Jobu 32 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 32:1-22

Ọ̀rọ̀ Elihu

1Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jobu lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀. 2Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre. 3Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi. 4Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí. 5Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.

6Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé:

“Ọmọdé ni èmi,

àgbà sì ní ẹ̀yin;

ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró,

mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.

7Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀,

àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.

8Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn

àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.

9Ènìyàn ńláńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n,

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.

10“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé: Ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;

èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.

11Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;

Èmi fetísí àròyé yín,

nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;

12àní, mo fiyèsí yín tinútinú.

Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́;

tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!

13Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí;

Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’

14Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.

15“Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́,

wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.

16Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́;

wọn kò sì dáhùn mọ́.

17Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi,

èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.

18Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ,

ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.

19Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò;

ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.

20Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,

èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

21Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan,

bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.

22Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀,

Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.

New International Version

Job 32:1-22

Elihu

1So these three men stopped answering Job, because he was righteous in his own eyes. 2But Elihu son of Barakel the Buzite, of the family of Ram, became very angry with Job for justifying himself rather than God. 3He was also angry with the three friends, because they had found no way to refute Job, and yet had condemned him.32:3 Masoretic Text; an ancient Hebrew scribal tradition Job, and so had condemned God 4Now Elihu had waited before speaking to Job because they were older than he. 5But when he saw that the three men had nothing more to say, his anger was aroused.

6So Elihu son of Barakel the Buzite said:

“I am young in years,

and you are old;

that is why I was fearful,

not daring to tell you what I know.

7I thought, ‘Age should speak;

advanced years should teach wisdom.’

8But it is the spirit32:8 Or Spirit; also in verse 18 in a person,

the breath of the Almighty, that gives them understanding.

9It is not only the old32:9 Or many; or great who are wise,

not only the aged who understand what is right.

10“Therefore I say: Listen to me;

I too will tell you what I know.

11I waited while you spoke,

I listened to your reasoning;

while you were searching for words,

12I gave you my full attention.

But not one of you has proved Job wrong;

none of you has answered his arguments.

13Do not say, ‘We have found wisdom;

let God, not a man, refute him.’

14But Job has not marshaled his words against me,

and I will not answer him with your arguments.

15“They are dismayed and have no more to say;

words have failed them.

16Must I wait, now that they are silent,

now that they stand there with no reply?

17I too will have my say;

I too will tell what I know.

18For I am full of words,

and the spirit within me compels me;

19inside I am like bottled-up wine,

like new wineskins ready to burst.

20I must speak and find relief;

I must open my lips and reply.

21I will show no partiality,

nor will I flatter anyone;

22for if I were skilled in flattery,

my Maker would soon take me away.