Johanu 10 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 10:1-42

Agbo kan àti olùṣọ́-àgùntàn kan

1“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà. 210.2: Mk 6.34.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn. 3Òun ni aṣọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde. 4Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. 5Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.” 610.6: Jh 16.25.Òwe yìí ni Jesu pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn.

7Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. 810.8: Jr 23.1; El 34.2.Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn. 9Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. 10Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.

1110.11: Isa 40.11; El 34.11-16; Hb 13.20; 1Pt 5.4; If 7.17; 1Jh 3.16; Jh 15.13.“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

14“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 1510.15: Mt 11.27.Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 1610.16: Isa 56.8; Jh 11.52; 17.20; Ef 2.13-18; 1Pt 2.25.Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. 1810.18: Jh 14.31; 15.10; Fp 2.8; Hb 5.8.Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

1910.19: Jh 7.43; 9.16.Nítorí náà ìyapa tún wà láàrín àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 2010.20: Jh 7.20; 8.48; Mt 11.18.Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”

2110.21: Jh 9.32; Ek 4.11.Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”

Àìgbàgbọ́ àwọn Júù

22Àkókò náà sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jerusalẹmu, ni ìgbà òtútù. 2310.23: Ap 3.11; 5.12.Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni, 24Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kristi náà, wí fún wa gbangba.”

2510.25: Jh 5.36; 10.38.Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi. 2610.26: Jh 8.47.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín. 27Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn: 2810.28: Jh 17.2; 1Jh 2.25.Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. 29Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. 3010.30: Jh 17.21.Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”

3110.31: Jh 8.59; 11.8.Àwọn Júù sì tún mú òkúta, láti sọ lù ú. 32Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”

3310.33: Le 24.16; Mk 14.64.Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.”

3410.34: Jh 8.17; Sm 82.6.Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? 35Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́. 36Kín ni ẹyin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó sì rán sí ayé kín lo de ti ẹ fi ẹ̀sùn kàn mi pé mò ń sọ̀rọ̀-òdì nítorí pé mo sọ pé, ‘Èmi ni ọmọ Ọlọ́run.’ 37Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. 38Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin ba à lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.” 3910.39: Jh 7.30; 8.59; Lk 4.30.Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.

4010.40: Jh 1.28.Ó sì tún kọjá lọ sí apá kejì Jordani sí ibi tí Johanu ti kọ́kọ́ ń bamitiisi; níbẹ̀ ni ó sì jókòó. 41Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ààmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Johanu sọ nípa ti ọkùnrin yìí.” 4210.42: Jh 7.31; 11.45.Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbà á gbọ́.