Jobu 39 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 39:1-30

Agbára Ọlọ́run

1“Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?

Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?

2Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé,

ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ,

3Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ,

wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde.

4Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn;

wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.

5“Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́?

Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,

6Èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún,

àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀.

7Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú,

bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran.

8Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀,

Òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí.

9“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí?

Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?

10Ìwọ le fi Òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo?

Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?

11Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀?

Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?

12Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé,

àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ?

13“Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí,

tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?

14Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀,

a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;

15Tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́,

tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.

16Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀;

asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;

17Nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n,

bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.

18Nígbà tí ó gbé ara sókè,

ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.

19“Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí,

tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?

20Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?

Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.

21Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú Àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀;

ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.

22Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó;

bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.

23Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹ́kẹ́pẹ́kẹ́,

àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.

24Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi,

bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.

25Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà!

Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré,

igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.

26“Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè,

tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?

27Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè,

kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?

28Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta,

lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.

29Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri,

ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.

30Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀,

níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”

New International Reader’s Version

Job 39:1-30

1“Job, do you know when mountain goats have their babies?

Do you watch when female deer give birth?

2Do you count the months until the animals have their babies?

Do you know the time when they give birth?

3They bend their back legs and have their babies.

Then their labor pains stop.

4Their little ones grow strong and healthy in the wild.

They leave and do not come home again.

5“Who let the wild donkeys go free?

Who untied their ropes?

6I gave them the dry and empty land as their home.

I gave them salt flats to live in.

7They laugh at all the noise in town.

They do not hear the shouts of the donkey drivers.

8They wander over the hills to look for grass.

They search for anything green to eat.

9“Job, will wild oxen agree to serve you?

Will they stay by your feed box at night?

10Can you keep them in straight rows with harnesses?

Will they plow the valleys behind you?

11Will you depend on them for their great strength?

Will you let them do your heavy work?

12Can you trust them to haul in your grain?

Will they bring it to your threshing floor?

13“The wings of ostriches flap with joy.

But they can’t compare with the wings and feathers of storks.

14Ostriches lay their eggs on the ground.

They let them get warm in the sand.

15They do not know that something might step on them.

A wild animal might walk all over them.

16Ostriches are mean to their little ones.

They treat them as if they did not belong to them.

They do not care that their work was useless.

17I did not provide ostriches with wisdom.

I did not give them good sense.

18But when they spread their feathers to run,

they laugh at a horse and its rider.

19“Job, do you give horses their strength?

Do you put flowing manes on their necks?

20Do you make them jump like locusts?

They terrify others with their proud snorting.

21They paw the ground wildly.

They are filled with joy.

They charge at their enemies.

22They laugh at fear. They are not afraid of anything.

They do not run away from swords.

23Many arrows rattle at their sides.

Flashing spears and javelins are also there.

24They are so excited that they race over the ground.

They can’t stand still when trumpets are blown.

25When they hear the trumpets they snort, ‘Aha!’

They catch the smells of battle far away.

They hear the shouts of commanders and the battle cries.

26“Job, are you wise enough to teach hawks where to fly?

They spread their wings and fly toward the south.

27Do you command eagles to fly so high?

They build their nests as high as they can.

28They live on cliffs and stay there at night.

High up on the rocks they think they are safe.

29From there they look for their food.

They can see it from far away.

30Their little ones like to eat blood.

Eagles gather where they see dead bodies.”