדרך שמעו שהמלך החדש אינו אלא ארכילאוס, בנו של הורדוס, ופחדו מאוד. בחלום נוסף יוסף הוזהר שלא להתיישב ביהודה, אז הם המשיכו לגליל 23והשתקעו בנצרת. זה קרה כדי לקיים את דברי הנביאים שכינו אותו ”נצרי“.2‏.23 ב 23 5 ראה: ישעיהו יא 1