Jobu 34 – YCB & HOF

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 34:1-37

Elihu pe Jobu níjà

1Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé:

2“Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,

kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye.

3Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,

bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò.

4Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa;

ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa.

5“Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi;

Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ.

6Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,

bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi,

ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’

7Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu,

tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi?

8Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó

sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.

9Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,

tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’

10“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi,

ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:

Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú,

àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!

11Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe,

yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀.

12Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà;

bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.

13Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́,

tàbí ta ni ó fi gbogbo ayé lé e lọ́wọ́?

14Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀

tí ó sì gba ọkàn rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,

15gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,

ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀.

16“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye,

gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi.

17Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí?

Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?

18O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘ènìyàn búburú ní ìwọ,’

tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘ìkà ni ẹ̀yin,’

19Mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé

tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ,

nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?

20Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú,

àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ;

a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.

21“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn,

òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.

22Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú,

níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sápamọ́ sí.

23Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan,

kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.

24Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí,

a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,

25nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn,

ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

26Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn

níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,

27nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i,

wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,

28kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀,

òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.

29Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi?

Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i?

Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;

30Kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọba

kí wọn kí ó má di ìdẹwò fún ènìyàn.

31“Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé,

èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́?

32Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi

bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

33Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà?

Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bí ìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́,

ìwọ gbọdọ̀ yan, kì í ṣe èmi.

Nítorí náà sọ ohun tí o mọ̀;

Pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ́!

34“Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi,

àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,

35‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe aláìgbọ́n.’

36Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin,

nítorí ìdáhùn rẹ̀ dàbí i ti ènìyàn búburú:

37Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;

ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa,

ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”

Hoffnung für Alle

Hiob 34:1-37

Gott gibt jedem Menschen, was er verdient

1Weiter sagte Elihu:

2»Hört mir zu, ihr Weisen, ihr gelehrten Männer!

Achtet auf das, was ich sage!

3Denn unser Ohr prüft die Worte,

so wie der Gaumen die Speise kostet.

4Wir müssen ein Urteil fällen,

wir wollen gemeinsam erkennen, was gut ist.

5Denn Hiob behauptet:

›Ich bin unschuldig,

und doch verweigert Gott mir mein Recht!

6Obwohl ich recht habe,

werde ich als Lügner hingestellt;

trotz meiner Unschuld hat mich sein tödlicher Pfeil getroffen!‹

7Schaut euch Hiob an,

wie er sich im Spott gefällt,

8wie er mit den Übeltätern Freundschaft schließt

und sich mit gottlosen Menschen einlässt!

9Denn Hiob behauptet: ›Es nützt gar nichts,

wenn ein Mensch versucht, Gott zu gefallen!‹

10Hört mir zu, ihr klugen Männer:

Sollte Gott jemals Böses tun?

Nein, niemals!

Der Allmächtige verdreht nicht das Recht!

11Gott bestraft einen Menschen nur für seine eigenen Taten;

jedem gibt er zurück, was er verdient.

12Gott begeht kein Unrecht,

das ist unvorstellbar!

Der Allmächtige beugt niemals das Recht!

13Er herrscht über Himmel und Erde,

er hat sie geschaffen.

Niemand steht über ihm!

14Wenn er wollte, könnte er seinen Geist

und seinen Lebensatem aus dieser Welt zurückziehen,

15dann würde alles Leben mit einem Schlag sterben,

und die Menschen zerfielen zu Staub!

16Bist du wirklich weise, Hiob,

dann hör jetzt genau zu, achte auf jedes Wort:

17Kann einer regieren, wenn er das Recht mit Füßen tritt?

Willst du Gott, den Gerechten,

für schuldig erklären, ihn, den Allmächtigen?

18Er ist es doch, der skrupellose Könige und gottlose Fürsten verurteilt.

19Er ergreift nicht Partei für die Mächtigen,

Hochgestellte zieht er den Armen nicht vor –

er hat ja allen das Leben gegeben!

20Die Fürsten sterben plötzlich,

mitten in der Nacht;

ihr Volk gerät in Aufruhr,

und sie verschwinden.

Ja, die Mächtigen werden beseitigt,

doch nicht von Menschenhand.

21Denn Gott sieht die Wege eines jeden

und alles, was er unternimmt.

22Es gibt keine Finsternis und keinen dunklen Ort,

wo Übeltäter sich vor Gott verstecken könnten.

23Er muss Menschen nicht erst lange verhören

und sie zu sich laden vor Gericht –

24nein, ohne Verhandlung stürzt er die Mächtigen

und setzt andere an ihrer Stelle ein.

25Über Nacht lässt er sie fallen

und zugrunde gehen,

denn er weiß, was sie getrieben haben.

26Er straft sie für ihre Vergehen,

und das in aller Öffentlichkeit.

27Denn diese Mächtigen wollten Gott nicht mehr gehorchen,

seine Weisungen waren ihnen völlig gleichgültig.

28Darum stieg der Hilfeschrei der Armen zu ihm empor –

und er hörte ihn!

29Aber wenn Gott schweigt,

wer will ihn dann beschuldigen?

Wenn er sich verbirgt, wer kann ihn noch erblicken?

Und doch wacht er über den Völkern,

ja, über der ganzen Menschheit;

30er verhindert,

dass ein gottloser Herrscher an die Macht kommt

und sein Volk ins Unglück stürzt.

31Der Mensch sollte zu Gott sagen:

›Ich bin schuldig geworden,

aber ich will nichts Böses mehr tun!

32Zeig mir die Sünden,

die ich selbst nicht erkenne!

Ich habe Unrecht begangen,

doch ich will es nicht mehr tun!‹

33Du aber weigerst dich umzukehren!

Und wenn es nach dir ginge,

sollte Gott dich dafür noch belohnen!

Du musst eine Entscheidung treffen, nicht ich!

Also, sag mir nun, was du weißt!

34Wer noch einen Funken Verstand hat,

wird mir zustimmen;

jeder Weise, der mich hört, wird sagen:

35›Hiob plappert daher ohne Sinn und Verstand.

Er weiß nicht, was er sagt!‹

36Ja, Gott soll Hiob weiter durch das Leiden prüfen,

weil er ihm so unverschämt widerspricht!

37Nicht genug, dass er Schuld auf sich lädt –

er lehnt sich auch noch offen gegen Gott auf!

Laut spottet er vor unseren Ohren

und findet viele Worte gegen ihn.«