Kolose 4 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Kolose 4:1-18

14.1: Le 25.43,53.Ẹyin ọ̀gá, ẹ máa fi èyí tí ó tọ́ tí ó sì dọ́gba fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ yín; kí ẹ sì mọ̀ pé ẹ̀yin pẹ̀lú ní Olúwa kan ní ọ̀run.

Àwọn ìlànà fún ìjọ

2Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; 3Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: 4Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. 54.5: Ef 5.16.Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. 6Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

Àwọn ìkíni ìkẹyìn

74.7-8: Ef 6.21-22.Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: 8Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; 94.9: Fm 10.Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.

104.10-11: Ap 19.29; 27.2; Fm 24.Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).

11Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi.

12Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. 13Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodikea, àti àwọn tí ó wà ní Hirapoli.

144.14: 2Tm 4.10-11; Fm 24.Luku, arákùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dema ki í yín.

15Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ní Laodikea, àti Nimpa, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.

16Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárín yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodikea; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodikea wá.

17Kí ẹ sì wí fún Arkippu pe, “Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún.”

184.18: 1Kọ 16.21.Ìkíni láti ọwọ́ èmi Paulu. Ẹ máa rántí ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.

New Amharic Standard Version

ቈላስይስ 4:1-18

1ጌቶች ሆይ፤ እናንተም በሰማይ ጌታ እንዳላችሁ ስለምታውቁ አገልጋዮቻችሁን በፍትሕና በቅንነት አስተዳድሯቸው።

ሌሎች ምክሮች

2ከማመስገን ጋር ነቅታችሁ በትጋት ጸልዩ። 3እኔ እስረኛ የሆንሁለትን የክርስቶስን ምስጢር ማወጅ እንድንችል፣ እግዚአብሔር የቃሉን በር እንዲከፍትልን ስለ እኛ ደግሞ ጸልዩ፤ 4ደግሞም መናገር እንደሚገባኝ ቃሉን በግልጽ እንድናገር ጸልዩልኝ። 5በውጭ ካሉት ሰዎች ጋር ባላችሁ ግንኙነት በጥበብ ተመላለሱ፤ በተገኘውም ዕድል ሁሉ ተጠቀሙ። 6ለእያንዳንዱ ሰው እንዴት መልስ መስጠት እንደሚገባችሁ ታውቁ ዘንድ ንግግራችሁ በጨው እንደ ተቀመመ ሁልጊዜ በጸጋ የተሞላ ይሁን።

የስንብት ሰላምታ

7ቲኪቆስ ስላለሁበት ሁኔታ በሙሉ ይነግራችኋል፤ እርሱ የተወደደ ወንድምና ታማኝ አገልጋይ፣ በጌታም አብሮኝ ሎሌ ነው። 8ስላለንበት4፥8 አንዳንድ የጥንት ቅጆች ስለ እናንተ…ያውቅ ዘንድ ሁኔታ እንድታውቁና ልባችሁንም እንዲያጽናና ለዚህ ጕዳይ ወደ እናንተ እልከዋለሁ፤ 9እርሱም ከእናንተ ወገን ከሆነው ከታማኙና ከተወዳጁ ወንድማችን ከአናሲሞስ ጋር ወደ እናንተ ይመጣል፤ እነርሱም እዚህ ስላለው ሁኔታ ሁሉ ይነግሯችኋል።

10አብሮኝ የታሰረው አርስጥሮኮስና የበርናባስ የአክስቱ ልጅ ማርቆስ ሰላምታ ያቀርቡላችኋል፤ ስለ ማርቆስ መመሪያ ደርሷችኋል፤ እንግዲህ ወደ እናንተ ሲመጣ ተቀበሉት።

11ኢዮስጦስ የተባለው ኢያሱም ሰላምታ ያቀርብላችኋል። ከተገረዙት መካከል ለእግዚአብሔር መንግሥት አብረውኝ የሚሠሩት፣ እኔንም ያጽናኑኝ እነዚህ ብቻ ናቸው፤ እነርሱም አጽናንተውናል።

12ከእናንተ ወገን የሆነው የክርስቶስ ኢየሱስ አገልጋይ ኤጳፍራ ሰላምታ ያቀርብላችኋል፤ እርሱም ፍጹም ጠንክራችሁና ሙሉ በሙሉ ተረጋግታችሁ በእግዚአብሔር ፈቃድ ሁሉ ጸንታችሁ እንድትቆሙ ዘወትር ስለ እናንተ በጸሎት እየተጋደለ ነው። 13ደግሞም ስለ እናንተ እንዲሁም በሎዶቅያና በኢያራ ከተሞች ስላሉት ተግቶ እንደሚሠራ እኔ እመሰክርለታለሁ።

14የተወደደው ሐኪሙ ሉቃስ እንዲሁም ዴማስ ሰላምታ ያቀርቡላችኋል።

15በሎዶቅያ ላሉት ወንድሞች፣ ለንምፉን፣ በቤቷም ላለች ቤተ ክርስቲያን ሰላምታ አቅርቡልኝ።

16ይህች መልእክት ከተነበበችላችሁ በኋላ በሎዶቅያ ላለችው ቤተ ክርስቲያን ደግሞ እንድትነበብ አድርጉ፤ እናንተም ደግሞ በሎዶቅያ ያለችውን መልእክት አንብቡ።

17ለአክሪጳም፣ “በጌታ የተቀበልኸውን አገልግሎት ከፍጻሜ ለማድረስ ተጠንቀቅ” በሉልኝ።

18ይህን ሰላምታ በገዛ እጄ የጻፍሁት እኔ ጳውሎስ ነኝ። እስራቴን አስቡ። ጸጋ ከእናንተ ጋር ይሁን።