Lefitiku 2 – YCB & ASCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 2:1-16

Ọrẹ ohun jíjẹ

1“ ‘Bí ẹnìkan bá mú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ wá fún Olúwa ọrẹ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró sí i, kí o sì fi tùràrí sí i, 2kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa. 3Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.

4“ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára, àkàrà tí a ṣe láìní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láìní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò. 5Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá jẹ́ inú àwo pẹẹrẹ ni o ti ṣe ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára tí a fi òróró pò, kò sì gbọdọ̀ ní ìwúkàrà. 6Rún un kí o sì da òróró sí i lórí, ọrẹ ohun jíjẹ ni. 7Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá jẹ́ ẹbọ ohun jíjẹ, tí a yan nínú apẹ, ìyẹ̀fun dáradára ni kí o fi ṣè é pẹ̀lú òróró. 8Mú ọrẹ ohun jíjẹ tí a fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe wá fún Olúwa gbé e fún àlùfáà, ẹni tí yóò gbe e lọ sí ibi pẹpẹ, 9Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa. 10Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.

11“ ‘Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún Olúwa kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí Olúwa. 12Ẹ lè mú wọn wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ mú wọn wá sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn. 13Ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ yín. Ẹ má ṣe aláìfi iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín sínú àwọn ọrẹ ohun jíjẹ yín, ẹ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ yín.

14“ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ ti àkọ́so oko yín wá fún Olúwa kí ẹ mú ọkà tuntun tí a fi iná yan. 15Kí ẹ da òróró lé e lórí, kí ẹ sì fi tùràrí sí i, ó jẹ́ ọrẹ ohun jíjẹ. 16Àlùfáà yóò sun ẹbọ ìrántí lára ọkà àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.

Asante Twi Contemporary Bible

3 Mose 2:1-16

Atokoɔ Afɔrebɔ

1“ ‘Obiara a ɔpɛ sɛ ɔbɔ aduane afɔdeɛ de ma Awurade no, ɛsɛ sɛ ɔde asikyiresiam a ɛyɛ fɛ a wahwie ngo agu so de aduhwam afra na ɛbɔ. 2Ɛsɛ sɛ ɔsa ne nsabuo ma de si aduane no nyinaa anan de ma asɔfoɔ no mu baako hye sɛ afɔrebɔdeɛ, na ɛbɛyɛ Awurade anisɔ. 3Ɛsɛ sɛ wɔde asikyiresiam no nkaeɛ ma Aaron ne ne mmammarima sɛ wɔn aduane; nanso wɔfa ne nyinaa sɛ afɔdeɛ kronkron a wɔabɔ ama Awurade.

4“ ‘Sɛ wɔde burodo a wɔato no fononoo mu brɛ Awurade sɛ afɔrebɔdeɛ a, ɛsɛ sɛ wɔde asikyiresiam a wɔayam no muhumuhu a wɔde ngo afra ato a mmɔreka nni mu na ɛbɔ saa afɔdeɛ no. Motumi de burodo ntrawa dɛɛdɛ a mmɔreka nni mu na mode ngo afa so nso bɔ afɔdeɛ ma ɛyɛ yie. 5Sɛ afɔrebɔdeɛ no yɛ aduane a wɔato no dadeɛ so a, asikyiresiam muhumuhu a mmɔreka mfra mu na mode ngo afra na momfa mmɔ saa afɔdeɛ no. 6Mommubu mu asinasini na monhwie ngo ngu so na ɛnyɛ sɛ atokoɔ afɔdeɛ ara pɛ. 7Sɛ monoa mo afɔdeɛ no wɔ kyɛnsee mu a, ɛno nso, momfa asikyiresiam muhumuhu a mode ngo afra na ɛmmɔ saa afɔdeɛ no. 8Sɛ moyɛ aduane bi, sɛ motooɛ, sɛ mokyeeɛ anaasɛ mohoeɛ no, ɛsɛ sɛ mode saa afɔrebɔdeɛ no kɔma ɔsɔfoɔ na ɔno nso de kɔ afɔrebukyia no anim de kɔma Awurade. 9Afɔrebɔdeɛ no mu kakra bi na ɛsɛ sɛ asɔfoɔ no hye, nanso Awurade ani bɛsɔ ade mu no nyinaa. 10Deɛ ɛbɛka no yɛ asɔfoɔ no dea, nanso wɔfa no sɛ ne nyinaa yɛ ɔhyeɛ afɔdeɛ kronkron a wɔabɔ de ama Awurade.

11“ ‘Afɔrebɔ a mode asikyiresiam na ɛbɔ no, mommfa mmɔreka mfra mu, ɛfiri sɛ, ɛnsɛ sɛ ɔhyeɛ afɔdeɛ biara a mobɛbɔ ama Awurade no, mode mmɔreka anaa ɛwoɔ fra mu. 12Mode bɛbrɛ Awurade sɛ aduanekan afɔrebɔdeɛ, nanso ɛnsɛ sɛ wɔhye wɔ afɔrebukyia no so sɛ afɔdeɛ a ɛsɔ Awurade ani. 13Momfa nkyene mfra afɔrebɔdeɛ biara, ɛfiri sɛ, nkyene yɛ nkaedeɛ wɔ Onyankopɔn apam no mu.

14“ ‘Sɛ mode mo mfudeɛ a ɛdi ɛkan mu aba kane rebɛbɔ afɔdeɛ a, emu aburoo no monhwane ho na monkye na momfa mma Awurade. 15Momfa ngo ne aduhwam nyɛ ho, ɛfiri sɛ, ɛyɛ atokoɔ afɔdeɛ. 16Na asɔfoɔ no bɛhye aburoo no bi a wɔde ngo ne aduhwam afra no sɛ nkaedeɛ wɔ Awurade anim.