Jona 2 – YCB & KLB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jona 2:1-10

Àdúrà Jona

1Nígbà náà ni Jona gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá, 2Ó sì wí pé:

“Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa,

òun sì gbọ́ ohùn mi.

Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́,

ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.

3Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú,

ní àárín Òkun,

ìṣàn omi sì yí mi káàkiri;

gbogbo bíbì omi àti rírú omi

rékọjá lórí mi.

4Nígbà náà ni mo wí pé,

‘a ta mí nù kúrò níwájú rẹ;

ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún

máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’

5Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn;

ibú yí mi káàkiri,

a fi koríko odò wé mi lórí.

6Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá;

ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí:

ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá,

Olúwa Ọlọ́run mi.

7“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi,

èmi rántí rẹ, Olúwa,

àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,

nínú tẹmpili mímọ́ rẹ.

8“Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké

kọ àánú ara wọn sílẹ̀.

9Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ.

Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́.

‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’ ”

10Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jona sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.

Korean Living Bible

요나 2:1-10

요나의 기도

1요나는 물고기 뱃속에서 자기 하나님 여호와께 이렇게 기도하였다.

2“내가 고통 중에

주께 부르짖었더니

주께서는 나에게 응답하셨으며

내가 2:2 또는 ‘스올의 뱃속에서’무덤과 같은 곳에서

주의 도움을 구하였더니

주께서 내 음성을 들으셨습니다.

3주께서 나를

바다 깊은 곳에 던지셨으므로

물이 나를 두르고

주의 큰 파도가 나를 덮쳤습니다.

4내가 주 앞에서 쫓겨났으나

나는 다시 주의 성전을

바라보겠다고 말하였습니다.

5물이 나를 덮쳐

내가 바다 깊은 곳에 빠졌을 때

바다풀이 내 머리를 휘감았습니다.

6내가 해저의 산 밑바닥까지 내려가

2:6 또는 ‘땅이 그 빗장으로 나를 오래도록 막았사오나’죽음의 땅에 갇혀 있었으나

나의 하나님 여호와여,

주께서 내 생명을

죽음에서 구해 내셨습니다.

7“내 생명이 서서히 사라져 갈 때

내가 다시 한번 여호와를 생각하며

기도하였더니

성전에 계시는 주께서

내 기도를 들으셨습니다.

8무가치한 우상을 숭배하는 자들은

주의 자비를 저버린 자들입니다.

9그러나 나는 감사의 노래로

주께 제사를 드리며

내가 서약한 것을 지키겠습니다.

구원은

여호와께서 주시는 것입니다.”

10여호와께서 물고기에게 명령하시자 그 물고기가 요나를 해변에 토해 내었다.